Wo àwọn tí ayé ń wò pé ó le gba ipò igbákejì Atiku nínú PDP

Wike, Atiku àti Okowa

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Bí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú gbogbo káàkiri Nàìjíríà ṣe ti parí ètò ìdìbò abẹ́nú láti yan olùdíje sípò Ààrẹ tí yóò díje níbi ètò ìdìbò gbogbogboò ọdún 2023, ìgbésẹ̀ tó kan ni yíyan igbákejì wọn.

Àjọ tó ń mójútó ètò ìdìbò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, INEC fún gbogbo àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú di ọjọ́ Kẹtàdánlógún, oṣù Kẹfà, ọdún 2022 láti fi fi orúkọ gbogbo àwọn olùdíje àti igbákejì wọn ṣọwọ́ sí àjọ náà.

Níbi ètò ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democraric Party, PDP tó wáyé lọ́jọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Karùn-ún ni Atiku Abubakar ti jawé olúborí níbi tó ti fẹ̀yìn Wike àti àwọn mìíràn janlẹ̀.

Bola Ahmed Tinubu náà fakọyọ níbi ètò ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress nígbà tó díje pẹ̀lú àwọn méjìlá mìíràn tó fí mọ́ igbákejì Ààrẹ Yemi Osinbajo, Rotimi Amaechi àti Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà Sẹ́nétọ̀ Ahmed Lawan.

Ní báyìí gbogbo àwọn olùdíje wọ̀nyí ni wọ́n ti ń foríkorí fikùnlukùn láti yan ẹni tí yóò ṣe igbákejì wọn.

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ti gbe ìgbìmọ̀ kan kalẹ̀ èyí àwọn gómìnà, ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́, àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ àti àwọn gómínà tẹ́lẹ̀ rí lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ náà kún ibẹ̀ láti fẹnukò láti lórí ta ni yóò jẹ́ igbákejì Atiku Abubakar.

Ìgbìmọ̀ yìí ló ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti ọjọ́bọ̀ gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ PDP, Debo Ologunagba ṣe sọ fún àwọn akọ̀ròyìn àti pé ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ ni àwọn yóò fi orúkọ ẹni náà léde.

Àwọn wo ni PDP le yàn fún ipò igbákejì Atiku

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kò sọ síta wí pé ẹni báyìí ni àwọn ń gbèrò láti yan gẹ́gẹ́ bí igbákejì fún Atiku, àwọn méjì kan ni ẹnu ń kùn pé ó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé ẹnìkan nínú wọn ni ipò náà yóò jámọ́ lọ́wọ́.

Àwọn méjéèjì náà ni gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike àti akẹgbẹ́ rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Delta, Ifeanyi Okowa.

Nyesom Wike

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Wike

Ìròyìn ní gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike ti ń kàn sí àwọn gómìnà ẹgbẹ́ rẹ̀ láti bojú àánú wo òun kí wọ́n fa òun kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò ṣe igbákejì Atiku níbi ètò ìdìbò gbogbogboò.

Wike tó gba ipò kejì níbi ètò ìdìbò abẹ́nú PDP ni wọ́n ní ó wà ní Abuja báyìí tó sì ń kàn sí àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ wọn láti fún ni ipò náà.

Àwọn ènìyàn ń wòye pé Wike kò jayopà tó bá ń bere fún ipò náà nítorí ipa tó ti kó fún ẹgbẹ́ náà àti èèkàn ní ẹkùn gúúsù tó le mú kí ẹgbẹ́ náà ri ìbò tó pọ̀ lásìkò ìbò.

Ifeanyi Okowa

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Okowa

Agbẹnusọ gómìnà ìpínlẹ̀ Delta, Olisa Ifeajika fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé gómìnà Ifeanyi Okowa wà lára àwọn tí ẹgbẹ́ náà ń gbèrò láti lò gẹ́gẹ́ bí igbákejì Ààrẹ lọ́dún 2023.

Ifeajika ni ọ̀gá òun tó gbangba sùn lọ́yẹ́ àti pé òun náà ti ń bá àwọn gómìnà nínú ẹgbẹ́ wọn sọ̀rọ̀ láti fàá kalẹ̀ láti ṣe amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ fún Atiku.

Ó ní òun gbàgbọ́ pé bí wọ́n bá gbe ètò ìdìbò kalẹ̀ láàárín àwọn gómìnà, òun mọ́ pé ọ̀gá òun ni wọ́n yóò dìbò fùn-ún.

Gbogbo àwọn olóyè ẹgbẹ́ PDP tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní dandan ni pé ipò igbákejì Ààrẹ gbọ́dọ̀ wá láti ẹkùn gúúsù Nàìjíríà àti pé ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ní gbòǹgbò, tí àwọn ènìyàn yóò dìbò yàn.

Yemi Osinbajo kí Bola Tinubu kú oríire

Aworan won fi owo bo owo

Oríṣun àwòrán, Google

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Igbakeji Aarẹ orilẹede Naijiria, Yemi Osinbajo ti ki Asiwaju Bola Ahmed ku oriire lẹyin to gbegba oroke gẹgẹ bi oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC.

Ninu atẹjade ti Osinbajo fi lede lo ti ki ku oriire, to si gboriyin fun un pe o di opo oṣelu tiwantiwa mu.

‘Mo ki Asiwaju Bola Ahmed ku oriire pẹlu bi o ṣe laluyọ gẹgẹ bi ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ naa ninu idibo sipo aarẹ ni ọdun to n bọ.

Bakan naa lo ki Aarẹ Muhammadu Buhari ku oriire abajade ipade gbogboogbo ti ẹgbẹ oṣelu APC.

O ni fun ọpọlọpọ ọdun ni Tinubu fi jẹ opomulero ninu iṣejọba tiwantiwa, eleyii si mu da yatọ laarin gbogbo awọn oludije.

Igbakeji Aare, Yemi Osinbajo ni ọpọlọpọ ọgbọn ati imọ ti Tinubu ni yoo mu tayọ lọna ati jẹ adari lorilẹede Naijiria.

Osinbajo wa kesi gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ patapata lati gbaruku ti Tinubu ki wọn le de ebute ayọ ni idido to n bọ.

‘’Gẹgẹ bi ẹni to fẹran ilọsiwaju, a gbọdọ ṣe ara wa ni ọkan, ki ẹgbẹ le ni ilọsiwaju.’’

Ibo to le ni ẹgbẹrun kan ninu awọn oludibo ‘Delegates’ to le ni ẹgbẹrun meji ni Tinubu fi ṣe agba fun Osinbajo ati gbogbo awọn ti wọn jọ dije du ipo naa.