Ọmọ bibi ilu Ikogosi-Ekiti ni Biodun Abayomi Oyebanji
Oun ni amugbalẹgbẹ pataki nipa ọrọ ile asofin si gomina ipinlẹ Ekiti laarin ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 1999 si 2000, ati laarin ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ, ọdun 2000 si oṣu Kẹsan an, ọdun 2001.
Bakan naa lo tun jẹ olori osisẹ ni ọọfisi gomina nipinlẹ Ekiti laarin oṣu Kẹsan an, ọdun 2001 si ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2003.
Oyebanji tun jẹ Kọmiṣọna fun eto isuna ati aato ọrọ aje nipinlẹ Ekiti laarin ọjọ kẹwaa, oṣu Kinni, ọdun 2013, si ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2014. O tun jẹ akọwe ijọba ipinlẹ Ekiti laarin ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2018, si ọjọ keje, oṣu Kejila, ọdun 2021.
Iṣẹ: Oṣiṣẹ ijọba
Ọjọ ori: Ẹni ọdun mẹrinlelọgọta
Kolawole ni alaga ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ekiti ko to kọwe fipo silẹ ninu osu Kẹsan an, ọdun 2021, lati dije du ipo gomina nipinlẹ naa.
Oun ni Kọmiṣọna fọrọ ayika laarin ọdun 2015 si 2018 lasiko ijọba gomina Ayodele Fayose.
Bisi Kolawole lo soju ẹkun idibo Efon nile aṣofin ipinlẹ Ekiti laarin ọdun 2007 si 2011.
Ọmọ bibi ilu Efon Alaaye, nipinlẹ Ekiti ni Kolawole.
Iṣẹ: Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ
Ọjọ ori: Ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin
Segun Oni ni gomina tẹlẹ ri nipinlẹ Ekiti laarin ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2007 si ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, ọdun 2010.
O wa lara awọn to da ẹgbẹ oṣelu United Nigeria Congress Party (UNCP) silẹ l’Ekiti nibi to ti fi ọkan sin ẹgbẹ naa.
Amọ lọdun 2014 lo kuro ninu ẹgbẹ oselu PDP lọ sinu ẹgbẹ oselu APC. Lọdun 2019, wọn jawe lọ rọkun nile fun ninu ẹgbẹ oṣelu naa ni Ifaki Ekiti, to wa labẹ ẹkun ijọba ibilẹ Ido/Osi, lori ẹsun pe o n ṣe awọn nnkan to tako ilọsiwaju ẹgbẹ naa, lẹyin naa lo tẹkọ leti lọ si PDP. Ninu oṣu Keji ọdun 2022, Oni tun fi PDP silẹ lọ sinu ẹgbẹ oṣelu SDP lẹyin to fidi rẹmi ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ ọhun.
Iṣẹ: Oṣiṣẹ ijọba
Ọjọ ori: Ẹni ọdun mejilelọgọta
Ọmọ bibi ilu Emure Ekiti, to wa ni ẹkun idibo guusu Ekiti ni Adebowale Ranti Ajayi.
Ajayi ni Kọmisọna akọkọ feto isuna ati aato ọrọ aje nipinlẹ Ekiti, to si tun ti jẹ Kọmiṣọna ri fun eto katakara, idokowo ati agbekalẹ ohun ọtun labẹ isejọba Kayode Fayemi.
Ọmọ ẹgbẹ oselu APC ni Adebowale Ranti Ajayi ko to lọ darapọ mọ ẹgbẹ oselu YPP nibi to ti n dije du ipo gomina.