Abia bọ́ sábẹ́ àkóso LP, Alex Otti di gómìnà tuntun; Wo àwọn olùdíje tó borí káàkiri Nàìjíríà

Abajade esi ibo Abia

Esi idibo si ipo gomina ni ipinlẹ mẹtadinlọgbọn ninu mejidinlọgbọn to waye lọjọ Abamẹta, ọjọ kejidinlogun oṣu kẹta ọdun 2023 lorilẹede Naijiria lo tii wọle bayii.

Ninu awọn ti ajọ eleto idibo ni Naijiria, INEC ti kede, APC lo bori lawọn ipinlẹ marundinlogun, PDP wọle ni ipinlẹ mẹsan, LP wọle ni ipinlẹ kan, NNPP si wọle ni ipinlẹ Kano nikan.

Gomina meje labẹ ẹgbẹ oselu APC lo pada fun saa keji: Babajide Sanwo-Olu (Eko), Dapọ Abiọdun (Ogun), Abdulrahaman AbdulRazaq (Kwara), Inuwa Yahaya (Gombe), Mai Mala Muni (yobe), Abdullahi Sule (Nasarawa) ati Babangana Zulum (Borno).

Ni ẹgbẹ oṣelu PDP gomina meji lo n pada fun saa keji labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu naa: Seyi Makinde (Ọyọ) ati Bala Mohammed (Bauchi)

Eyi lawọn gomina ti ajọ INEC ti kede lẹyin idibo ọjọ Satide:

Ipinlẹ Abia – Alex Otti (LP)

Aworan idibo

Ajọ eleto idibo Naijiria kede orukọ Alex Otti gẹgẹ bi gomina tuntun ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan ni ipinlẹ Abia.

Otti to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu Labour Party, LP ni ibo 175,466 lati gbẹyẹ mọ oludije PDP, Okey Ahiwe to ni ibo 88,526.

Ipinlẹ Enugu – Peter Mbah (PDP)

Aworan esi idibo

Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC ti kede oludije fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Peter Mbah gẹgẹbi olubori idibo sipo gomina ni ipinlẹ Enugu.

INEC kede pe Mbah ni ibo ẹgbẹrun lọna ọgọjọ ati ẹgbẹrin o le aadọrun ati marun un (160, 895); lati fi ajulọ han oludije ẹgbẹ oṣelu Labour party, LP Chijioke Edeoga to ni ibo ẹgbẹrun mẹtadinlọgọjọ ati ẹẹdẹgbẹta o leaadọta ati meji (157,552) nibi ibo gomina to waye lọjọ kejidinlogun oṣu kẹta ọdun 2023.

Ibo ẹgbẹrun mẹrinla ati ọrinlelẹẹdẹgbẹta o din marun (14,575) ni ẹgbẹ oṣelu APC ni ninu esi idibo naa.

Ipinlẹ Gombe – Muhammad Yahaya (APC)

Ni ipinlẹ Gombe, Muhammad Yahaya gba saa keji pẹlu lẹyin ti ajọ INEC kede pe ibo rẹ lo pọ julọ pẹlu ibo 342,821 kọja oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP Muhammad Barde to ni ibo 233,131 ti oludije NNPP, Khamisu Mailantarki si ni ibo 19,861.

Ipinlẹ Eko – Babajide Sanwo-Olu (APC)

Aworan esi idibo

Babajide Sanwo-Olu ti ẹgbẹ oṣelu APC ko ibo 762,134 lati fagba han Gbadebọ Rhodes-Vivour ti ẹgbẹ oṣelu LP to ni 312,329.

Ipinlẹ Akwa Ibom – Umo Eno (PDP)

Ni ipinlẹ Akwa Ibom Umo Eno ni gomina tuntun nibẹ pẹlu ibo 356,346 lati gbẹyẹ mọ oludije YPP ti oun ni ibo 136,262 ati oludije APC to ni ibo 129,602.

Ipinlẹ Ọyọ- Ṣeyi Makinde (PDP)

Aworan esi idibo

Gomina Seyi Makinde ti ẹgbẹ oṣelu PDP gba saa keji pẹlu ibo 563,756 lati fi ajulọ han Teslim Fọlarin APC to ni 256, 685 ati Adebayọ Adelabu ti Accord party to ni ibo 38, 357.

Ipinlẹ Yobe – APC

Gomina Buni gba tikẹti saa keji gẹgẹ bi gomina ni ipinlẹ Yobe pẹlu ibo 317,113 nigbati oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Sharif Abdullahi ni ibo 104,259 lati gbe ipo keji.

