A ti fàyè gba ilé ẹ̀kọ́ Chrisland láti ṣe àyẹ̀wò aládàni lórí ikú Whitney Adeniran - Ilé-ẹjọ́

Aworan whitney, ile ẹkọ Chrisland

Awọn obi Whitney Adeniran ọmọ ọdun mejila to padanu ẹmi rẹ laipe nigba ti ile iwe rẹ Chrisland International ṣe ere idaraya ojule sojule ile ẹkọ naa, yoo yoju si awọn to gbọ ẹjọ lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan ile iwe Chrisland.

Adajọ Olabisi Fajana lo fidi ọrọ naa mulẹ nigba ti oun sọrọ lori iwe ibeere ile iwe Chrisland lati ṣe iwadii aladani lori abajade ti ijọba ipinlẹ Eko ṣe oku Whitney.

Adajọ naa tun fun ile ẹko Chrisland laṣẹ lati gba oluyẹwo miran ti o mọ nipa ẹya ara ẹniti o ti gbẹmi mii.

Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Eko ti gbe igbimo ti yoo ṣe iwadii ohun ti o fa iku Whitney silẹ lati ọjọ ketala osu keji ọdun yii.

Ni ọjọ keji osu kẹta ọdun yii ni ijọba ipinlẹ Eko kede abajade iwadii rẹ to si fihan wi pe iku Whitney ko sẹyin ijamba ina ẹlẹtiriiki ti ko si tun ri eemi mi simu.

Iwadii yii lo jẹ ki igbẹjọ lori ẹsun naa bẹrẹ lọjọ kẹrin osu kerin ọdun yii, ṣugbon ile ẹkọ Chrisland bẹ ile ẹjọ lati faye gba a lati ṣe iwaadi tirẹ lori ohun to ṣeku pa Whitney, ọmọ ile ẹkọ naa, ko si ṣe ayẹwo awọn ẹri ti ijọba ipinlẹ Eko gba wa silẹ ẹjọ.

Adajọ Fajana pasẹ ki wọn pese awọn ẹri to fidi isẹlẹ naa mulẹ ni ile iwosan ti awọn ti ijọba fẹsun kan fẹ lo ati pe ki awọn Obi Whitney si wa nibẹ.

Ile ẹjọ pasẹ ki awọn Obi Whitney fara han ile ẹjọ lati jẹri lọjọ kẹtadinlogun osu kẹrin.

Ìyá Whitney Adeniran sọ̀rọ̀ lórí ìgbẹ́jọ́ ikú ọmọ rẹ̀ tó ń lọ lọ́wọ́

Whitney Adeniran

Oríṣun àwòrán, @bam.babycity

Iya Whitney Adeniran, akẹkọọ Christland College to di oloogbe, iyẹn Blessing Adeniran ti sọ pe oun ko tii pe ile ẹkọ naa lẹjọ.

Blessing Adeniran ni ijọba ipinlẹ Eko ni ile ẹkọ naa n ba ṣe ẹjọ lọwọ kii ṣe oun.

Iya oloogbe ọhun lo fi ọrọ naa lede ninu fidio kan to di lede loju opo Instagram rẹ.

O ni “Mi o tii pe ile ẹkọ Christland lẹjọ o, ijọba ipinlẹ Eko lo n ba wọn ṣe ẹjọ.”

“O yẹ ki a maa ṣe iwadii iroyin ki a to maa pin kiri.”

Obinrin naa ṣalaye pe awọn eeyan kan ti n da oun ati ẹbi oun lẹbi pe wọn n ba Christland ṣe ẹjọ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, oun ko tilẹ yọju sile ẹjọ ti wọn ti n gbọ ẹjọ naa rara, ati pe ile ẹkọ naa gan lo fi ọrọ nipa iṣẹlẹ iku ọmọ oun lọ ijọba.

O ṣalaye pe ilẹ ẹkọ Christland lo lọ fi ọrọ ọhun lọ ọlọpaa lọjọ ti ọmọ oun ku, kii ṣe oun.

Obinrin naa sọ pe oun yoo gbena woju ẹnikẹni to ba fi ẹsun kan oun lori ọrọ naa.

O pari ọrọ rẹ pe ki awọn eeyan dẹkun ati maa sọ fun awọn ti nnkan ba ṣẹlẹ si ki wọn gba fun Ọlọrun lai ṣe ohun to yẹ.

Ẹwẹ, lara awọn to to n jẹjọ lori iku ọmọ naa ni ọga agab ile ẹkọ Christland ati igbakeji rẹ.