Ṣé lóòtọ́ọ́ ní Seyi Makinde parí ìjà láàrin NURTW àti PMS?

Awọn to n pari aawọ

Oríṣun àwòrán, Oyo state Park Management

Gomina ipinlẹ Oyo Seyi Makinde ti dasi wahala ohun aigbọraẹniye to n waye laarin awọn ẹgbẹ awakọ NURTW ati ajọ to n seto lilọ bibọ lawọn ibudo iwọkọ Park Management System ni ipinlẹ Oyo.

Makinde petu saawọ laarin wọn lasiko ipade alaafia kan to waye nibi ti awọn awakọ ọmọ ẹgbẹ NURTW kan ti wọn ko faaye gba ninu ẹgbẹ fi tinufẹdọ darapọ mọ PMS.

O sọ fawọn ikọ mejeeji pe ki wọn yago fun ikọlu tabi itajẹsilẹ kankan to le ṣakoba fun alaafia ipinlẹ Oyo.

Makinde ṣalaye pe ijọba oun ṣe agbekalẹ igbimọ to n mojuto ibudo iwọkọ ki awọn baa le ri gba gbogbo tọrọ kọbọ to yẹ ko wọle sapo ijọba jọ ni.

O ni awọn owo wọnyi yoo jẹ anfaani faraalu ati ipinlẹ naa.

''Mo fẹ fi ẹmi imoore mi han si gbogbo ẹni to wa sibi ipade yi loni.Ki a so ootọ fun ara wa, a ko nilo itajẹsilẹ ninu oṣelu wa inu mi si dun si pe gbogbo yin n farabalẹ lati gbọ mi''

''Ẹ jẹ ki n tun sọ fun yin. Ko si erongba oloṣelu kan to ṣe pataki debi pe ki a wa maa ta ẹjẹ silẹ.Ko to nkan taa n tori rẹ pa ara wa.Ni ọdun mẹta ti mo ti de ori alefa, mi o sun ile ijọba ni ọjọ kan ṣoṣo nitori mo lero pe mo ṣe le sun si ile mi to wa ni tosi.

Makind ni yatọ si nkan to n ṣẹlẹ tẹlẹ to ṣe pe awọn ẹgbẹ awakọ to wa ni Abuja nikan lo n jẹ mudunmudun to wa nidi iṣẹ tawọn ti Ibadan n ṣe, nisinyi, awọn awakọ labẹ ilana ati eto ti ijọba gbe kalẹ yoo ri anfaani jẹ ninu oogun wọn.

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde

Ni ipinlẹ Oyo, ọrọ awọn ẹgbẹ ati iṣakoso ọrọ iṣẹ awakọ ero jẹ eleyi to maa n da awuyewuye silẹ lọpọ igba.

Idi si ni pe orisi igun awọn ẹgbẹ yi lo n ba ara wọn fa wahala ni paapa lori ọrọ ẹni to lẹtọ lati maa ṣe akoso awọn awakọ.

Lẹnu igba ti Gomina Makinde de ori alefa yi, o ti da si aimọye aawọ laarin awọn awakọ koda o debi pe o paṣẹ pe ki awọn ẹgbẹ NURTW kogba wọle lawọn ibudo iwọkọ ni Oyo.

“Ko si idoola ija kankan laarin awa NURTW ati PMS l‘Oyo”

Wayi o, awọn ọmọ ẹgbẹ ọmọ ọlkọ ero nipinlẹ Oyo, NURTW ti sẹ lori iroyin kan to gbalẹ pe awọn ti pari ija pẹlu ẹgbẹ alakoso gareeji ọkọ nipinlẹ Oyo.

Aarẹ ẹgbẹ ọlọkọ ero, Tajudeen Baruwa lo sisọ loju ọrọ yii plu afikun pe ẹgbẹ NURTW ko ni ajọsepọ kankan plu PMS, tii se ikọ alakoso gareeji ọkọ nipinlẹ Oyo.

O wa tnumọ pe Alhaji Abideen Olajide ti ọpọ eeyan mọ si Ejiogbe si ni alaga ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Oyo.