Ipinlẹ Ogun – Dapọ Abiọdun (APC)

Aworan esi idibo

Gomina Dapọ Abiọdun ti ẹgbẹ oselu APC gba saa keji pẹlu ibo 276,298 lati gbẹyẹ mọ Ọladipupọ Adebutu ti PDP to ni ibo 262,383.

Ipinlẹ Jigawa – Namadi Dammodi (APC)

Ni ipinlẹ Jigawa, oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Namadi Dammodi ni gomina tuntun nibẹ. Ibo 618,449 lo ko lati fi idi oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Lamido Mustapha to ko ibo 368,726 janlẹ.

Ipinlẹ Kwara – Abdulrazaq Abdulrahaman(APC)

Aworan esi idibo

Gomina Abdulrazaq ti ẹgbẹ oṣelu APC gba saa keji rẹ pẹlu ibo 273,424 lati kọja oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Yaman Abdullahi to ni ibo 155,490.

Ipinlẹ Taraba – Kefas Agbu (PDP)

Ọgagunfẹyinti Kefas Agbu ti ẹgbẹ oṣelu PDP lo bori ni idibo gomina ni ipinlẹ Taraba pẹlu 257,926 lati fagba han Ọjọgbọn Sani Yahaya ti ẹgbẹ oṣelu NNPP to ni ibo 202,278 ati Emmanuel Abdulaziz to ni ibo 141,592.

Ipinlẹ Katsina – Dikko Radda (APC)

Aworan esi idibo

Dikko Radda ti ẹgbẹ oṣelu APC ko ibo859,892 lati gbe oroke kọja Sẹnetọ Yakubu Lado to n dije lẹgbẹ oṣelu PDP. Lado ni ibo 486,260.

Ipinlẹ Zamfara – Dauda Lawal-Dare (PDP)

Ọmọwe Dauda Lawal-Dare ti ẹgbẹ oṣelu PDP lo yẹ aga mọ gomina to wa nipinlẹ Zamfara bayii, Bello Matawalle nidi pẹlu ibo 377,726.

Gomina Matawalle ti ẹgbẹ oṣelu APC ni ibo 311,976.

Ipinlẹ Sokoto – Aliyu Ahmed (APC)

Aworan esi idibo

Aliyu to jẹ igbakeji gomina ipinlẹ naa, Aminu Tambuwal ko to yi babanriga pada bọ si ẹgbẹ oṣelu APC lo bori pẹlu ibo 453,661 lati fi ajulọ han Umar Saidu ti ẹgbẹ oṣelu PDP to ni ibo 404, 632.

Ipinlẹ Niger – Umar Bago (APC)

Alhaji Umar Mohammed Bago ti ẹgbẹ oṣelu APC lo gbegba oroke ni idibo gomina ni ipinlẹ Niger.

Bago to jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofinṣoju lorilẹede Naijiria bayii ni ibo 469,896 lati gbẹyẹ mọ Alhaji Liman Kantigi ti ẹgbẹ oṣelu PDP lọwọ.

Ibo 387,476 ni Kantigi ni.

Ipinlẹ Kaduna – Sẹnetọ Uba Sani (APC)

Aworan esi idibo

Sẹnetọ Uba Sani, oludije fun ẹgbẹ oṣelu APC ni yoo ma gba ọpa aṣẹ lọwọ gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai.

Ibo 730,002 ni Sẹnetọ Uba Sani ni latifi moke mọ Isah Ashiru ti ẹgbẹ oṣelu PDP to ko ibo 719, 196 jọ.

Oludije ẹgbẹ oṣelu Lp ni ibo 58,283, NNPP si ni ibo 21,405.

Ipinlẹ Cross River – Bassey Otu (APC)

Ni ilu Calabar lọjọ Aje, Ajọ INEC kede Ọmọọba Bassey Edet Otu ti ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹbi ẹni ti awọn eeyan ipinlẹ naa ṣẹṣẹ dibo yan gẹgẹ bi gomina tuntun nibẹ pẹlu ibo258,619.

Oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnetọ Sandy Onor ni ibo 179,636

Ipinlẹ Delta – Sheriff Oborevwori (PDP)

Aworan esi idibo

Ni ipinlẹ Delta, Oloye Sheriff Oborevwori ti ẹgbẹ oṣelu PDP lo bori pẹlu ibo 360,234 lati na olori igbakeji aarẹ ile aṣofin agba Naijiria, Sẹnetọ Ovie Omo-Agege ti ẹgbẹ oṣelu APC to ni ibo 240,229.

