Tí Tinubu bá kọ̀ láti yanjú àtúntò ìjọba, ó ṣeéṣe kí.... - Soyinka

Oríṣun àwòrán, wolesoyinka/facebook
Ọjọgbọn Wole Soyinka ti rọ aarẹ tuntun tilu dibo yan ni Naijiria, Bola Ahmed Tinubu lati mu ọrọ atunto orilẹede yii ni ọkunkundun.
Wole Soyinka lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ile isẹ Akọroyin Channels.
Ọjọgbọn Soyinka ni iṣejọba Bola Tinubu gbọdọ rii wi pe o mu eto atunto ijọba lokunkundun, o tẹsiwaju wi pe ti ijọba ba fẹ ki awọn eto ati ilana iṣejọba kẹsẹjari wọn gbọdọ rii wi pe ohun ti ọpọ awọn ọdọ ati ara ilu fẹ ni ki wọn gbe ṣe.
Soyinka ni: "Ohun tuntun ti n sọrọ, wọn si lagbara ju ti tẹlẹ lọ, wọn kii ṣe ohun to n pariwo lasan, ohun ti wọn sọ jẹ ooto ọrọ, lati ma kuna, pupọ wọn n beere fun ilana iṣejọba miiran, a o le ko iyan wọn kere.
Ilumọọka Ọjọgbọn naa tun ni "ti a ba kọ taa gbo ti wọn, gbogbo alasilẹ ijọba lori eto idagbasoke ni yoo fori sanpọn, aa si tun pada si ẹsẹ aarọ”.
Soyinka nigba ti o sọrọ lori iṣoro airowo na to waye ṣaaju ki eto idibo to waye ni, Gomina banki apapọ orilẹede yii Godwin Emefiele ti rufin ẹṣẹ si iwa ọmọniyan pẹlu bi ọwọngogo owo naira ṣe wa.
O tẹsiwaju wipe aarẹ Muhammed Buhari wa lara awọn to fi ọpọ iya jẹ awọn ọmọ orilẹede yii pẹlu bo ṣe fi aye gba ki ọwọngogo owo ko wa.
Soyinka ni "Emefiele ati ọga rẹ, aarẹ Buhari ni wọn lọwọ si aisi owo, fun aarẹ Buhari lati jẹ ki iṣoro airowo naa ṣẹlẹ.
O ni "pẹlu iṣoro airowo na, mi n le ra iwe iroyin, mi n le ra guguru ati ẹpa, o tumọ si wi pe awọn agbẹ ko le ri owo lati san fun ọlọkọ to fẹ ba wọn gbe ere oko wọn wa le”.
Ọjọgbọn naa rọ awọn to dije dupo aarẹ orilẹede yii lati fun awọn agbẹnusọ wọn ni isinmi ki wọn ye kona mọ ina oṣelu to n jo lọwọlọwọ, ki awọn to wọle ba awọn ara ilu sọrọ taara, ko le mu opin ba aigbọra ẹni ye to n sẹlẹ.















