Ekiti Assembly: Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin júwe ilé fáwọn alága ìjọba ìbílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Ekiti@official
Ilé ìgbìmọ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ekiti tí fún àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rẹ̀rìndílógún, awọn kansẹlọ mẹ́tàdínlọ́gọ́sàn àtí àwọn èèkàn olóṣèlú níjọba ìbílẹ̀ ní ìwé ló rókún níle aláìní gbèdéke nítori ẹ̀sùn níná owó ìjọba ìbílẹ̀ mákumaku.
Lásìkò tó ń ba àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lóri ìfẹ̀nukò ilé, alága ìgbìmọ tẹ̀ẹ́kótó lóri igbóhùn sáfẹ́fẹ́ àti adarí oko-òwò ijọba Họnọrabu Gbenga Aribisọgan, sàlàyé pé ìgbésẹ̀ ọ̀hún wáyé nílànà ofín ọdún 1999.
Ó ní lẹ́yìn tí ìgbìmọ tẹẹ́kótó lóri iwé owó tí wọn gbé iṣẹ́ fún jábọ lóri abájáde ìwádìí wọn lóri ìṣúnà àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ní arídájú ti jẹyọ pé wọn ń ṣe owó ìlú mọkumọku tí ìgbìmọ ò sí lé mójúkúrò
''A ṣiṣẹ́ lórí àwọ ìwé wọn à sì rí àrídájú pé àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ ṣe ǹkan tó wù wọn láti ṣe i'sẹ́ àkànṣe tó ju ǹkan tó yẹ kí wọn ṣe lọ, èyí ló fún wọn ní ànfàní láti hùwà jẹgúdújẹra''
Aribisogan bẹnu àtẹ lu àhesọ ọ̀rọ̀ pé àwọn alága fún ilé ìgbìmọ aṣofin ní mílíọ̀nù mẹ́jọ láti dáwọ́ ìdádúró náá dúró, ó fi kún-un pé àwọn ọmọ ìgbìmọ tẹ̀ẹ́kótó nìkan ló sàbẹ̀wó sí gbogbo ètò tó wáye ní àwọn ìjọba.