Ipinlẹ Plateau – Caleb Mutfuwang (PDP)

Oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Caleb Mutfuwang ni aga ipo gomina ipinlẹ Plateau ja mọ lọwọ pẹlu ibo 525,299.

Mutfuwang fi idi oludije ẹgbẹ oṣelu APC Nentwae Yilwatda janlẹ ni ibo gomina to waye lọjọ kejidinlogun oṣu kẹta ọdun 2023.

Ibo 481, 370 ni oludije APC naa ni.

Ipinlẹ Ebonyi – Francis Nwifuru (APC)

Aworan esi idibo

Ọgbẹni Francis Nwifuru ni ajọ INEc kede gẹgẹ bi olubori ibo gomina ni ipinlẹ Ebonyi pẹlu ibo 199,131.

Oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP, ọgbẹni Ifeanyi Odii lo ṣe ipo keji pẹlu ibo 80,191.

Ipinlẹ Nasarawa – Abdullahi Sule

Gomina Abdullahi Sule n pada fun saa keji gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Nasarawa.

Ibo 347,209 ni gomina Sule to dije labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ni, nigbati oludije fun PDP, David Ombugadu ni ibo 283,016.

Ipinlẹ Bauchi – Bala Mohammed – APC

Aworan esi idibo

Oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnetọ Bala Abdulkadir Mohammed ni ajọ INEC kede gẹgẹ bi olubori ibo gomina naa ni ipinlẹ Bauchi.

Sẹnetọ Bala Mohammed n pada fun saa keji pẹlu ibo 525,280; nigbati Ọgagunofurufufẹyinti Sadiq Abubakar ti ẹgbẹ oṣelu APC ni ibo 432,272.

Ipinlẹ Borno – Ọjọgbọn Babangana Zulum (APC)

Ọjọgbọn Babangana Umara Zulum ri tikẹti saa keji gba lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Borno.

Ibo 545,543 ni awọn eeyan ipinlẹ naa fi gbe Zulum pada fun saa keji lati gbẹyẹ mọ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Mohammed Ali Jajari to ni ibo 82,147 lọwọ.

Ipinlẹ Kano – Abba Yusuf (NNPP)

Aworan esi idibo

Abba Yusuf, oludije fun ẹgbẹ oṣelu NNPP ni gomina tuntun ni ipinlẹ Kano.

Ẹgbẹ oṣelu NNPP n gba akoso iṣejọba ipinlẹ naa kuro lọwọ ẹgbẹ oṣelu APC pẹlu ibo to le ni miliọnu kan, 1,019,602.

Ibo 892,705 ni Nasiru Gawuna ti ẹgbẹ oṣelu APC ni.

Ipinlẹ Benue – Hyacinth Alia (APC)

Alufa ijọ Aguda, Hyacinth Alia lo jawe olubori gẹgẹbi gomina ipinlẹ Benue bayii.

Alufaa Alia ko ibo 473,933 lati fi idi oludije ẹgbẹ oṣelu PDP Titus Uba janlẹ.

Titus Uba ni ibo 223,913.

Ipinlẹ Rivers – Sim Fubara (PDP)

Oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Sim Fubara lo bori gẹgẹbi gomina ipinlẹ Rivers.

Fubara ko ibo 302,614 jọ lati lewaju Tonye Cole to n dije fun ẹgbẹ oṣelu APC.

Tonye Cole ni ibo 95,274, nigbati Beatrice Itubo to n dije lọ́bẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, LP ni ibo 22,224.

INEC

Bi INEC se n kede esi idibo awọn ipinlẹ lorilẹede Naijiria ni awọn Oludije kan n ki arawọn ku orire, ti awọn miiran di n fapa janu pe kudiẹkudiẹ wa ninu ilana ti eto idibo naa fi waye.

Bakan naa ni a ni awọn ipinlẹ kan ti INEC kede awọn ti dawọ ikede duro nitori pe wọn kẹfin awọn kudiẹkudiẹ ninu esi idibo naa

BBC Yoruba se akojọpọ awọn ipinlẹ ti INEC ti kede ẹni to bori esi idibo ati awọn ipinlẹ ti wọn ti kede idaduro ikede esi ibo.

INEC

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ọjọ Ajẹ, ogunjọ oṣu kẹta ni INEC ti bẹrẹ lati maa kede esi ibo ni awọn ipinlẹ ti idibo Gomina ati ile igbimọ aṣofin ti waye

Ti a ko ba gbagbe eto idibo ti waye ni awọn ipinlẹ kan saaju ọdun eto idibo 2023 nipinlẹ Osun, Ondo, Ekiti, ati Anambra.

