PDP ṣetán láti kéde olùdíje igbákejì ààrẹ fún Atiku

PDP ṣetán láti kéde olùdíje igbákejì ààrẹ fún Atiku

Aworan Atiku

Oríṣun àwòrán, Google

Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Iyiochia Ayu ti ni ki awọn eniyan ni igbagbọ ninu ẹgbẹ ati oludije fun ipo aarẹ, Atiku Abubakar lori ẹni ti yoo dije gẹgẹ bi igbakeji rẹ.

Ayu ni laarin wakati mejidinlaadọta naa ni awọn yoo fi le ẹni ti yoo dije igbakeji naa lede.

Lasiko ipade pẹlu ajọ to n ṣakoso ijiroro lori ẹni ti wọn yoo gbe fun igbakeji Atiku naa lo sọ bẹẹ.

O ni ijiroro naa da le ẹni ti wọn yoo gbe lati dije igbakeji aarẹ naa pẹlu Atiku Abubakar.

‘’Laarin wakati mejidinlaadọta, a o sọ ẹni ti yoo dije du ipo igbakeji aarẹ naa’’

Lara awọn to wa nibi ijiroro naa ni Alaga ẹgbẹ awọn gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Aminu Tambuwal; Gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed; gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom;

Ati Aarẹ Ile Igbimọ Aṣofin tẹlẹ, David Mark; gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹri, Olusegun Mimiko; gomina ipinlẹ Cross River tẹlẹ, Liyel Imoke, tofimọ Sẹnatọ Philip Aduda ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ajọ Eleto Idibo ni Naijiria,INEC ti fun gbogbo ẹgbẹ oṣelu di Ọjọ Kẹtadinlogun, Oṣu Kẹfa lati ṣe iforukọ silẹ gbogbo awọn oludije ati igbakeji wọn.