Ètò ìsìnkú alápapọ̣̀̀ fún àwọn tó kú ní ìkọlù Ọwọ ti bẹ̀rẹ̀ báyìí

Owo

Owo church Attack: Àwọn 40 ní wọn n seto ìsìnkú wọn lóní

Owo church attack
Skip Wo bi wọn ṣe n ṣeto isinku awọn to ku ni ikọlu naa nibi and continue readingWo bi wọn ṣe n ṣeto isinku awọn to ku ni ikọlu naa nibi

End of Wo bi wọn ṣe n ṣeto isinku awọn to ku ni ikọlu naa nibi

Ijo Owo

 Ijọ Catholic Diocese of Nigeria ni oni, Ọjọ kẹtadinlogun, Oṣu Kẹfa ni wọn yoo sin oku gbogbo awọn to gbẹmi mi ni ikọlu si ẹka ṣọọṣi ni ilu Ọwọ, nipinlẹ Ondo.

Awọn agbesunmọmi lo ṣekọlu si ile ijọsin St. Francis Catholic Church ni ilu Ọwọ, ti wọn si ṣina bolẹ pẹlu ado oloro lu awọn ọmọ ijọ ni asiko ẹsin ni Ayajọ Pentecost.

Gẹgẹ bi ile ijọsin naa ṣe sọ, eniyan ogoji lo ku ninu iṣẹlẹ naa, ti awọn eniyan to le ni aadọta si farapa.

Isinku ọlọgọọrọ naa ni awọn n ṣe ni itẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ni si agbegbe Emure, ni ilu Ọwọ.

Titi di asiko yii, ko i tii si ẹnikẹni ti wọn fi panpẹ ọba mu pe o lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.

Amọ ijọba apapọ ni ikọ agbesunmọmi ISWAP lo wa ni idi iṣelẹ naa amọ gomina ipinlẹ Ondo ni wọn ko le sọ bẹẹ lai ri eri to daju nipa ikọlu naa.

Orilẹede Naijiria n koju igbesunmọmi lọtun losi to fi mọ ijinigbe ati iyapa kaakiri orilẹede ọhun.