Kurunmi: Akọni Ààrẹ Ọ̀nà Kakanfo tó pàdánù ọmọ márùn-ún to bí sínú ogun Ìjàyè

Oríṣun àwòrán, Other
Ní ayé àtijọ́, onírúurú ogún lo tí wáyé láàárín ẹ̀yà Yoruba sì àwọn ẹ̀yà miran àti ní àárín ara wọn pẹlu.Ọkàn pàtàkì nínú irufẹ ogun bẹẹ ni ogún ìjàyè tó wáyé láàárín Ààrẹ Ọ̀nà Kakanfo ìgbà náà, tí wọn pé ní Kurunmi àti Balogun Ibikunle pẹ̀lú Basorun Ogunmola tí ilẹ̀ Ibadan, to fi mọ àwọn ìlú miran ni ilẹ̀ Yorùbá. Ilu Ìjàyè yìí jẹ́ ìlú kékeré kan tí wọ́n dá silẹ lọ́dún 1785, o si wà lójú ọna Ibadan si Isẹyin, tí gbogbo wọn wa ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ báyìí. Gẹ́gẹ́ bá ṣe rii ka lójú òpó itakun agbaye àti nínú àwọn inú ìwé ìtàn lorisirisi, onírúurú nkan lo ṣokùnfà ogun Ìjàyè àti ìṣubú Ààrẹ Kurunmi.
Bí ogún Ìjàyè àti ìṣubú Ààrẹ Kurunmi ṣe bẹ̀rẹ̀ rèé:Ilu Ọ̀yọ́ ijọ́hun ni ibujoko agbára àti ìṣàkóso àwọn ìlú yooku nílẹ Yoruba,
ìlú Ọ̀yọ́ yìí sí ní àwọn ìlú yoku máa ń ṣàn isakọlẹ si lọdọ Aláàfin, tí wọn gba gẹgẹ bii olórí wọn.Ayé Aláàfin Abiodun sì ni ọmọ-ọmọ rẹ, Orisabiyi, tí ọmọ Aláàfin Abiodun obìnrin bí, dá ìlú Ìjàyè silẹ, tí Kurunmi sì jáde láti ìlú Ọ̀yọ́ lọ tẹ̀dó si ìjàyè nígbà tó di aarẹ ọna kakanfo àti alágbára jagunjagun, tí kò leè bá Aláàfin wá n'ilu Ọ̀yọ́.
Awọn Fulani gbógun ti ilu Ọ̀yọ́ , tí ìjọba Ọ̀yọ́ si dojú dé lọ́dún 1831, àmọ́ tí ikọ ọmọ ogun Ibadan gba ominira Ọ̀yọ́ padà lọ́wọ́ Fulani lọdun 1840.Kò pẹ ní Ibadan, tíì ṣe ìlú tó tóbi julọ nilẹ Yoruba, pé ìpàdé pẹlu awon ilu miran nilẹ Oodua.,
Afojúsùn rẹ sì ni láti wá ọna ti ìṣọ̀kan àti irẹpọ yóò fi padà silẹ Yoruba,
Nibẹ sì ni wọn ti fẹnu ọrọ jóná pé, kí gbogbo ìlú nilẹ Yoruba máa san isakọlẹ wọn fún ìlú Oyo tuntun lábẹ́ Aláàfin Atiba, tó jọba lẹ́yìn ogun Fulani.
Ìlú Ibadan àti ìjàyè tí Ààrẹ Ọ̀nà Kakanfo ń gbé si ni Aláàfin Atiba gbara le julọ, ti àwọn olórí ìlú méjèèjì náà sì jẹ òye ologun, Aṣáájú Ibadan nígbà náà, Ibikunle jẹ́ Balogun, tí Kurunmi sì ti jẹ́ Ààrẹ Ọ̀nà Kakanfo. Nítorí pé ìjàyè ni olórí ogún wá, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń lọ tẹ̀dó si ilu naa, tó sì ń fẹ́ ju si lojoojúmọ́, tí wọ́n sì ń gbà ìlú náà lọ ṣe oko-owo ńlá.Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ajihinrere lo bẹ̀rẹ̀ sii tẹ̀dó si Ìjàyè nígbà ti yoo fi di ọdún 1854.

