Coronavirus vaccine: Kí ló wà nínú àbá àkóso ajakalẹ àrùn tó fi ní àtakò?

Ile igbimọ aṣofin

Oríṣun àwòrán, others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Ilé asofin táwọn aṣojú nilẹ wa ká àbá òfin tí yóò máa ṣe àkóso ajakalẹ-arun fún ìgbà kejì ni ọṣẹ tó kọjá àmọ́ igbesẹ náà tí ń mú awuyewuye lọwọ láàrin àwọn ọmọ Nàìjíríà.

Olórí ilé asoju-sofin fúnra rẹ, Femi Gbajabiamila sì lo gbé àbá òfin náà kalẹ, èyí to ni yóò mú kó seese fún ìjọba àpapọ̀ láti dènà ajakalẹ-arun.

Bákan náà, òfin àkóso ajakalẹ-arun náà ni yóò rọ́pò òfin iyasọtọ lásìkò ajakalẹ-arun, tí wọn pé ní National Quarantine Act.

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, others

Àtakò tí aba náà ni lórí ayélujára pọ débi pé agbarijọpọ ẹgbẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi, CAN gan tí kesi ilé asofin pé ko jawọ nínú sísọ di òfin, tí sẹnatọ àná kan sì ti gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sile ẹjọ́.

Ọ̀pọ̀ awuyewuye tó rọ mọ aba akoso ajakalẹ-arun yìí ló mú kí BBC Yoruba máa béèrè pé, kí ló wà nínú àbá náà, tó fi ní àtakò tó èyí, tá sì ṣàgbéyẹ̀wò abá náà láti mú àwọn kókó tó wà nínú rẹ jáde.

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, others

Abala keje àti í kejìlá àbá náà ro olùdarí àgbà fun ibùdó tó ń ṣe àkóso ajakalẹ-arun àrùn ni Naijiria, NCDC lágbára, láti gbé àwọn igbesẹ tó ṣe kókó, tó wá nisalẹ yìí, lásìkò tí ajakalẹ-arun bá bẹ silẹ.

Kókó tó wà nínú àbá àkóso ajakalẹ-arun:

  • Ṣíṣe àyẹ̀wò ikú tó pa òkú kan
  • Gbígba ọ̀rọ̀ tó ṣe kókó lẹ́nu mọlẹbí aláìsàn
  • Fífi tipa gba òkú ẹni tó bá kú láti ipaṣẹ ajakalẹ-arun
  • Àgbàra láti kéde ilé ẹnikẹ́ni bíi ibùdó iyasọtọ
  • Àgbàra láti gbé ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ kó kúrò ní irú agbegbe iyasọtọ náà, fún ọlọ́pàá
  • Abala kerinlelogun aba náà tún fún ọlọ́pàá lágbára láti gbé ẹnikẹ́ni tó bá ní arun si ahamọ
  • Abala ogún òfin náà fún NCDC ni agbára láti dawọ ipejọpọ èrò dúró àbí ètò kan dúró lásìkò ajakalẹ-arun
  • Abala kokanlelaadorin aba yìí fún ọga àgbà NCDC àtàwọn ọlọ́pàá abẹ rẹ lágbára, láti ni agbára gẹ́gẹ́ bíi Ààrẹ Nàìjíríà lásìkò ajakalẹ-arun, lai si ẹni ti yoo yẹ lọwọ wo, ohunkóhun tó bá ṣe lásìkò naa
  • Abala karunlelaadota ro NCDC lágbára láti béèrè ìwé kiwe tàbí ohunkóhun pẹlu ipá lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni tàbí fi ipá wọnú ilé kan lai gba àṣẹ lọ́wọ́ ọlọ́pàá
  • Ẹgbẹrun lọ́nà ọgọ́rùn-ún náírà ni owó ìtanràn ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ lábẹ́ òfin naa tàbí kó lọ sí ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà
  • Tí onitọun bá tún tún ẹsẹ náà dá, yóò san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ìgbà náírà tàbí kó fi ẹ̀wọ̀n ọdún kan jura

Èrò ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tó tako aba náà sì ni pé, ó yí gbé agbára ńlá wọ ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ ọga àgbà fún àjọ NCDC, to di lee di apàṣẹ wàá, tàbí kó si agbára náà ló kọjá sísọ.

