Russia gbà pé òun lẹ́bi lórí ìkọlù Ukraine àmọ́ ó ní ojú kò tì òun

Mínísítà fọ́rọ́ ilẹ̀ òkèèrè ní Russia sọ pé àwọn kò sọ pé awọn kò jẹ̀bí dídojú ogun kọ Ukraine àmọ́ awọn kò ṣe ohun tó burú

Sergel Lavrov

Láti ìgbà tí ikọ̀ ọmọ ogun Russia tí kọlu orílẹ̀èdè Ukraine losu mẹrin sẹ́yìn, ẹgbẹlẹgbẹ aráàlú lo ti kú, tí wọn sì ti ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilegbe jẹ, tí àìmọye mílíọ̀nù ọmọ Ukraine si ti sá kúrò nílé wọn.

 Àmọ́ ní Ọjọ́bọ, mínísítà fọrọ ilẹ̀ òkèèrè ni Russia, Sergel Lavrov wo mi loju koroju, to si sọ fun mi pe nnkan ko ri bí wọn ri.

 "A kò kọlu Ukraine, a kàn ṣe ifilọlẹ akanse isẹ ologun nibẹ ni, torí ko si ba ṣe le salaye fáwọn orílẹ̀èdè agbaye pé wiwọ Ukraine lọ sinu àjọ NATO jẹ iwa ọ̀daràn."

Bakan naa lo ti ikede ilẹ̀ Russia lẹyin pe awọn ologun Nazi wa nílẹ̀ Ukraine, to si jẹ pe awọn gan ni àwọn fẹ́ le jade lorilẹede naa.

 Lavrov yii si lo ti da awuyewuye silẹ lọpọlọpọ igba pẹlu bo ṣe so aarẹ ilẹ̀ Ukraine to jẹ ẹ̀yà Júù pọ mọ awọn ologun Nazi lati Germany.

Ọ̀pọ̀ igba si lo ní ẹ̀jẹ̀ Adolf Hitler wa lara awọn Júù, eyi to n bi awuyewuye.

 Akọroyin BBC wa bi nipa àkọsílẹ̀ àjọ ìṣọ̀kan agbaye kan tí wọn gbé jáde nípa abule Yiddish lẹkun Chernihiv nibi ti ọmọ ogun Russia ti kan nipa fáwọn eeyan bii ọtalelọọdunrun lati kuro nibẹ.

 Lara àwọn èèyàn naa la tí ri ọmọde merinlelaadọrin àti akanda ẹda márùn-ún, ti wọn si ni ki wọn lọ maa gbe lábẹ́ ilé ẹ̀kọ́ kan.

 Ọjọ́ mejidinlọgbọn ni àwọn èèyàn náà lo lábẹ́ ile ẹ̀kọ́ naa, ti eeyan mẹwa si ku ninu wọn.

 Ko sì ile iyagbẹ, omi àtàwọn ohun eelo amayedẹrun nibẹ, tí Akọroyin BBC si n beere pe ṣe ara ogun ti Russia n gbe táwọn ologun Nazi naa ree?

Aarẹ Amẹrika, Biden, aarẹ Russia, Putin ati Lavrov ati asaaju ijọba mii

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àmọ́ Levrov ni ibanujẹ nla gbaa ni iṣẹlẹ naa amọ àjọ United Nations maa n kún awọn orilẹ-ède alágbára lágbàyéé lẹ́yìn láti pa irọ ni.

 "Kii ṣe pe orílẹ̀èdè Russia ko kuku ní ẹbí tiẹ̀ àmọ́ oju ko ti wa lati sọ iru èèyàn ta jẹ."

 Ẹni ọdun merinlelaadọrin ni Lavrov, to si ti wá nípò minisita fún ọdún méjìdínlógún àmọ́ táwọn orílẹ̀èdè agbaye tí fi òfin de òun àti ọmọbìnrin rẹ.

 Ilẹ̀ Amẹ́ríkà lo fi ẹ̀sùn kàn pe oun lọ ń tàn ìròyìn èké kalẹ nípa Ukraine.