'Àwa kò ní lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tí kò bá ti sí oúnjẹ fún wa mọ́'

Àwọn olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ ní orílẹ̀ èdè South Sudan tí ṣèkìlọ̀ wí pé ó ṣeéṣe kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sá kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ nítorí bí àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, United Nations ṣe ń gbèrò láti ṣe ìdádúró fífún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní oúnjẹ.
Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹfà ní àjọ UN kéde pé àwọn yóò dín ènìyàn mílíọ̀nù mẹ́fà àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba kù nínú àwọn ènìyàn tí àjọ náà ń fún ni oúnjẹ nítorí ọ̀dá owó.
Lára àwọn ènìyàn tí ìgbésẹ̀ yìí yóò ṣe àkóbá fún ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó tó ẹgbẹ̀rún méjìdínlọ́gọ́sàn-án tí UN ń fún ní oúnjẹ ní ilé ẹ̀kọ́.
Ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà, Anita Anna Samson, ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún, tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Mayo Girls Primary School ní Juba ní bí kò bá ti sí oúnjẹ, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kò ní wá sí ilé ẹ̀kọ́.
Anita pàrọwá sí UN láti tẹ̀síwájú nípa pípèsè oúnjẹ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni yóò kó ìpalára bá tí àwọn kò bá fi rí oúnjẹ mọ́.
Ó ní òun gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan, òun kò ní lọ sí ilé ẹ̀kọ́ mọ́ nítorí àwọn òbí òun kò ní oúnjẹ tí wọ́n yóò fún òun.
Akẹ́kọ̀ọ́ màáràn tó jẹ́ ọmọọdún mẹ́tàdínlógún, Ijora Jovian náà tẹmpẹlẹmọ wí pé ipa tí pípèsè oúnjẹ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kò kéré rárá.
Jovian ní ètò náà fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní àǹfàní láti máa wá sí ilé ẹ̀kọ́ ní àsìkò àti ìgbà gbogbo nítorí wọ́n mọ̀ wí pé àwọn yóò jẹun òwúrọ̀ àti ti ọ̀sán kí wọ́n tó lọ sílé tó sì máa ń mú wọn dúró sí ilé ẹ̀kọ́.
Igbákejì olùkọ́ àgbà ilé ẹ̀kọ́ náà, Thomas Hakim Sebit náà ní ohun ìbànújẹ́ ni ìkéde náà jẹ́ fún àwọn nítorí ó máa ṣàkóbá fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àwọn akẹ́kọ̀ọ́.
Sebit ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kò ní wá sì ilé ẹ̀kọ́ mọ́ tí wọ́n ṣe ìdádúró ètò náà.
Bákan náà ló pàrọwà sí àwọn UN láti tún tẹ̀síwájú nípa ṣíṣe àtìlẹyìn fún ètò fífún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní oúnjẹ kí àwọn ọmọ tí yóò máa wá sí ilé ẹ̀kọ́ náà le máa pọ̀ si.
Wo àwọn àwòràn tó làmìlaaka nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ Adúláwọ̀ lọ́sẹ̀ tó kọjá

Oríṣun àwòrán, AFP
Awọn akẹkọọ kan ni orilẹ-ede South Africa ṣebi ẹlẹgbẹ ti awọn mii ni wọn dibọn bii oku nibi ayẹyẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Africa last week: Wo àwọn àwòràn tó làmìlaaka nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ Adúláwọ̀ lọ́sẹ̀ tó kọjá

Oríṣun àwòrán, EPA

Oríṣun àwòrán, Reuters

Oríṣun àwòrán, EPA

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oríṣun àwòrán, EPA

Oríṣun àwòrán, AFP

Oríṣun àwòrán, AFP












