Kaduna: Àwọn agbébọn pa ènìyàn 14 níbi ìgbéyàwó ní Ungwan Pa-Gwandara

Ọmọogun Naijria

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ìròyìn ní wí pé àwọn mẹ́rìnlá ló kú lẹ́yìn tí àwọn agbébọn sígun bo agbéégbé Ungwan Pa-Gwandara tí wọ́n tí ń se ìgbéyàwó.

Ijọba Ipinlẹ Kaduna ti ran awọn ọmọogun lọ si agbègbè Ungwan Pa-Gwandara ni ijọba ibilẹ Jema'a, lẹyin ti awọn agbebọn sigun bo agbegbe na.

Ile isẹ Iroyin News Agency of Nigeria fi lede wi pe alẹ ọjọ Isinmi ni awọn agbebọn naa wa ṣe ọsẹ́, ti ọpọlọpọ si ku, ti awọn miran si farapa.

Arakunrin Samuel Aruwan to jẹ oluranlọwọ agba fun gomina ipinlẹ Kaduna lori eto iroyin lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade ni ilu Kaduna.

Àkọlé fídíò, 'Kaduna ni àjọ NYSC pín mi sí sùgbọ́n...'

Aruwan sọ wi pe awọn ọmọogun Naijiria naa yoo da abo bo awọn to wa ni agbeegbe na, ki alaafia o le pada si ilu.

Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai to bu ẹnu ẹtẹ lu bi awọn agbebọn se ṣe ikọlu naa, sọ pe gbogbo awọn to lọwọ ninu iṣẹ ibi naa ni ọwọ ofin yoo te laipe.

Àkọlé fídíò, Yorùbá gbà pé òrìṣà bí ìyá kò sí!

Gomina ipinlẹ Kaduna naa wa rọ awọn ara ilu lati se jẹjẹ lasiko yii, ki wọn si ta ijọba lolobo, ti wọn ba mọ awọn to sisẹ ibi naa.

Àkọlé fídíò, 'Tayọ̀tayọ̀ ni mó fẹ́ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú INEC ki ìdìbò 2019 lé dára'