Àkọlé fídíò, Wo bí o ṣe leè ṣe ìjìnàsíraẹni ní ibiṣẹ́ lásìkò Coronavirus yìí

Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àbádòfin NCDC tó ń fa fà kí n fà lórí ìtàkùn àgbáyé

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, @dabiodunmfr

Lẹnu ọjọ diẹ sẹyin lawọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori abadofin to rọ mọ ajakalẹ arun ti ile igbimọ aṣojuṣofin dawọle.

Abadofin ọhun ti wọn pe ni "Control of Infectious Disease Act" ni agbẹnusọ ile naa, Femi Gbajabiamila fi lede lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹrin ọdun 2020, ṣugbọn ọrọ naa ti di fa ki n fa lori itakun agbaye.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe atọhunrinwa lati ilẹ Singapore ni abadofin naa, lawọn mii n sọ pe yoo fun ọga agba ajọ to n gbogun ti itankalẹ ajakalẹ arun ni Naijiria, NCDC, ni agbara to pọ ju ẹni ti wọn dibo yan lọ.

Ṣugbọn bawo ni ọrọ abadofin ọhun ṣe jẹ gan? Ẹ sunmọ bi!

Njẹ abadofin naa ti di ofin?

Benjamin Kalu, to ṣoju ile naa so fun BBC pe, irọ ni iroyin ti a wọn eeyan kan n gbe kiri pe, ile aṣofin ọhun yara sọ abadofin naa di ofin laarin ọjọ diẹ.

Kalu sọ pe "Iwe ofin naa yoo la oniruru ipele kọja gẹgẹ bi awọn ofin to ṣaaju rẹ ko to di ofin nilẹ yii."

O ni ile ọhun ko ti sọ abadofin kankan di ofin lasiko yii, nitori oriṣiriṣi ilana lo rọ mọ sisọ abadofin di ofin.

Àkọlé fídíò, Se lootọ ni pe eniyan le ko Coronavirus lara ẹni to ti kú?

Kalu ṣalaye pe "Abadofin yoo de ipele ti wọn yoo ti ka ni gbagede, ti awọn onimọ nipa ajakalẹ arun yoo si dasi."

"Lẹyin naa ni igbimọ miran yoo wo gbogbo kudiẹ kudiẹ to ba wa ninu rẹ, lẹyin naa ni yoo de ile aṣofin agba, ti awọn naa yoo si ṣe iṣẹ le lori."

"Fun idi eyi, ko si kanjukanju ninu ọrọ gbigbe ofin kalẹ"

Kalu sọ siwaju si pe ofin naa ṣe pataki lasiko yii nitori ofin ajakalẹ arun to wa nilẹ tẹlẹ ni ti iba jẹdọjẹdọ, iba ponju-pontọ, ati iba onigba meji, ati pe ofin ọhun ko ni fun ọga agba NCDC lagbara to pọ ju.

Ni ti ọga agba ajọ NCDC, Chikwe Ihekweazu, o ni oun mọ pe erongba rere ni awọn aṣofin ni, ti wọn ṣe n gbero lati gbe ofin ọhun kalẹ, ṣugbọn kii ṣẹ asiko lo yẹ ki wọn daba rẹ.

Gbigba abẹrẹ ajẹsara ko ni jẹ tipatipa

Ọpọ ahesọ ọrọ lo ti n lọ lori itakun agbaye pe ijọba yoo fi tipa tikuku mu awọn eeyan gba abẹrẹ ajẹsara Coronavirus, ṣugbọn agbẹnusọ awọn aṣofin ọhun ni ọrọ ko ri bẹ.

Àkọlé fídíò, Ṣe lilo Methtoletom lé koju aarun Corornavirus?

