Coronavirus: Àwọn ìpèníjà nípa ṣíṣe iṣẹ láti ilé lásìkò COVID 19 yìí

Ni ibẹrẹ osu kẹrin yi la mu awọn imọran wa funun yin lati ọdọ awọn onimọ nipa bi a ti le se isẹ wa daadaa lati ile.
A ti pa diẹ lara awọn imọran ti ẹyin naa fi sọwọ pẹlu ti wọn.
Awọn imọran to le mu ki ẹ gbadun sise isẹ lati ile lasiko idejumọle to n lọ lọwọ lasiko konile-o-gbele yii
Wo diẹ lara awọn aba ati ọna ti yoo jẹ ki ṣiṣe isẹ lati ile rọrun sii lasiko konile-o-gbele coronavirus yii:

Sarah M, to n sisẹ nilu London ni oun ti wa ri wi pe didanikanwa jẹ nkan to maa n mu irẹwẹsi ba ọkan.
O rọ awọn eeyan lati ma se fojudi anfani ibaraẹni sọrọ to ti wa tẹlẹ saaju ajakalẹ yi.
Haralds Gabrans, a to wa lati orile-ede Latvia ni o nira fun oun lati gba pe bi nkan yoo ti se maa ri ree ati pe yoo to ọsẹ meloo kan ti o to dopin.
Yatọ si gbogbo ipenija wọn yi, awọn kan ti sawari pe sise isẹ lati ile lasiko ajakalẹ yi si le jẹ ọna isẹ to sanfaani pupọ paapaa ti eeyan ba ni awọn isesi to daa ati ibalẹ ọkan ti yoo mu ki isẹ lọ deede.
Fifi eto si iṣẹ ati ifaayesilẹ ṣe pataki:
Ọpọ lo ti sọ fun wa pe awọn n sisẹ fun wakati to pọ tawọn ba wa nile ju ki awọn wa ni ibi isẹ lọ.
Lalai si awọn alabasisẹ ti yoo tawọn lolobo pe asiko ti to lati lọ jẹun tabi ki wọn nasẹ diẹ, eeyan o kan maa sisẹ lọ bi aago ni.
Aba tawọn eeyan muwa ni pe ki a fi eto si isẹ wa ki a si faaye kalẹ fun isinmi loore-koore.
Angeliki (Pavlou) Heinz, da ọrọ to wa nilẹ yi bi ọgbọn.
Ohun ati ọkọ rẹ a ma saaba pade ni ile idana wọn lasiko isinmi bi igba pe ibi isẹ ni wọn wa.
Diana Wilson to jẹ ọga agba nile isẹ Tracemyfile ni ilẹ Gẹẹsi ni tiẹ sọ pe awọn ki fi asiko ounjẹ aarọ, ọsan tabi talẹ sẹre, koda bi isẹ ba pari tabi ti ko pari nile.
Christina Brazzale, ni sise isẹ lati ile ko ni awọn nkan ti yoo ma dari ọkan kaakiri pupọ bi ki eeyan wa ni ibisẹ.
O ni ''bayi ti mo wa nile, mi o ki n fi asiko ti maa rin jade lati gba oorun tabi atẹgun sara ṣere.
O tẹsiwaju pe "Bi mo ti se wa nile yi, o fun mi laanfaani lati mu asiko isinmi mi ni koko yatọ si ti mo ba wa ni ibisẹ''
Bakan naa wiwa nile a maa mu ki awọn eeyan mi maa sare lati pari isẹ ti wọn n se, awọn eleyi ti wọn yan fun ara wọn ati isẹ ile lẹẹkan naa.
Imọran ti Hannah Allyse Kim ati awọn mi mu wa ni pe ,ma se ju ara rẹ lọ.
Sebi-o-timọ bi ẹlẹwa sapọn. Asaretete ko ni kọja ile bẹẹ ni aringbere ko ni sun sọna ni imọran pe ki onikaluku ṣe iṣẹ niwọnb ko si maa dide.
Wọn kadi imọran yi pe ki a ri pe a ni eto ati ilana ta fẹ fi se isẹ wa lojojumọ.
Eleyi ko ni mu ki a kan maa daamu ara wa lasan.
Wa ọna orisi lati fi ṣe iṣẹ rẹ:
Fun ọpọ eeyan nise ni ọjọ yoo dabi ẹni pe ko fẹ tan. Irẹwẹsi ọkan ti n mu ki gbogbo ọjọ ri bakan naa loju wọn.
