Buhari at 76: Àwọn àwòrán tó làmì-laaka nípa Buhari

Ọdun 1942 ni Hando Adamu ati Hajia Zulhatu Musa bi Aarẹ Muhammadu Buhari sinu idile Baalẹ Fulani, l'abule Dumurkol nitosi Daura.

Buhari, Gustaf, ati Zaki

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọdun 1977 ni Muhammadu Buhari ya aworan yii pẹlu Ọba Sweden, Carl Gustaf ati Sheikh Ahmed Zaki nilu Stockholm, Sweden, lasiko to lọ fun ipade ajumọṣe fun awọn orilẹ-ede to n pese epo rọbi
Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Muhammadu Buhari lasiko to fi jẹ aarẹ ologun ni Naijiria lọdun 1983 si 1985
Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Buhari lasiko to n gba iṣakoso lẹyin to ṣaṣeyọri ninu iditẹ gbajọba lọwọ Shehu Shagari lọdun 1983
Buhari ati idile rẹ

Oríṣun àwòrán, @other

Àkọlé àwòrán, Buhari pẹlu iyawo rẹ to ti d'oloogbe, Safinatu, ati awọn ọmọ marun un to bi fun un. Ọdun 1971 ni Buhari gbe e niyawo, ṣugbọn o kọ ọ silẹ l'ọdun 1988.
Buhari

Oríṣun àwòrán, other

Àkọlé àwòrán, Ọdun 1942 ni wọn bi Aarẹ Muhammadu Buhari sinu idile Baalẹ Fulani l'abule Dumurkol nitosi Daura, Hando Adamu ati Hajia Zulhatu Musa lorukọ obi rẹ
Buhari

Oríṣun àwòrán, other

Àkọlé àwòrán, Buhari ni ilu Owerri lasiko oogun Biafra to waye ni Naijiria laarin ọdun 1967 si 1970
Buhari, Aisha Aliyu Gebbi ati Nicole Benson

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhari

Àkọlé àwòrán, Ẹ jẹ ki awọn ọmọde ki o wa s'ọdọ mi... Buhari yẹ awọn ọmọde yii si, o sọ pe ọkan lara wọn, Nicole Benson fi ẹgbẹrun marun un ati ẹẹdẹgbẹrin Naira kun owo ipolongo ibo oun l'ọdun 2015
Buhari

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhari

Àkọlé àwòrán, Agbẹ l'ọba, aarẹ Buhari ko fi iṣẹ agbẹ silẹ nitori pe o di aarẹ. Baba re to n gbin ẹfọ ati eso ninu oko rẹ ni Daura, ṣaaju ko to lọ France fun ipade apero 'One Planet' l'ọdun 2017
Buhari

Oríṣun àwòrán, @buhari

Àkọlé àwòrán, Ipade Aare Buhari pelu awon loba-loba nilu Jos
Buhari

Oríṣun àwòrán, @buhari

Àkọlé àwòrán, Buhari nigba ti o n ṣabewo sawọn eniyan ipinlẹ Benue leyin ọpọlọpọ ikọlu