O sọ pe "Awọn to ba fẹ rinin ajo ilẹ okere nikan ni ofin to rọ mọ abẹrẹ ajẹsara kan, gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe ma n gba kaadi abẹrẹ ajẹsara fun iba ponju pontọ ti wọn ba fẹ lọ orilẹede miran.

Kalu sọ siwaju si pe "A ko ni fi ipa mu ẹnikẹni lati gba abẹrẹ ajẹsara, ṣugbọn ẹni to ba mọ pe oun ni arun naa yoo foju wina ofin to ba gbe wọ orilẹede yi."

Ṣe ẹda ofin orilẹede Singapore ni abadofin naa?

Ni ti pe boya ilẹ Singapore ni awọn aṣofin ti mu abadofin ọhun wa, ọgbẹni Kalu sọ pe irọ patapata ni.

O ni "Irọ nla ni pe ẹda ofin ile Singapore ni abadofin naa, nitori ofin o ṣeeṣe ki ofin orilẹede kan jọ ti omiran, papa ti wọn ba n dojukọ iṣoro kan tabi ni afojusun to ba baramu."

Àkọlé fídíò, Corornavirus: Ṣe lilo ìbọ̀wọ́ le dènà ààrùn Coronavirus

Erongba awọn ọmọ Naijiria si abadofin ọhun

Ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria atawọn ẹgbe ajafẹtọẹni lo ti n sọ ohun ti wọn ro nipa abadofin naa loju opo Twitter pẹlu #stopncdcbill.

Ẹwẹ, o kere tan, ẹgbẹrun meji eeyan lo ti lugbadi arun Coronavirus ni Naijiria nigba ti a n kọ iroyin yii lọwọ.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Isolation Center: Minisita feto ìlera ni ìjọba fẹ́ ṣe àyẹ̀wò fún èèyàn mílíọ̀nù méjì láàárín oṣù mẹ́ta tó ń bọ̀, tí wọn sì nílò ibùdó iyasọtọ sì

Ibusun ni ibudo itọju alaarun coronavirus kan

Oríṣun àwòrán, others

Minisita feto ìlera, Dókítà Osagie Ehanire tí rawọ ẹ̀bẹ̀ sáwọn ọmọ Nàìjíríà láti gbé ilegbe wọn kalẹ fún ibùdó iyasọtọ.Ehanire rawọ ẹbẹ yìí lásìkò ìpàdé pẹlu awọn akọroyin n'ilu Abuja.O ni àfojúsùn àjọ to ń rí sì àkóso àrùn ni Naijiria ni lati ṣe àyẹ̀wò fún èèyàn mílíọ̀nù méjì láàárín oṣù mẹ́ta tó ń bọ̀, tí wọn sì nílò ibùdó iyasọtọ si.Minisita feto ìlera ni "Mo ń rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti gbé ilegbee wọn kalẹ fún ibùdó iyasọtọ fún ìgbà díẹ̀.

Kii se pe àwọn ibùdó iyasọtọ wa ti kún àmọ́ a kàn fẹ́ máa palẹ mọ báyìí ka leè pèsè ohun èlò tó yẹ síbẹ̀."

Ìpínlẹ̀ Eko ń bá àwọn iléètura sọ̀rọ̀ fún ìpèsè ibùsùn fáwọn aláàrùn Coronavirus

Ìpínlẹ̀ Eko ń bá àwọn iléètura sọ̀rọ̀ lọ́nà àti kojú ìpèníjà ibùsùn láwọn ibùdó ìtọ́jú àwọn aláàrùn COVID-19

Ijọba ipinlẹ Eko ni awọn ti n ba awọn ileetura sọrọ l'Eko fun iranwọ lori iṣoro aisi ibusun to to lawọn ibudo itọju awsn alaarun coronavirus ni ipinlẹ Eko.

Ibusun ni ibudo itọju alaarun coronavirus kan

Oríṣun àwòrán, others

Ni Ọjọbọ ni oludari agba ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, Dokita Chikwe Ihekweazu pariwo faye gbọ pe ipenija to ga julọ ti eto kikoju ajakalẹ arun COVID-19 n koju ni aisi iye ibusun to to lawsn ibudo itọju awọn alaarun naa ni ipinlẹ Eko.

