'Tinubu ni yóò sọ pàtó ìgbà tí owó ìrànwọ́ orí èpò "subsidy" yóò tán'

Aworan Tinubu

Oríṣun àwòrán, BolaTinubu/Facebook

Alaga igbimo ipolongo aarẹ fun ẹgbẹ oselu APC ni aarẹ tuntun ti ilu dibo yan Bola Tinubu ni yoo sọ pato igba ti oun yoo yọ owo iranwo ori epo kuro.

Bo tilẹ jẹ wi pe iṣejọba aarẹ Buhari ti fi lede wi pe owo iranwọ ori epo yoo tẹsiwaju di inu oṣu kẹfa ọdun yii, Festus Keyamo ni ijọba to n bọ ni yoo sọ boya ohun yoo wọgile owo iranwọ naa.

ọpọlọpọ awuyewuye lo ti bẹrẹ si ni suyọ lori ohun ti igbesẹ yii le mu wa ti awọn alagbata epo bẹntiro ti ni o ṣeeṣe ki lita epo bẹntiro to aadọtalelẹẹgbẹrin naira fun jala epo kan.

Ṣugbon awọn adari ajọ osiṣẹ ti ni, ijọba gbọdọ tun awọn ile isẹ ifọpo ṣe ki wọn to yọ owo iranwo naa.

Ile isẹ to wa fun ipese epo lorilẹede yii ti ni irinwo biliọnu ni awọn aa gẹgẹ bii owo iranwọ epo loṣu eyi ti ko ṣeeṣe ki o tẹsiwaju.

Bola Tinubu gbọdọ yọ owo iranwọ ori epo - Keyamo

Festus Keyamo ni oun mọ wi pe aarẹ tuntun yoo yọ owo iranwo ori epo, nitori alakalẹ ilana aarẹ Buhari ni, ṣugbon Tinubu ni yoo sọ igba ti oun yoo yọ owo iranwọ naa.

Keyamo tun ni oṣu kẹfa ọdun yii ni ijọba la silẹ pẹlu aba isuna lati san owo naa mọ.

Ninu ọrọ rẹ, adari eto ipolongo naa ni ”O wa lara oun ti a fi ṣe ipolongo, mi o ni le joko sibi ki si sọ pato igba ti yoo bẹrẹ, ṣugbon yiyọ igunpa owo epo wa lara ohun ti aarẹ tuntun jẹjẹ lati ṣe, oun nikan kọ ṣugbon gbogbo awọn to ṣe ipolongo ibo sipo aarẹ.

“Idi ti ijọba fi fọwọ si osu kẹfa gẹgẹ bi igba ti owo iranwọ ori epo ba tan ni wi pe owo isuna to gbe abala owo iranwọ ori epo yoo dopin ninu oṣu kẹfa.

Ṣugbon ti ijọba tuntun ba bẹrẹ oun ni yOo sọ bi yoo ti ṣe e”.

Ẹma da kun iya ati iṣoro awọn ọmọ orilẹede yii - Ẹgbẹ oselu PDP, NNNP

Agbẹnusọ ẹgbẹ osẹlu PDP Ibrahim Abdullahi ni “Bawo ni ẹgbẹ oṣelu APC se le yo owo iranwọ ori epo?ko si ohun to jọ.awọn lo gbogun ti ijọba ẹgbẹ oselu PDP nigba ti o fẹ yoo owo iranwọ ori epo.

Lẹyin ọdun Mejọ ninu isejọba wọn o se nkankan,awọn ọmọ orilẹede yii ko gbọdọ gba wọn gbo”.

Alukoro ẹgbẹ oṣelu NNPP,ọgagun Agbo ni ẹgbẹ oṣelu oun ko fọwọ si yi yọ owo iranwọ ori epo nitori yo mu ọpọ inira ba awọn ọmọ orilẹede yi.

Agbo ni “Ijọba gbe owo iranwo ori epo wa ki awọn ti oku die kato fun le jẹ igbadun ijọba,sugbon ti wọn ba yoo owo iranwọ ori epo oṣeṣe ki awọn alaini jẹ iya sii ẹgbẹ oselu NNPP ko fọwọ si igbese ijọba yii.

A ó gùnlé ìyànṣẹ́lódì àti ífẹ̀hónúhàn tí Tinubu bá gbà ipò Ààrẹ àyàfi... - Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́

aworan awon osise

Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC ni oun ṣetan lati wọ ṣokoto kan naa pẹlu ijọba tuntun to ba mu ileri rẹ sẹ lati yọ igunwọ ori epo.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ mejeji ni ti ijọba Bola Tinubu ba kọ lati se atunṣe to yẹ si awọn ibudo ifọpo ti ijọba ati awọn ibudọ ifọpo alabọde aladani, ti ijọba Bola Tinubu ba si kọ lati ṣe eyi awọn oṣiṣẹ yoo gunle iwọde jakejado Orilẹede yii.

Aarẹ Muhammadu Buhari ti kede ṣaaju wi pe oun yoo yọ owo igunpa ori epo ki o to lo saa rẹ tan gẹgẹ bi aarẹ.

Minisita eto isuna Naijiria, Zainab Ahmed ni eto idibo ọdun yii ati ilana ikaniyan Orilẹede yii lo faa ti yiyo owo igunpa ori epo se duro na.

Minisita fun awọn osisẹ,Chris Ngige ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn oniroyin ni ijọba Aarẹ Buhari yo gbe ilana a tele lati yoo owo igunpa ori epo fun ijọba tuntun Bola Tinubu to nbọ.

Hakeem Ambali aarẹ awọn osisẹ ijọba ibilẹ to tun jẹ akapo ẹgbẹ osisẹ nii,awọn osisẹ ko fọwọ si ilana yii.

Ambali ni “awa osisẹ ko fọwọ si yiyo igunpa owo epo titi ti ijọba yoo fi ṣe atunṣe to yẹ si awọn ibudo ifọpo, ki wọn si mu ilana tuntun ba awọn ile iṣẹ ifọpo aladani”.

Adari osisẹ ni, o ṣe ni laanu wi pe ninu gbogbo awọn orilẹede agbaye ti wọn ni epo rọbi orilẹede Naijiria nikan ni ko ni eroja lati fọ epo fun ra rẹ.

“Ẹ jẹ ki ijọba fun awọn oniṣowo aladani ni asẹ lati fọ epo fun lilo labẹle”.

Titus Amba adari awọn olukọ lorilẹede yii ni, gbogbo igbesẹ ti ẹgbẹ osisẹ orilẹede yii ba gbe ni awọn fọwọ si.

Igba keji aarẹ ẹgbẹ osisẹ TUC Tommy Etim ni “owo igunpa ori epo ti ijọba n pariwo jẹ irọ nitori, ojojumo ni owo epo yatọ sii “igunpa wo wa ni ijọba n parọ mo? a ti kọja igba ti ijọba le fi igunpa ori epo halẹ mo wa.”

Imoran wa fun ijọba ni wi pe ki wọn ma parọ fun wa mo, ki wọn wa ojutu si ọrọ awọn ile ifọpo ijọba ki wọn si ṣiṣẹ.”

“Owo ti wọn ni awọn san gẹgẹ bi owo iranwọ ori epo ki wọn fi tun awọn ile isẹ ifọpo wa se, ki wọn si se atunse si owo osu awọn osisẹ”.