Súnmọ́ ìyàwó rẹ̀ nínú Ramadan àmọ́ tóo bá kú pi ... ẹ wá gbọ́ òótọ́ - Akewugbagold lahùn
Adari ẹsin Islam kan to gbajumọ ni ilẹ yoruba paapaa ni ilu Ibadan to fi ṣe ibugbe, Sheikh Taofeek Akweugbagold ti yananana awọn ohun to yẹ ni ṣiṣẹ atawọn “kai ma ṣe” lasiko aawẹ Ramadan.
Gẹgẹ bi awọn ẹlẹsin musulumi ṣe ti ba asiko aawẹ Ramadan de bii ọjọ melo kan bayii, ọpọ ibeere lo saba maa n jẹ jade lẹnu awọn eeyan nipa oun ti wọn lee ṣe ati eyi ti Islam kọ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo yii pẹlu adari ẹsin ti ọpọlọpọ musulumi fẹran ti wọn si gbagbọ ninu ọrọ rẹ, Alhaji Akweugbagold ni ki awọn musulumi gbiyanju lati ma sọ laada wọn nu tori ki lo yẹ ka ṣe ati ki ni ko yẹ ka ṣe.

O mẹnu ba awọn iṣe oloore ti musulumi le maa ṣe ninu fidio to wa loke yii.
Bakan naa, Akewugbagold tun ṣalaye awọn nnkan to maa n fa awuyewuye laarin awọn musulumi lara eyi ti ibalopọ laarin lọkọ laya wa.
Ṣe ibalopọ wa tọ lasiko Ramadan ati pe igba wo gaan ni eeyan lee kan lu bẹẹdi? - Ẹ wo fidio naa loke.






