NURTW Oyo: Ìfikùnlukùn yóò wàyé pẹ̀lú Gómìnà Makinde láìpẹ́

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde

Àkọlé àwòrán, NURTW rọ Gómìnà Makinde láti jèbùrẹ́ lórí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ awakọ̀ èrò ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Aarẹ ẹgbẹ awakọ ero lorilẹ-ede Naijiria, Alhaji Najeem Yasin ti ke si gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde lati fi oju miran wo igbesẹ to gbe lati gbẹsẹle ẹgbẹ naa nipinlẹ Ọyọ.

Alhaji Yasin ni awọn yoo ṣepade pẹlu gomina Makinde laipẹ lati wa ojuutu si ọrọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni ọjọ Ẹti to kọja ni Makinde paṣẹ pe eegun ẹgbẹ awakọ ero, NURTW ko gbọdọ ṣẹyọ fun igba diẹ nipinlẹ Ọyọ lẹyin ti wọn fi ẹsun kan awọn ọmọ ẹgbẹ naa pe wọn n da omi alaafia ru lọna ati gba ibudokọ lọwọ ara wọn.

Àkọlé fídíò, Pẹ̀lú gbogbo bùkátà, Bàbá 80 gboyè Masters

Ọrọ yii jade ninu ọrọ ti aarẹ ẹgbẹ awakọ ero NURTW, Najeem Yasin fi ranṣẹ lati orilẹ-ede Saudi Arabia nibi ti o ti lọ ṣe Umrah fun ọdun Ramadan.

Amọṣa ni ọjọ Aje ni ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ fi oju awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ ero ipinlẹ Ọyọ mọkandinlọgbọn han fawọn oniroyin lẹyin ti wọn ni ọwọ tẹ wọn ni ibi ti wọn ti n gbero ati da wahala silẹ lawọn ibudokọ kan nipinlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Ajayi: ṣé ìwọ mọ irúfẹ́ ọmọ tí Yorùbá ń pè bẹ́ẹ̀?

Kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Shina Olukolu ni marundinlogun ninu awọn afurasi naa ni ọwọ ba lasiko ti wọn fẹ da omi alaafia ilu ru lagbegbe Idi Arẹrẹ, Bẹẹrẹ, Orita Aperin, Iwo road ati ibudokọ ni Eruwa, Ilu Ibadan.

Àkọlé fídíò, Ondo: Dejí sun ọmọ méje àtagbalagba meji mọ́lé nítorí pé ó ń bínú