Amọṣa ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC news, kọmiṣọna feto iroyin ni ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Gbenga Ọmọtọṣọ ni ijsba ipinlẹ naa ti bẹrẹ igbesẹ lati beere fun iranwọ ati ajọṣepọ lọdọ awọn ileetura lati koju ipenija ọhun.

Ni asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, o din diẹ lẹgbẹrun kan eeyan ti ayẹwo ti fihan pe o laarun naa ni ipinlẹ Eko nikan

Coronavirus Cases in Africa: Sanwo-Olu kéde ìgbésẹ̀ fún pípadà sẹ́nu iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Eko

Gomina Babajide Sanwoolu

Oríṣun àwòrán, Babajide sanwo-olu

Ijọba ipinlẹ eko ti gbe ilana aa tẹẹle kalẹ fun bi wọn yoo ṣe bẹrẹ si ni ka eto kanile o gbele kuro nilẹ ni ṣiṣẹ n tẹle ni ipinlẹ Eko.

Amọṣa awọn eto wa ni ṣisẹ n tẹle ti yoo maa waye kaakiri ipinlẹ Eko ni ibamu pẹlu aṣẹ ti aarẹ Muhammadu pa ni ọjọ Aje lori awọn igbesẹ ọlọtọ ni toun ọtọ tawọn ipinlẹ lee maa gbe lawọn ipinlẹ kọọkan lati pinwọ ajakalẹ arun Coronavirus.

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ni nipele nipele ti aṣọ alubọsa n wa ni wọn yoo maa ṣe eto ati ilana ti wọn n gbe kalẹ naa.

Gomina Sanwo-Olu kede awọn igbesẹ naa eleyi ti yoo bẹrẹ ifidimulẹ lati ọjọ kẹrin oṣu karun ọdun 2020.

Lara awọn igbesẹ naa ni pe awọn ọlọkada ko gbọdọ siṣẹ kaakairi ipinlẹ Eko; ti awọn oni kẹkẹ marwa ko si gbọdọ gbe ju ero meji lọ.

Awọn eto ati ilana yooku niwọnyii:

  • Aṣẹ konile-o-gbele lati irslẹ si kutukutu owurọ ni ibamu pẹlu ohun ti aarẹ Muhammadu Buhari pa laṣẹ ninu ọrs rẹ.
  • Awọn oṣiṣẹ alakasọ igbega kini de ikejila yoo tẹsiwaju lati maa ṣe iṣẹ wọn lati ile ayafi ti ọga tabi adari ẹka ileeṣẹ ijọba ti wọn n ba ṣiṣẹ ba ni ki wọn wa ṣe ohunkohun nileeṣẹ ijọba.
  • Nigbati awọn to wa lakasọ kẹtala soke yoo joko jiroro lori ilana iṣẹ ti wọn yoo fi ṣeto bawọn oṣiṣẹ yooku yoo ṣe maa wa si ẹnu iṣẹ.

Lori eto igbokegbodo ọkọ ati karakata pẹlu iṣẹ gbogbo.

  • Ko si ọkọ bọọsi akero to gbọdọ gbe ero kun. Ida ọgọta ero nikan ni wọn yoo maa gbe sinu ọkọ wọn.
  • Ko gbọdọ si ọlọkada kankan to gbọdọ rinna yatọ si awọn to n ṣe iṣẹ alaaro(courier)
  • Gbogbo awọn ileeṣẹ to fẹ bẹrẹ iṣẹ pada lọjọ kẹrin gbọdọ yoo maa ṣiṣẹ laarin agogo mẹsan owurọ si mẹta ọsan. Aṣẹ yii kan awọn ileeṣẹ aladani gbogbo, ile itaja nlanla atawọn ọja gbogbo.
  • Gbogbo awọn awakọ ero ni wọn gbọdọ maa lo ibomu wọn, ti wọn si gbọdọ ma lo eroja ifọwọ Hand sanitizer. Gbogbo awọn ibudokọero lo si gbọdọ yẹra fun akunfaya ero.
  • Ko saye a n duro ninu ọkọ bọọsi akero ijọba BRT ati LBSL. Gbogbo awọn ohun elo amuletutu (Air conditioning system) lo gbọdọ wa ni pipa nigba gbogbo.
  • Awọn ọkọ olomi yoo lee ṣiṣẹ laarin agogo mẹfa aarọ si mẹfa irọlẹgbogbo awọn ile ijo,, ilee sinima ati ibudo igbafẹ etiokun gbogbo ni yoo ṣi wa ni titi pa gbọingbọin.

