"Mo lo ọdún mẹ́ta ní aṣálẹ̀ Sahara, oṣù mẹ́jọ lẹ́wọ̀n Libya ati Algeria, kí n le dé Yúróòpù àmọ́..."

Oríṣun àwòrán, NEMA/FACEBOOK
Ajọ NEMA to n ri si isẹlẹ pajawiri ni Naijiria, ti ko ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria to ha si ajo pada wa si Naijiria.
Ninu awọn to pada wale lati ri ọkunrin mẹrindinladọrin, obinrin mẹtadinlọgbọn ati ọmọde mẹtadinlọgota.
Ọpọ awọn to sẹsẹ pada wale naa lo wa lati Kano, Bauchi, Kaduna, Katsina, Benue ati Ipinlẹ Abia.
Lara awọn to pade wọn ni papakọ ofurufu Aminu Kano ni adari ajọ NEMA ni Kano, ajọ Red Cross ati ile iṣẹ Ọtẹlẹmuyẹ.
Bakan naa ni ile isẹ aabo ara ẹni ni aabo ilu ati awọn ajọ miran to ni nnkan se pẹlu ajọ NEMA wa ni papakọ ofurufu lati ki awọn eeyan naa kaabọ.

Oríṣun àwòrán, NEMA/Facebook
"Iya jẹ mi pupọ, ọdun mẹta ni mo lo ninu aṣalẹ Sahara tori mo fẹ jẹ eeyan laye"
Bẹẹ si ni bi ọpọ ọdọ orilẹede yii ti n gbiyanju lati “japa” si ilẹ okere, o yẹ ka fi iriri awọn eeyan to ti gbiyanju saaju lati lọ lọna aitọ yii se arikọgbọn.
Ọkan lara awọn ọmọ Naijiria to si sẹsẹ de pada lati ilẹ Yuroopu ti NEMA ki kaabọ si Naijiria ni Izeh Solomon.
Ọmọ bibi ipinlẹ Abia ni, o si wa lara awọn aadọjọ ọmọ orilẹede yii, ti ajọ NEMA gbe pada lati orilẹede Niger.
Nigba to n sọ iriri ati ilakọja to ri nitori o fẹ gba ọna aitọ wọ Germany, Izeh salaye, ilẹ kun lori ohun ti oju rẹ ri.
Izeh Solomon, ninu alaye rẹ ni ẹẹdẹgbẹta dọla ti yoo gbe oun de Libya ni oun sa fun, ti oun fi bọ sọwọ.
O ni ”nigba ti mo n gbiyanju lati sọda lati Libya lọ si Yuroopu lori okun, wọn fi mi si atimọle fun osu mẹfa ni orilẹede Algeria, mo si wa lẹwọn fun osu meji.
Iya jẹ mi pupọ, ọdun mẹta ni mo lo ninu aṣalẹ Sahara, bi mo ti n gbiyanju ati lọ si Germany ki nle jẹ eeyan."
Ajọ NEMA ni gbogbo awọn to pada wale ni yoo kopa ninu eto ẹkọsẹ, ti wọn yoo si pese owo diẹ fun wọn lati da durọ.
Abdullahi wa rọ awọn to sẹsẹ de naa lati bọwọ fun ofin Orilẹede yi, ki wọn si yago fun oun ti yoo sọ wọn di ero ẹwon.
Wo irú ìyà tí ìjọba UK, US fẹ́ fi jẹ àwọn ọmọ Nàìjíríà tó fa rògbòdìyàn lásìkò ìbò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba Ile UK ati orilẹede Amẹrika ti bu ẹnu atẹ lu bi rogbodiyan se bẹ silẹ lasiko ibo, eyi to fa ija ẹlẹyamẹya, titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ ati awọn kudiẹkudiẹ miiran to waye lasiko ibo gomina ati ile igbimọ asofin ipinlẹ to waye lọsẹ to kọja.
Orilẹede mejeeji ninu atẹjade ọtọọtọ ni awọn ṣetan lati fi ofin de iwe irina ẹnikẹni ti wọn ba kẹfin pe o lọwọ ninu bi rogbodiyan ṣe bẹ silẹ lasiko ibo.
"Ijọba ilẹ UK ti ṣetan lati gbe igbesẹ tako awọn to lọwọ ninu bi wọn ṣe da eto idibo ru ati awọn nnkan miiran to lodi si ofin eto idibo ati pe awọn eeyan ko ni ni anfani lati gba Fisa nitori wọn ti sẹ sofin to lodi si ẹtọ ọmọniyan."
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Kọmisọna agba ile UK, Atinuke Akande Alege fi lede, o ni ajọ ọhun ti se akojọpọ awọn ẹri lati fi gbe igbesẹ to tako awọn eeyan to kopa ninu bi rogbodiyan se bẹ silẹ lasiko ibo.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
"Awọn ọmọ ẹgbẹ alamojuto wa kẹfin rogbodiyan ati titẹ oju awọn oludibo mọlẹ ni ọpọ igba nibi ti ibo ti waye.
"A gbọ iroyin, ti a si ni ẹri lọwọ lori bi awọn kan ṣe ra ibo, ija ẹlẹyamẹya ati bi awọn janduku kan ṣe ji apoti ibo gbe lasiko ti ibo n lọ lọwọ ni awọn ipinlẹ kọọkan paapa julọ Ipinlẹ Eko, Rivers ati Enugu."
Atẹjade naa fi kun un pe ilẹ UK kọminu lori lilo ẹlẹyamẹya, ẹsin ati ede ti awọn oloṣelu kan fi n fa rogbodiyan lorilẹede Naijiria.
Bakan naa ni ijọba ilẹ Amẹrika ti sọ pe eto idibo naa ko lọ bi awọn ọmọ Naijiria ṣe lero.
Aṣoju ijọba ilẹ Amẹrika si Naijiria, Mary Beth Leonard, lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan.
Leonard sọ pe ọpọ araalu lo n binu ti inu wọn ko si dun si esi ibo naa, bo tilẹ jẹ pe awọn kan n ṣajọyọ pe esi ibo ọhun lọ bi awọn ṣe fẹ.
O ni "O han gbangba pe gbogbo bi eto idibo ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji ṣe lọ kuna lati ri bi awọn ọmọ Naijiria ṣe lero."
"Mo ti sọ lọpọ igba ṣaaju eto idibo naa pe Naijiria ti ṣe ọpọ aṣeyọri ni nnkan bii ogun ọdun sẹyin lẹyin to ti pada si ijọba awa arawa, ati pe bo ṣe n ṣe eto idibo rẹ wa lara awọn aṣeyọri ọhun."















