A kò ní fi agídí mú ẹnikẹ́ni láti san ₦1,000 owó ìdàgbàsókè ẹ̀kọ́, ṣùgbọ́n... – Ìjọba Ondo

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi
Ijọba ipinlẹ Ondo ti sọ pe ẹgbẹrun kan owo idagbasoke eto ẹkọ ti awọn kede ṣe pataki fun gbogbo ọmọ ipinlẹ naa lati san.
Wọn ni awọn ko ni fi agidi mu ẹnikẹni lati san owo naa, amọ ẹnikẹni to ba kọ lati san ko ni jẹ awọn anfaani kan lati ọdọ ijọba.
Kọmiṣọna eto ẹkọ ipinlẹ Ondo, ọgbẹni Femi Agagu lo fi ọrọ naa lede ninu ifọrọwerọ kan BBC Yoruba.
Agagu sọ pe “Owo naa kii ṣe owo ori o, owo idagbasike ni lati ran eto ẹkọ lọwọ ni.”
“Ko si ẹnikẹni ti yoo fi ipa mu ọ pe ko lọ san owo naa amọ ti eeyan ba fẹ janfani ijọba, ijọba yoo bere iwe ẹri pe irufẹ ẹni bẹẹ ti san owo ọhun lati fi han pe ọmọ ipinlẹ Ondo to n fẹ ilọsiwaju ilu ẹni bẹẹ.”
“Ẹni to ba kọmlati san owo ọhun ko ni lafaani lati jẹ awọn anfani kan bii gbiba iwe ẹri owo ori tabi iwe ẹri ilẹ, C of O.”
Bawo ni wọn ṣe fẹ gba owo naa?

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi
Agagu sọ pe awọn agbalagba ti wọn le san owo ori ni wọn yoo maa san owo naa, bẹẹ ni ko kan awọn akẹkọọ ti ko niṣẹ lọwọ.
O ni eto kan ti wọn pe ni “Pay Direct” ni wọn yoo maa fi gba owo ọhun, ti ẹni to ba san owo ọhun yoo si ni risiiti.
O fi kun pe awọn araalu tun le fi owo naa ranṣẹ si ijọba lati ori foonu wọn nibikiti ti wọn ba wa.
Kọmisọna ọhun ṣalaye siwaju si pe kii ṣe awọn to n gbe ipinlẹ Ondo nikan ni sisan owo naa wa fun.
O ni “Ti o ko ba fi ipinlẹ Ondo ṣebugbe amọ to fẹ ra ile tabi ilẹ nipinlẹ Ondo, o gbọdọ san owo naa nitori o ti di ara wa naa niyẹn.”
Ki ni ijọba yoo fi owo naa ṣe?
Agagu sọ siwaju si pe owo naa yoo wulo fun idagbasoke eto ẹkọ nipinlẹ Ondo.
O ni “A fẹ fi owo yii kun owo ti ijọba ti la kalẹ fun etọ ẹkọ tẹlẹ nitori owo naa ko to.”
“A ni oniruru ohun ti a le fi owo naa ṣe, fun apẹrẹ, fasiti mẹta ni a ni nipinlẹ Ondo, yatọ si ọpọ awọn ile ẹkọ mii, to fi mọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama, a si ni ọpọ awọn olukọ yanturu.”
Kọmiṣọna ọhun sọ pe awọn le fi owo naa san owo oṣu awọn olukọ, kọ ile ẹkọ tuntun, ra awọn ohun elo ẹkọ igbalode, tabi awọn ohun miran to ṣe pataki si eto ẹkọ.
O pari ọrọ rẹ pe awọn ọlọpọlọ pipe ni ijọba Ondo ti yan si igbimọ ti yoo maa bojuto owo naa, lọna ati ri daju pe owo ọhun lọ si ẹka ibi ti wọn n fẹ ko lọ lai si magomago kankan.












