Coroavirus drugs: Àwọn aláṣẹ̀ America fọ́wọ́ sí lílo òògùn Ebola fí tọ̀jú Coronavirus

Remdesivir

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ to n mojuto ipese ounjẹ ati òògùn nilẹ America, Food and Drug Administration (FDA), ti fọwọ si lilo òògùn ti wọn fi n tọju aisan Ebola fun itọju coronavirus.

Bi wọn ṣe fi ọwọ si remdesivir tumọ si pe wọn le maa lo oogun naa fun itọju awọn ti coronavirus ti de mọlẹ sileewosan.

Laipẹ yii ti wọn dan oogun naa wo fun Covid-19, o ṣe iranlọwọ lati mu ki ara awọn ti aarun naa ṣe ni ijamba pupọ ko tete ya laarin ọjọ mọkanla dipo ọjọ mẹẹdogun to maa n gba wọn lọ tẹlẹ.

Ileeṣẹ to ṣe oogun naa, Gilead pharmaceutical company sọ pe oun yoo fun ijọba ni miliọnu kan aabọ igo oogun naa lati lo.

Ṣugbọn ṣa, awọn onimọ ti sọ pe awọn eniyan ko gbọdọ ri oogun remdesivir gẹgẹ bi "ajẹ bi idan" fun coronavirus.

Amin iyasọtọ kan

Ija ti dopin, ogun si ti tan fun aarẹ orileede Amẹrika, Donald Trump, nitori o ti moribọ lọwọ iyọni nipo.

Nibi igbẹjọ aarẹ orileede Amẹrika naa, nile aṣofin agba ti ni pe ko ma ijọba rẹ lọ nitori pe ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan.

Ile aṣofin naa, ti o ṣepe awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ Republican lo pọju nibẹ, fi ibo mejilelaadọta si mejidinlaadọta ju ti ẹgbẹ Democrat lọ, ti wọn si ni ko jẹbi ẹsun pe o lo ipo ni ilokulọ.

Lori ẹsun pe o ṣe idiwọ fun ile aṣofin, ibo mẹtalelaadọta si mẹtadinlaadọta ni ẹgbẹ rẹ fi dibo gbe lẹyin rẹ.

Ninu idibo naa to waye lọjọru, ile kọ lati yọ aarẹ Trump to jẹ aarẹ karundinlaadọta orileede Amẹrika.

Bayi yoo jẹ aarẹ akọkọ ti wọn yọ ni ile aṣoju-sofin, ti yoo kopa ninu idibo to n bọ lọna loṣu Kọkanla ọdun yii.

Ki ni aarẹ Trump sọ lẹyin ikede yi?

Ọgbẹni Trump, ti ko figba kan maa sọ pe oun ko jẹbi ẹsun naa, yoo kopa ninu idibo fun saa ọlọdun mẹrin miran ni oṣu Kọkanla ọdun 2020.

Igbimọ ipolongo idibo rẹ sọ ninu atẹjade kan pe, ''Aarẹ Trump ti wẹ yan kanin-kanin bayi, ohun to si ku ni ka gbajumọ eto ṣiṣe iṣẹ sin awọn eeyan ilẹ Amẹrika''

Àkọlé fídíò, Trump impeachment: Trump kò fìdí janlẹ̀ tán, àmọ́ níbo ni yóò jásì?

''Awọn alainikanṣe ẹgbẹ Democrat mọ pe awọn ko le bori rẹ, nitori naa ni wọn fi n dete iyọni-nipo''

Atẹjade wọn tẹsiwaju pe, ọna ati ṣe ipolongo ni 'iṣẹlẹ buruku' yii ati 'iranu' ti wọn ṣe jẹ.

Aarẹ Trump, ti ọrọ yii kan sọ loju opo Twitter rẹ pe oun yoo fesi si iṣẹlẹ yii lọjọbọ.