Access Bank: A kò dá ẹnikẹ́ni dúró lẹ́nu iṣẹ́, Coronavirus ló jẹ́ ká ti àwọn ẹ̀ka wa

Access bank

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Wọn ni Covid-19 lo da iṣẹ duro lawọn ẹka kan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ile ifowopamọ Access Bank ti sọ pe irọ pata ni ọrọ kan to n tan kalẹ loju opo ikansiraẹni pe ile ifowopamọ naa n da awọn oṣiṣẹ rẹ duro.

Ninu atẹjade kan ti ile ifowopamọ naa fi lede loju opo rẹ ti awọn alaṣẹ rẹ si fọwọ si lo ti sọ ọrọ ọhun.

O ni "A fẹ sọ pe ko si ootọ ninu ọrọ ti awọn eeyan n sọ pe a fẹ da ida marundinlọgọrin awọn oṣiṣẹ wa duro."

Acess Bank

Oríṣun àwòrán, Access Bank

"Ko si ile ifowopamọ kankan to le ti ilẹkun ẹka rẹ lai kọkọ gba aṣẹ lọwọ banki apapọ, CBN, ohun ti a ṣẹ ni pe a da iṣẹ duro lawọn ẹka wa kan ni, a ko da ẹnikẹni duro lẹnu iṣẹ."

Ile ifowopamọ naa ṣalaye pe wọn da iṣẹ duro lawọn ẹka kan nitori ajakalẹ arun Covid-19 to n ba gbogbo aye finra.

O pari ọrọ rẹ pe ile ifowopamọ ọhun yoo bẹrẹ si ni ṣi awọn ẹka rẹ pada, ṣugbọn ko ni ṣi gbogbo rẹ tan nigba kan naa nitori awọn ẹka mii yoo wa ni titi fun awọn oṣu diẹ si.

Ṣaaju ni iroyin kan ti tan kalẹ loju opo Twitter ati Facebook pe ile ifowopamọnaa ti bẹrẹ si n da awọn oṣiṣẹ rẹ duro lẹyin to fun ijọba apapọ ni biliọnu kan naira lati fi gbogun ti ajakalẹ arun Coronavirus.

Access Bank ti gba ilé ìfowópamọ́sí Diamond Bank

ACCESS ATI DIAMOND BANK

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Àkọlé àwòrán, Ẹ̀rọ̀ àwọn ọmọ Naijiria se ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí bí ilé ìfowópamọ́sí Diamond se darapọ̀ mọ́ ile iilé ìfowópamọ́sí Access.

Ibeere to n suyọ lẹnu awọn ọmọ Naijiria ni wi pe kini yoo sẹlẹ si isẹ awọn osisẹ Diamond Bank, lẹyin ti ile ifowopamọsi naa kede wi pe awọn yoo darapọ mọ ile ifowopamọsi Access.

Ni Ọjọ Aje ni awọn adari ile isẹ Diamond Bank naa kede idarapọ mọ ile isẹ Access Bank.

Ninu ọrọ ti wọn fi lede, ki o to di Osu Kẹfa, ọdun 2019 ni awọn yoo pari gbogbo eto lati se idarapọ mọ Access Bank.

Àkọlé fídíò, Yorùbá gbà pé òrìṣà bí ìyá kò sí!

Kini yoo sẹlẹ si awọn osisẹ Diamond Bank?

Awọn ọmọ Naijiria lori ẹrọ ikansiraeni Diamond Bank lori opo Twitter ti n fesi bi Diamond se darapọ mọ Access Bank.

Ọpọ ninu wọn n bere wi pe njẹ awọn osisẹ Banki naa ko ni dii alainisẹ lẹyin ti wọn ba ti darapọ mọ Access Bank.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Bakan naa ni awọn eniyan kan n bere wi pe ẹni to ba n lọ banki mejeeji, kini yoo sẹlẹ si wọn?

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Awọn miran ti lẹ n se awada wipe se Access Bank yoo tun gba oju opo ikansiraẹni Twitter ti Diamond Bank.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Àkọlé fídíò, Gbogbo ènìyàn ló wọ agbádá ikú, ẹni tó kàn lẹnìkan kò mọ̀

Igba akọkọ kọ ni yii ti ile isẹ ifowopamọsi Access yoo ma gba banki miran mọra. Ọdun 2011 si 2012 ni wọn gba Intercontinental Bank Plc, ti wọn si fi ọwọ osi juwe ile fun ọpọlọpọ awọn osisẹ banki Intercontinental naa ki wọn to darapọ mọ ile ifowopamọsi Access Bank.

Àkọlé fídíò, Alápinni: Kò sí ẹni to fẹ́ kọ́kọ́ kọ́ iṣẹ́ òṣèré bíi ti àtẹ̀yìnwá
Àkọlé fídíò, CJ Gold: ẹ̀rù kọ́ka ba ìyá mi nígbà ti mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìjà jíjà