Coronavirus Cases in Africa: Olórí ẹ̀ṣọ́ Adarí ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Bola Ahmed Tinubu ti kú lẹ́yìn tó lùgbàdì àrùn Coronavirus

CORONAVIRUS

Oríṣun àwòrán, Others

Adari ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti kẹdun Olori ẹsọ alaabọ rẹ,Alhaji Lateef Raheem to ku lẹyin to lugbadi arun Coronavirus.

Tinubu fi eyi lede ninu atẹjade ti ikọ iroyin adari naa buwọlu.

Ninu atẹjade naa ni Tinubu ti fi lede wi pe oun ati iyawo oun ko ni arun Coronavirus lẹyin ti awọn ṣe ayẹwo.

Adari ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ni awọn gbe igbese lati se ayẹwo naa kete ti ayẹwo fi lede pe arun Coronavirus lo pa Alhaji Raheem.

Amọ wn ni ọkan ninu awọn oluranlọwọ fun Bola Tinubu ti lugbadi arun naa to si ti ya ara rẹ sọtọ.

Wọn fikun pe Ajọ̀ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria,NCDC ti bẹrẹ si ni wa awọn ti wọn ti ni ibaṣepọ pẹlu oloogbe naa fun ayẹwo arun Coronavirus.

Ogoji eniyan lo ti ku lorilẹede Naijiria lati igba ti arun Coronavirus naa ti bẹrẹ si ni ja rain ni Naijiria.

Èèyàn mẹ́rin péré ló ní àrùn Coronavirus ni Ọjọ́ Satidé

Ajọ to n ri si igbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC fi sita loju opo Twitter rẹ eniyan mẹrin lo lugbadi arun Coronavirus ni Ojọ Satide ni ilu Kano.

Ninu atẹjade ti ajọ naa fi si oju oppo ikansiraẹni Twitter wọn ni ajọ naa ti fi lede bẹẹ.

Coronavirus

Amọ eyi ti fa ariyanjiran ni oju ọpọ ikansiraẹni Twitter ti ọpọlọpọ eniyan si n bere pe ki lo n ṣẹlẹ ni ipinlẹ Kano.

Awọn miran n sọ wi pe oye eniyan to ti lugbadi arun naa ju oye naa lọ.

Èèyàn mọ́kànlá kú lọ́jọ́ kan ṣoṣo ní Kano

O kere tan, eniyan mọkanla lo di oloogbe niluu Kano lọkọ kan, ṣugbọn ko si ẹni to le sọ bo ya aarun coronavirus lo ṣeku pa wọn.

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Ọpọlọpọ awuyewuye lo n lọ lori iye eniyan to ti kọ arun Coronavirus ni ipinlẹ naa ati ọna ti ijọba n gba lati dojukọ itankalẹ arun naa.

Iroyin ti a gbọ ni pe ọga agba banki kan to n reti esi ayẹwo to ṣe fun aarun covid-19 wa lara awọn to ku naa.

Alakoso igbimọ to n ri si ọrọ covid-19 nipinlẹ Kano, Dokita Tijani Hussaini lo fidi ọrọ yii mulẹ.

O ṣalaye pe o digba ti esi iwadii ba jade lori ohun to ṣ'okunfa iku awọn eniyan naa ki awọn to le mọ bo ya aarun coronavirus lo pa wọn.