- Coronavirus: Àwọn ohun tí a kò tíì mọ̀ nípa àrùn Covid-19
- Kí lo mọ̀ nípa fẹntilétọ̀, ohun èlò aṣèrànwọ́ èémí
- A fẹ́ lo ẹ̀jẹ̀ àwọn èèyàn tó ye àrùn Coronavirus láti fi ṣe ìwòsàn fún àwọn tó wà lórí àárẹ- UK
- Coronavirus: Kíni àwọn àmì tuntun tó n fihàn?
- Ọjoọ́ mélòó ni Coronavirus ń lò lára kí ènìyàn tó gba ìwòsàn?

Ninú èyí taa tí rí ara àwọn oludasilẹ ìjọ onitẹbọmi Baptist, Ẹni-ọwọ Thomas Bowen, to da ilé ẹ̀kọ́ silẹ ni ilu naa ati ìjọ onitẹbọmi àkọ́kọ́ ni Naijiria.
Lásìkò yìí, Kurunmi tí di alágbára ńlá, tí oun ati awọn Ẹ̀gbá pẹ̀lú Ìjẹ̀bú sì ń ṣiyèméjì lórí àwọn òfin tí Ibadan gbé kalẹ ọhun
Iyẹn eyi tí Ààrẹ Kurunmi sì ń fura pé, Ibadan fẹ dá ìjọba tiẹ̀ silẹ ni, tó sì fẹ́ gba agbára lọ́wọ́ ìlú Ọ̀yọ́.

