Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ Musulumi láṣẹ láti máa wọ Hijab nílé ẹ́kọ́ ní ìpínlẹ̀ Eko - Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ

Ẹ̀tọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni láti wọ Hijab l’Eko - Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ

Hijab

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ti sọ pe awọn akẹkọọ to jẹ Musulumi le maa wọ ijaabu lawọn ile ẹkọ to wa nipinlẹ Eko lai si idẹyẹ si kankan.

Inu yara ile naa to wa niluu Abuja ni idajọ ọhun ti waye lọjọ Ẹti.

Ṣaaju ni ile ẹjọ kotẹmilọrun kan ti kọkọ dajọ pe awọn akẹkọbinrin to jẹ Musulumi le maa wọ ijaabu naa lawọn ile ẹkọ nipinlẹ Eko lọjọ kọkanlelogun, oṣu Keje, ọdun 2016, amọ idajọ naa ko tẹ ijọba ipinlẹ Eko lọrun.

Eyii lo mu ijọba Eko gba ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria lọ ninu oṣu Keji, ọdun 2017, lati tako idajọ ti ile ẹjọ kọtẹmilọrun naa da.

Iwe ẹjọ naa to ni nọmba CA/L/135/15lo n waye laarin ijọba ipinblẹ Eko ati arabinrin kan, Aisat Abdulkareem, arabinrin Moriam Oyeniyi ati ẹgbẹ awọn akẹkọọ tojẹ Musulumi ni Naijiria.

Igbẹjọ laarin awọn obinrin yii ati ijọba Eko waye lẹyin ti adajọ Mudupe Onyeabo ti ile ẹjọ giga kan ni Ikeja, nipinlẹ Ekọ ti kọkọ fofin de lilo ijaabu lawọn ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati ile ẹkọ girama kaakiri ipinlẹ naa.

Ẹgbẹ awọn Musulumi ọhun sọ pe ofin ti ile ẹjọ naa fi de ijaabu lilo n ṣafihan idẹyẹsi awọn akẹkọọbinrin to jẹ Musulumi l’Eko, ko si tẹ awọn lọrun.

Idajọ ile ẹjọ

Ẹwẹ, nigba ti ile ẹjọ to ga julọ naa yo gbe idajọ rẹ kalẹ, o ni ọrọ ẹsin ni ijaabu jẹ fun awọn Musulumi, o si jẹ ọna kan gboogi ti wọn fi n sin Ọlọrun.

O ni ijaabu lilo fun awọn Musulumi ko ni da iyapa silẹ laarin awọn akẹkọọ Musuli naa atawọn akẹgbẹ wọn, bakan naa ni ko tumọ si pe awọn Musulumi n dẹyẹ si awọn akẹkọọ to ku ti kii ṣe Musulumi.

Lara awọn adajọ to wa ninu igbimọ to gbe idajọ ile ẹjọ giga julọ naa kalẹ ni; Olukayode Ariwoola, Kudirat Kekere-Ekun, John Inyang Okoro, Uwani Aji, Mohammed Garba, Tijjani Abubakar, ati adajọ Emmanuel Agim.

Ki ni awọn Musulumi sọ?

Nigab ti wọn sọrọ lori idajọ naa, Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ to jẹ Musulumi ni Naijiria, MSSN, Miftahudeen Thanni, sọ pe idajọ naa n tumọ si pe awọn Musulumi lawọn ile ẹkọ l’Eko le maa wọ ijaabu bayii lai si idẹyẹsi kankan lati ọdọ awọn akẹgbẹ wọn.

O ni idajọ ọhun yoo mu ki igabgbọ awọn eeyan gbilẹ si ninu ẹka eto idajọ Naijiria.

Lẹyin naa lo kilọ fun awọn olukọ atawọn araalu mii lati dẹkun idẹyẹsi awọn Musulumi nitori bi wọn ṣe yan lati maa mura ni ilana ẹsin wọn.