Òpó iná ‘’National Grid’’ tún bàjẹ́ iná ọba tún lọ!
National Grid Collapse: Ìgbà 17 rèé ní 2023 tí iná ọba ní Naijiria paná pi

Oríṣun àwòrán, Google
Ileeṣẹ apin-ina-ka ni ipinlẹ Kaduna ti kede pe opo ina ọba ti gbogboogbo ti bajẹ fun igba kẹtadinlogun ninu ọdun yii.
Igbakigba ti ina ọba naa ba lọ ni kii si ina ni awọn agbegbe kan kaakiri Naijiria
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ apin-ina-ka ni Kaduna fi lede ni wọn ti ni ipinlẹ Kaduna ati awọn agbegbe kan ko ni ina ọba nitori ẹka kan lati ‘national grid’ to n pin fun wọn ti bajẹ.
‘Nitori naa wọn kesi awọn onibara wọn lati mu suuru atiwi pe ina ọba yoo pada laipẹ.’
Amọ koi tii han si gbangba awọn ipinlẹ ti ina ọba to bajẹ naa kan.
Eleyii jẹ ko jẹ igba kẹtadinlogun ti ina ọba yoo ma bajẹ laarin ọdun 2022 yii nikan.
Bi o tilẹ jẹpe wọn ko fi lede lọpọ igba ti ina ọba naa ba bajẹ nitori kii pe ti wọn ma a tun tunṣe.
Amọ igba miran wọn maa n fi to araalu leti ki wọn le gbaradi fun gbogbo igba ti wọn maa fi wa ni okunkun lai ni ina, ki wọn to tunṣe pada.












