Obasanjo kọ̀wé sí ìjọba UK láti fi ojú àánú wo Ekweremadu lórí ìdájọ́ ẹ̀sun ṣíṣe òwò ara

Obasanjo, Ike Ekweremadu

Oríṣun àwòrán, @RealOlaudah

Aarẹ Naijiria nigba kan ri, Oloye Olusegun Obasanjo ti kọwe si ile ẹjọ ilẹ Gẹẹsi lori igbẹjọ igbakeji Aarẹ ile igbimọ aṣofin tẹlẹ, Ike Ekweremadu, ati iyawo rẹ lori ẹsun ṣise owo ẹya ara.

Ninu lẹta kan ti Obasan kọ si ile ẹjọ Central Criminal Court, to wa ni Old Bailey, niluu London lo ti rawọ ẹbẹ ọhun.

Ṣaaju ni ile ẹjọ ti kọkọ sọ pe Ekweremadu jẹbi ẹsun ti wọn fi kan, eyii to mu ko ṣeeṣe ki oun ati iyawo rẹ fi ẹwọn ti iye ọjọ rẹ to ọdun mẹwaa jura.

Lẹyin ti ile ẹjọ naa sọ pe tọkọtaya ọhun jẹbi lo kede pe oun yoo ṣe idajọ wọn lọjọ karun un, oṣu to n bọ.

Aarẹ Naijiria tẹlẹ ri naa ti wa kọwe si ijọba ilẹ UK lati fi oju aanu wo Ekweremadu ati aya rẹ.

Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Obasanjo

Obasanjọ sọ ninu lẹta to kọ pe Ekweremadu ti kẹkọọ lara iṣẹlẹ naa, oun si n fẹ ki wọn ṣaanu rẹ.

O ni “Akowe ile ẹjọ... mo mọ pe ohun ti awọn mejeji ṣe buru jai, ko si si orilẹ-ede to le fi ọwọ yẹpẹrẹ mu irufẹ iwa bẹẹ.”

“Amọ ṣa, yoo wu mi, nitori ibaṣepọ to wa laarin ijọba UK ati Naijiria; gẹgẹ bii ipo Ekwueremadu to jẹ ọkan lara awọn aṣofin to dantọ ni Naijiriai ati nitori ilera ọmọ rẹ obinrin to nilo itọju, mo fẹ ko ba mi bẹ ijọba UK ki wọn fi oju aanu wo ọrọ naa.”

“Mo gbagbọ pe ọgbẹni Ekweremadu ati aya rẹ ti kọ ẹkọ nla lara iṣẹlẹ yii, mo si gbagbọ wọn yoo tẹsiwaju lati maa jẹ apẹrẹ fun awọn araalu.”

Lẹyin naa lo bẹbẹ pe ki wọn gbe ọrọ oun inu lẹta naa yẹwo ki Ekweremadu ati iyawo rẹ le ri aanu gba lọjọ idajọ wọn to n bọ laipẹ.