Rukayat Motunrayo Shittu: Àwọn ìdí tí ìpò yìí fi tọ́ sí Rukayat nìyí
Rukayat Shittu, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn obinrin to bori ibo sile igbimọ asoju aṣofin ipinlẹ Kwara ti ransẹ ikini si awọn eeyan agbegbe rẹ to jade dibo fun un ninu eto idibo to waye lọjọ Satide.
Ajọ INEC kede Rukayat Shittu gẹgẹ bi ẹni bori ibo naa lẹyin to ni apapọ ibo to ju ẹgbẹrun meje lọ lati fi idi akẹgbẹ rẹ, lati ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Abdullah Magaji janlẹ.
Lasiko to n fi ẹmi imoore han loju opo ibanidọrẹ Facebook rẹ, Rukayat ni oun dupẹ lọwọ awọn eeyan agbegbe rẹ fun bi wọn ṣe fun ni anfani lati soju wọn.
Mo kọ̀ láti jẹ́ ìyàwó ilé tàbí ìyà ọmọ lásán- Rukayat Motunrayo Shittu.
Emi kò díje dupò lati lọ kówó jẹ rara- Rukayat Shittu.
Eni ọdun mẹrindinlọgbọn obinrin to n dije dupo aṣoju-ṣofin sile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara ni BBC Yoruba ti wa kan bayii.
O salaye idi pataki to se fẹ dije dupo ni Owode onire ni ijoba ibile Asa ni ipinle Kwara.
- Òpó iná ‘’National Grid’’ tún bàjẹ́ iná ọba tún lọ!
- Ìtẹ̀síwájú àwọn eèyàn Ekiti ló jẹ́ mi lógún- Kemi Elebute Halle
- Wo àwọn àwòràn tó làmìlaaka nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ Adúláwọ̀ lọ́sẹ̀ tó kọjá
- Orangun: Ègún ni kí ǹkan wa má wù àwa gangan ti a ni ǹka náà
- Èrèdí tí mi ò ṣe ní ìbò kankan níbi ètò ìdìbò abẹ́nú APC l’Abuja rèé - Bakare
- Lẹyìn tó tẹ ìyá arúgbó 70 pa, erin padà wá lọ́jọ́ ìsìnkú láti wá gbé òkú sálọ
Ta ni Rukayat Shittu?
Ọdun 1996 ni wọn bi omidan Rukayat Shittu
O jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn bayii.
O kawe gboye nile ẹkọ National Open University ni Naijiria.
O jẹ ọmọ bibi ilu Manyan ni Owode Onire ni ijoba ibile Asa ni ipinle Kwara ni aarin gbungbun Naijiria.
Rukayat salaye awọn ohun to gbe e dide ati bi ọpọ sẹ n satileyin fun un nipinle Kwara fun BBC Yoruba.
