Didier Drogba: Agbabọọlu to fí okiki dáwọ ìjà ogun abẹ́lé dúró n'ilẹ baba rẹ

Oríṣun àwòrán, others
Ni papa isere Al-Merrikh Stadium ní orile-ede Sudan ní iṣẹlẹ kan to mí agbo ere bọọlu n'ilẹ Afrika ti waye.
Ọjọ kẹjọ, oṣù Kẹwaa, ọdún 2005 ni ọjọ ta n wí yi.
Orile-ede méjì Cameroon àti Ivory Coast jó n du aye ẹni tí yóò tẹsiwaju ninu ìsòrí wọn láti kópa níbi ìdíje ife ẹyẹ bọọlu agbaye ni odun 3006.
Lara awọn to lewaju iko Ivory Coast ni akinkanju agbaboolu kan ti orukọ rẹ n jẹ Didier Drogba.
Yatọ si Drogba awọn ilumọọka agbabọọlu miran bi Yahya Touré, Kolo Touré ati Emmanueli Eboue wa lori papa ti ireti sí wa pé wọn yóò jáwé oluborí.
Tohun ti bi awọn wonyi ṣe n gbero pé ki wọn fi itan lelẹ, paapaa bi ohun tó n ṣẹlẹ ni orile-ede wọn kò ṣe fararọ nitori ogun abẹ́lé to n gbegi dina alaafia ara ilu.

Oríṣun àwòrán, others
Ààrẹ Laurent Gbagbo ati awọn ọmọ ogun rẹ ni wọn n se akoso guusu ile naa ti awọn ọmọ ogun ọlọtẹ Guilamme Soro si di agbára mú ni ariwa ilẹ náà.
Ki wa ni Drogba ṣe tó mú dì ilumọọka agbabọọlu n'ilẹ rẹ?
È tẹti kí ẹ ma bawa kalọ.
Nínú Ifesewonse to waye ní Sudan, ni ikọ agbabọọlu Ivory Coast ti da bantẹ iya góòlù mẹta si ọkan fún wọn.
Inu gbogbo ọmọ Ivory n dun ṣugbọn ki won to lè mọ bóyá wọn yóò tẹsiwaju tabi bẹẹkọ; wọn nilati kópa nínú ìdíje ife ẹyẹ agbaye ní ọdún 2006,
Cameroon ti awọn náà n gba bọọlu lọwọ pẹlu Egypt ni lati gba ọmi. Gbogbo ile Ivory Coast lo n se ádùrá kikan-kikan kí Cameroon fidiremi.

Oríṣun àwòrán, others
Aseyin wa aseyinbọ, Ivory Coast lo tẹsiwaju lọ ìdíje agbaye.
Idunnu ṣubu lù ayo fún gbogbo ilẹ náà tí kò sì sí ìyàtọ̀ kánkan láàrin àwọn tó n dojú ìjà kọ ara wọn mọ ;asiko ajọyọ ọhun.
Níwájú àwọn akọroyin lágbayé, ni Didier Drogba ti sọrọ ti o si parowa sí àwọn tó n já pe ki won dẹkun ija wọn.
'Ẹ jọwọ ẹ da ibọn yin silẹ; ki ẹ si kópa nínú eto idibo, Ati ọkunrin ati obinrin ilẹ wa, lóni a fihan pe gbogbo wa le jijọ gbe pọ ti a ko ro boya èèyàn kan wà lati goosu tabi Ariwa Ọkan ní gbogbo wa.
Ori ijinle lémi ati awọn akẹgbẹ mí wa, è gbà alaafia láàyè n'ilẹ wa."
Aworan bí Drogba ati awọn akẹgbẹ rẹ tí ṣe kunlẹ bẹ awọn ologun láti gba alaafia laaye jẹ nkan ti awọn Ileese amohunmaworan kaakiri fi n hàn n'ilẹ wọn.
Ko pe kò jìnà sí ọjọ yí, àwọn tó n já gba lati joko forojomitooro ọrọ tí wọn sì dà ọwọ ija duro.
Bi o ba se wí pe ere fiimu ni ọrọ ti a n so yí jé ní, enit to kọọ yóò ti ni eleyii to lati fi pari ere idinnut yi, ṣugbọn kò tan sibe.
Leyin ti Ivory Coast dari pada nibi idije Ife ẹyẹ agbaye ta n wí yi lọdun 2006 ni Drogba kéde lasiko to n se àbẹwò sí àgbègbè ilu rẹ ni Bouake láwọn yóò tí gba Ifesewonse to n bọ lọnà pẹlu Madagascar.
Iyalẹnu ni ọrọ yii jẹ nitori Bouake ta n wí yii dàbí ilé agbára àwọn ọmọ ogun ọlọtẹ.
Kò dájú pé Drogba gba iyọnda lọdọ ààrẹ ko tó kede ọrọ yí ṣugbọn nitori ifẹ tàwọn èèyàn ni ṣi ìdíje bọọlu, sibẹo ṣi wáyé níbẹ.
Ọjọ nla ni ọjọ ti a n wí yi ti orile-ede Ivory Coast si borí Madagascar pẹlu ami ayo márún ún sí odo.

Oríṣun àwòrán, others
Kete ti ìdíje yí parí ni gbogbo èèyàn rọ si ori papa ti won ko si fi ti ẹyà ṣe nínú idawọ ìdùnnú lọjọ ta n wí yi. Gbogbo Ivory Coast lo duro gẹgẹ y ọkan ti iṣẹlẹ yí sì tún so gbogbo ilẹ náà papo gege bí ọkan.
Ṣugbọn ìdùnnú yi ko pẹ to fi tun di ìbànújẹ nitori awọn ọmọ ogun ko dawọ ija duro.
Ọdún marun un lẹyìn ogun tun waye nitori ija to tẹlẹ esi ìdìbò. Èèyàn tó tó egberun mẹta ló bá ija yi lọ.

Oríṣun àwòrán, others
Ọwọ tẹ ààrẹ Gbagbo ti ọ sí dero ile-ejo agbaye níbi tí wọn ti fesuny kan pe o da ẹsẹ nla to fako ijẹ ọmọnìyàn.
Ni oṣù kínní ọdún 2019 won tu sile pe kò jẹbi amọ ọ di wa ni àhámọ́ láti jejo ko-te-mi-lorun
Nínú inu fo àyà fò ni ilẹ Ivory Coast wa lo in I ṣugbọn awọn èèyàn ilẹ náà kò ní gbàgbé ipá ribiribi tí Didier Drogba àti àwọn akẹgbẹ rey ko lati mu alaafia ba ile won.

Oríṣun àwòrán, others
Bo tile je pe wọn ko ribi gba àmì ẹ̀yẹ láwọn ìdíje agbaye ti won ti kopa, orukọ wọn kò ní parẹ nínú ìtàn ilẹ wọn.
Awọn ìkọ yí fihàn pé bí a bá gbaruku ti ara wa kò sí bí a kò ṣe ni jo gbe ní àlàáfíà.
Odun 2018 ní Didier Drogba feyinti nìdí eré bọọlu.
Akínkanjú agbaboolu ti awọn ololufẹ rẹ lọri pápá àti lorile-ede rẹ kò ní gbàgbé láyè láyé ni.
















