Àbọ̀ ìpàdé tá a ṣe pẹ̀lú Atiku rèé ní kété tí Tinubu wọ́lé bíi olùdíje APC - Tambuwal

Oríṣun àwòrán, @atiku
Alaga ẹgbẹ awọn gomina latinu ẹgbẹ oselu PDP lorilẹede yii, tii tun se gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Tambuwal ti sisọ loju ohun ti wn jiroro nibi ipade to waye lana ọjọbọ.
Ni kete ti wọn kede pe Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lo bori ibo lati yan ọmọ oye ti yoo soju ẹgbẹ oselu APC ninu ibo aarẹ to n bọ, ni igun alatako, PDP bẹrẹ ipade naa.
Ipade naa si ni oludije fun ipo aarẹ to n gbe asia ẹgbẹ oselu PDP, Atiku Abubakar se agbatẹru rẹ, eyi to pe awọn gomina to wa lati ẹgbẹ oselu naa si.
Alatilẹkunmọrise si ni ipade naa eyi ti wọn ko gba awọn akọroyin lati bawọn peju si.
Amọ nigba to n sisọ loju ohun ti wọn gbe kọrọ yara sọ, Tambuwal ni bi ẹgbẹ oselu awọn yoo se bori ibo aarẹ lọdun 2023 ni koko ohun ti ipade naa da le lori.
“A sọrọ nipa bi irẹpọ ati ifọwọsowọpọ yoo se jọba ninu ẹgbẹ wa, eyi ti yoo mu ki eto ipolongo ibo ta ba se yọri si rere, ta si bori idibo gbogbo, wa lara awọn ohun ta jiroro le lori.
Ipade naa dabi ipade ifikunlukun ni lori ọna ti ẹgbẹ wa yoo gba tẹ siwaju .
Ta ni yoo jẹ igbakeji oludije fun ipo aarẹ ni PDP?
Nigba ti awọn akọroyin bi gomina ipinlẹ Sokoto naa leere pe ta ni ẹgbẹ oselu PDP n gbero lati yan gẹgẹ bi igbakeji fun oludije fun ipo aarẹ, Atiku Abubakar.
Tambuwal salaye pe Atiku si n finuwenu lọwọ lori ẹni ti yoo jẹ igbakeji fun to si wa lara awọn ohun to n fẹ ki awọn gomina pDP gba oun nimọran le lori.
Lara awọn eekan ninu ẹgbẹ oselu PDP to peju sibi ipade naa ni alaga ẹgbẹ, Iyorchia Ayu, Gomina Nyesom Wike, Udom Emmanuel ati Samuel Ortom.
Awọn yoku ni Ifeanyi Okowa, Bala Muhammed ati Seyi Makinde.

Àjọ tó ń mójútó ètò àyíká ní ìpínlẹ̀ Eko tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí task force àti àwọn ọlọ́kadà fìjà pẹ́ẹ́ta ní ọjọ́ Keje, oṣù Kẹfà, ọdún 2022 ní agbègbè Ida-Araba, ìjọba ìbílẹ̀ Surulere.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀wá lọ́wọ́ ṣe sọ, ní nǹkan bí aago mẹ́wàá ni àwọn task force ya wọ àdúgbò náà láti fi òfin de àwọn ọlọ́kadà gẹ́gẹ́ bí òfin tí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ṣe.
Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà di rògbòdìyàn nígbà tí àwọn ọlọ́kadà náà fárígá pé àwọn kò ní gbà kí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba náà gba àwọn ọ̀kadà wọn.
Lára àwọn fọ́nrán tó gba orí ayélujára Twitter ni èyí tó ṣàfihàn bí àwọn ọlọ́kadà náà ṣe dá wàhálà sílẹ̀, tí wọ́n sì dáná sí ojú títì.
Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ènìyàn kan fi sórí ayélujára pé àwọn kò rí ọkọ̀ nítorí rògbòdìyàn tí wọ́n ń fà ni agbègbè náà.
Lára àwọn olùgbé agbègbè náà tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ó ya àwọn lẹ́nu pé àwọn task force le máa mú àwọn ọlọ́kadà níbẹ̀ nítorí ìjọba ìbílẹ̀ Mushin ni ibẹ̀, kò sì sí lára àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ti fòfin de àwọn ọlọ́kadà.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko Benjamin Hundeyin ní kò sí ẹnikẹ́ni tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.
Hundeyin ní kò sí ilé kankan tí wọ́n jó nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti wí pé àwọn task force tó lọ síbẹ̀ múra lọ́wọ́ dada.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, agbẹnusọ àjọ task force, Gbadeyan Abdulraheem ní ọ̀kadà ọgọ́sàn-án ni àwọn mú ní àná.
Abdulraheem ni àwọn mọ̀ pé oju bọ̀rọ̀ kò ṣe gbọmọ lọ́wọ́ èkùrọ́ nítorí náà ni àwọn ṣe múrà dání dada nítorí àwọn ti mọ pé àwọn ọlọ́kadà náà kò ní fara balẹ̀ fún àwọn.
Ó ní ohun gbogbo ti padà bọ̀ sípò ní agbègbè náà báyìí.