Imọran ti wọn le fi koju eleyi tawọn eeyan mu wa ni pe ''ẹ sisẹ nibi ti atẹgun yoo ti maa fẹ si yin daadaa.
Bi o ba ṣe pe ki ẹ tẹni si abẹ igi ni tabi ki ẹ duro ni faranda yin, eyi ko ni mu ki isẹ tete su u yin.
Anastasia Balandina lati London ni balikoni oun loun ti maa n sisẹ ti oorun ba ti jade.
O ni o maa n tu oun lara gan an ni
Yatọ si eleyi, ọna miran ti a le fi gbadun sise isẹ wa lati ile ni pe ki a wa awọn ere ti awa ati awọn mọlẹbi wa yoo jijọ maa se.
Bi o ba se wi pe ki ẹ jijọ maa se bojuboju tabi sise ipade ranpẹ lori oun tẹ ẹ fẹ se ni ojumọ kọọkan lẹ ba yan laayo, ko si ọna ti ẹ yan ti ko ni jẹ ki ẹ gbadun isẹ yin lati ile.
E ma jẹ ki o yọ awọn ọmọ yin silẹ:
Awọn to ba n sisẹ lati ile ti awọn ọmọ wọn wa lọdọ wọn a maa ronu bi awọn yoo ti se sisẹ pẹlu wahala itọju ile.
Imọran ti ọpọ fi sọwọ ni pe ki eeyan wa nkan ti awọn ọmọ yoo ma se lasiko ti eeyan ba n se isẹ rẹ bi ki wọn ma tun ile se,sise ere idaraya tabi ki lọkọlaya ma bawọn sere laarin ara wọn.
Emma Cantril, to jẹ oludasilẹ ileesẹ Intelligent Profile ni ilẹ Gẹẹsi ni oun ti ni isẹ toun ya sọtọ fawọn ọmọ oun lojojumọ.
Lati igba ti mo ti n sisẹ lati ile bi nkan bi ogun ọdun sẹyin ipenija ti o lagbara ti mo le tọka si ni pe bi maa ti se yanju asọ fifọ, ina dida, ile titunsẹ ki n si tun lee se isẹ mi pẹlu ifọkanbalẹ.
O ni ki wahala naa ma baa le fẹ se oun lese, oun a maa ri pe onikaluku lo ni isẹ tiẹ ti yoo ṣe lojumọ.
O ni bi bẹẹ kọ, eeyan ko ni le se gbogbo rẹ pọ pẹlu asiko perete to wa nilẹ.
Bẹẹ lọrọ ri lọdọ ọgbẹni Jonathan Wareham lati Italy ti isede ka oun, iyawo rẹ ati awọn ọmọ mẹta mọle.
O ni yiyan isẹ fun onikaluku se pataki bẹẹ si ni o yẹ ki eeyan maa nasẹ sita lẹẹkọọkan naa se pataki.
''Sisọ otitọ fun ara rẹ ati awọn ọmọ rẹ nipa oun to n sẹlẹ se pataki''
Ma se bọkan jẹ ninu gbogbo wahala idejumọle to wa nita yi, awọn to fi imọran sọwọ siwa ni ki a gba kamu ka si ma se ba ara wa lọkan jẹ.
Wareham ni lati ilẹ lo ti yẹ ki ọkan eeyan gba kamu ohun to delẹ ki o si ri i gẹgẹ bii ''asiko ti eeyan yoo mu idagbasoke ba ara rẹ ati mọlẹbi rẹ.''
O ni bi oun ati mọlẹbi oun ti se bẹrẹ si ni gbe igbe aye wiwapọ pẹlu ara wọn yi, oun ti se awari awọn kudiẹ-kudiẹ to wa ninu iwa oun ti oun si ti n se atunse.
O ni ki awọn eeyan gbiyanju lati gbadun aise nkankan yi ki wọn si gba pe gbogbo nkan ni yoo yi pada bọ sipo to ba ya.
Ni pataki, o ni ki a ma gbagbe pe mọlẹbi wa se pataki pupọ.
O ni ki a ri asiko idejumọle yi bi eleyi ti a o fi jẹ ki irẹpọ tubọ rinlẹ ninu mọlẹbi wa.
O sọ pe ki a ma gbagbe pe itan manigbagbe ni a n fi lelẹ lasiko yi eleyi ti ko ni si ẹni ti yoo gbagbe rẹ ninu mọlẹbi wa.
