Ajọ INEC ti kede esi ibo nipinlẹ mejinlelogun, ti ẹgbẹ oṣelu APC, PDP ati NNPP si pese awọn oludije to jawe olubori ninu awọn ibo naa

Ẹgbẹ oṣelu PDP bori nipinlẹ mẹfa, APC nipinlẹ mẹdogun ti ẹgbẹ oṣelu NNPP si bori nipinlẹ kan, eyiu ni ipinlẹ Kano.

PDP bori ni Plateau, Bauchi, Oyo, Delta Rivers ati Akwa Ibom.

APC jawe olubori nipinlẹ Sokoro, Katsina, Jigawa, Gombe, Lagos. Kwara, Niger Yobe, Nasarawa, C'Rivers, Ebonyi, Ogun, Benue, Kaduna ati Borno.

Nipinlẹ Ogun, Lagos, Kaduna ati Katsina awọn oludije to fidi rẹmi ti ke gbari sita pe awọn ko tẹwọgba esi ibo rara, to sise lati morile ileẹjọ lati ja fun nnkan ti wọn pe ni ẹtọ wọn.

Orukọ awọn gomina, ipinlẹ ati ẹgbẹ oṣelu wọn

Maapu
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ipinlẹ Oyo-

Oluseyi Makinde lati ẹgbẹ oṣelu PDP fun saa keji,

Ipinlẹ Eko-

Babajide Sanwoolu lati ẹgbẹ oṣelu APC fun saa keji,

Ipinlẹ Ogun-

Dabo Abiodun lati ẹgbẹ oṣelu APC fun saa keji ,

Ipinlẹ Kwara-

Abdulrahman Abdulrazaq lati ẹgbẹ oṣelu APC fun saa keji,

Ipinlẹ Yobe-

Mai Mala Buni lati ẹgbẹ oṣelu APC fun saa keji,

Ipinlẹ Gombe-

Muhammadu Yahaya lati ẹgbẹ oṣelu APC fun saa keji,

Ipinlẹ Sokoto-

Ahmed Sokoto lati ẹgbẹ oṣelu APC,

Ipinlẹ Jigawa -

Namadi Dammodi lati ẹgbẹ oṣelu APC ,

Ipinlẹ Kano-

Abba Yusuf lati ẹgbẹ ẹgbẹ oṣelu NNPP,

Ipinlẹ Akwa Ibom-

Umo Eno lati ẹgbẹ oṣelu PDP,

Ipinlẹ Katsina-

Dikko Radda lati ẹgbẹ oṣelu APC,

Ipinlẹ Kaduna-

Uba Sani lati ẹgbẹ oṣelu APC,

Ipinlẹ Benue-

Hyacinth Alia lati ẹgbẹ oṣelu APC,

Ipinlẹ Cross Rivers-

Bassey Otu lati ẹgbẹ oṣelu APC,

Ipinlẹ Niger-

Mohammed Umar Bago lati ẹgbẹ oṣelu APC,

Ipinlẹ Delta-

Sheriff Oborevwori lati ẹgbẹ oṣelu PDP,

Ipinlẹ Plateau-

Mutfwang lati ẹgbẹ oṣelu PDP,

Ipinlẹ Ebonyi-

Nwifuru Declared lati ẹgbẹ oṣelu APC,

Ipinlẹ Bauchi-

Bala Mohamed lati ẹgbẹ oṣelu PDP,

Ipinlẹ Borno-

Babagana Umara Zulum lati ẹgbẹ oṣelu APC

Awọn ipinlẹ wo ni INEC ti kede idaduro ati pe ki ni idi?

Ipinlẹ Abia, Enugu, Kebbi Imo, ati Ipinlẹ Adamawa ni awọn ipinlẹ ti INEC ti kede pe idaduro wa lori ikede esi ibo gomina wọn.

Ajọ INEC nipinlẹ Adamawa, Enugu, Abia, Imo ati ipinlẹ Kebbi ti kede dida kika ikede esi ibo gomina duro lẹyin ti wọn kẹfin kudiẹkudiẹ ninu esi ibo naa.

INEC ni awọn gbe igbesẹ naa nitori bi esi ibo ko se jọ ara wọn ati kudiẹkudiẹ to waye lasiko eto idibo naa.

Bakan naa ni INEC ni idibo ile igbimọ asofin ipinlẹ Sokoto ko kẹsẹjari.