Ilé aṣòfin Ekiti ní kí àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ dá N3.6bn padà

Oríṣun àwòrán, Ekiti@official
Ile Igbimọ Aṣofin Ekiti ti ni ki awọn alaga ijọba ibilẹ ti wọn ni ko lọ rọkun nile ni ọdun 2018 da biliọnu mẹta aabọ o le diẹ ti wọn fẹsun kan wọn pe wọn na ni inakuna pada.
Àwọn aṣofin mẹrindinlogun naa ni wọn da duro ni oṣu kẹfa ọdun 2018 nigba iṣejọba gomina ana, Ayo Fayose.
Awọn aṣofin gbe igbesẹ naa nibi ijoko aṣekagba saa awọn aṣofin to wa nibẹ lọwọ.
Ṣugbọn awọn aṣofin ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP to wa ni ijoko naa bẹnu atẹ lu igbesẹ yii, bo tilẹ jẹ pe abẹnugan ile , Adeniran Agbada fi ontẹ lu ipinnu ile naa, bo ṣe sọ wipe awọn alaga ọhun ṣe aṣeju ni owo nina wọn.
Alaga naa lo ijọba ibilẹ rẹ Ise/Ọrun gẹgẹ bi apẹẹrẹ. O ni wọn ya ọọdurun miliọnu naira sọtọ lati kọ olu ileeṣẹ ijọba ibilẹ ṣugbọn wọn ko owo naa jẹ.