Oríṣun àwòrán, Other
Ifura Kurunmi yìí ń di òótọ́ nígbà tí Ibadan tẹsiwaju láti máa gba isakọlẹ lọ lọ́wọ́ àwọn ìlú amọna tó wa lábẹ́ rẹ, tó si ń rọ Ìjàyè pé kó lọ san isakọlẹ tiẹ̀ sì Ọ̀yọ́, lai gba àwọn ìlú abẹ rẹ láàyè láti ṣe bẹ́ẹ̀.Ọ̀rọ̀ yìí ń lọ bẹẹ títí di ìgbà tí Aláàfin Atiba waja lọ́dún 1859, tí Ibadan sì tún yari pé ọmọkùnrin Atiba, tí orúkọ rẹ ń jẹ Adelu, ni yóò gùn orí itẹ àwọn baba ńlá rẹ, lai tẹle ìlànà oyè jíjẹ nílùú Ọ̀yọ́.A gbọ pe ki Aláàfin Atiba to waja, lo tí fi ohùn silẹ pé Adelu, tíì ṣe àkọ́bí òun, ní òun fẹ́ kó jẹ ọba lẹ́yìn òun. Èyí sì lòdì sí ìlànà tó wà nílẹ tẹ́lẹ̀, torí àkọ́bí Aláàfin gbọ́dọ̀ kú pẹ̀lú rẹ ni.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìlú yòókù nilẹ Yorùbá fara mọ èyí, aarẹ Kurunmi nìkan ló yari pé kò leè rí bẹ́ẹ̀ rárá, àṣà adayeba ìlú Ọ̀yọ́ kò sì gbọ́dọ̀ parun.Nígbà tí Aláàfin Atiba sì waja lọ́dún 1859, Adelu lo jọba lẹ́yìn rẹ lóòótọ́, tí Kurunmi kò sì lọ síbi ayẹyẹ iwuye rẹ tàbí fún ní ọwọ gẹ́gẹ́ bíi Aláàfin.Onírúurú èèyàn ni wọ́n rán lọ sipẹ fún Kurunmi àmọ́ tí kò gbà rárá láti tẹ síbi tí àwọn ìlú yòókù nilẹ Yoruba tẹ sì. Kurunmi woye pé Ibadan gbé igbesẹ náà, ko leè rọrùn fún láti tẹsiwaju nídìí isakọlẹ tó ń gba lọ́wọ́ àwọn ìlú tó wà ní abẹ rẹ ni, tó sì tako Ibadan lórí ìpinnu náà.
Ibadan ń tiẹ̀ ni Kurunmi, tii se Ààrẹ Ọ̀nà Kakanfo fẹ́ di Aláàfin, lo se n tako òun, òun náà kò si ní gbà kó di Aláàfin lẹ́yìn Atiba, torí Kurunmi yóò di olórí kunkun bii Afonja ni.Nígbà tí wọ́n ko ri ojútùú sì aigbọraẹniye yìí lo bá di ogún, ìṣẹ̀lẹ̀ náà sì ló bi ogún Ìjàyè.Àwọn ìlú tó darapọ mọ ogún ìjàyè:Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú ìjàyè, Ọ̀yọ́ àti Ibadan lo dojú kọ ara wọn lórí ogun náà, tó wáyé laarin Ààrẹ Kurunmi tí ìjàyè àti Balogun Ibikunle pẹ̀lú Basọrun Ogunmola tí ìlú Ibadan; síbẹ̀ àwọn ìlú miran nilẹ Yoruba naa darapọ mọ ogun ìjàyè nítorí onírúurú ìdí.
Àwọn Ẹ̀gbá darapọ mọ ogun ìjàyè, tí wọn sì gbé sẹ́yìn Kurunmi láti tako Ibadan, kò máa bàa di aṣáájú miran fún ẹ̀yà Yoruba.Àwọn Ìjẹ̀bú náà tẹle Kurunmi lẹ́yìn láti tako Ibadan, lọ́nà àti dáa lọwọkọ, nìdí ìgbésẹ tó ń gbé láti dá èdè aiyede silẹ laarin Ìjẹ̀bú àti Remo,
Eyí tí yóò fun Ibadan láǹfààní láti rí ọna kọjá si etí òkun feto okoowo.Bákan náà ni ẹ̀yà Fulani tí Kurunmi tí ìjàyè lẹ́yìn, láti fi iya jẹ ibadan torí bo se di wọn lọwọ láti tán ẹṣin Islam yíká ilẹ Yoruba.Bí wọn ṣe ja ogún ìjàyè àti òpin rẹ Ikọ ogún Ibadan tẹ̀dó sì ẹba odò Ọsẹ, èyí tó to maili mẹ́tàlá sì ìlú ìjàyè, nígbà tí ogún ìjàyè, èyí tí Kurunmi àti Ogunbona tilu Abeokuta kò sódì, tẹ̀dó si ilu Olokemeji, tó wá ní ẹba odò Ogun.
Ikọ ogun Ibadan máa ń rán alami loore-koore láti mọ bí ogun ìjàyè tí ń ṣe sí, èyí sì lo mú kí wọn mọ pe ìlù ni wọn máa ń lu láti pàṣẹ fun ikọ ogún Ìjàyè pé kí wọn tẹsiwaju láti ibi tí wọ́n tẹ̀dó si.
Ìlù yìí sí ní ikọ ogún Ibadan lù láti tán àwọn ọmọ ogún Ìjàyè jáde pé kí wọ́n rekọjá odò Ọsẹ, tí kò jìnnà sí ibi tí wọ́n wa, èyí to yí ogun Ìjàyè lọ́wọ́ pátápátá.

Oríṣun àwòrán, Other
Bí wọn ṣe gbọ ìlú yìí ni igbakeji Kurunmi ni kí wọn rekọja odò, ọwọ ọmọ ogun Ibadan si ni wọn bọ si, tí wọn si ge orí ọmọ Kurunmi to wa lójú ogun.Orí ọmọ yìí ni wọn fi ransẹ si Kurunmi, láti pa asamọ fún pé ó ti fidi rẹmi nínú ogun náà, ibanujẹ si ni èyí jẹ fun Kurunmi torí ọmọ rẹ maraarun lo bá ogun náà lọ. Àmọ́ àkọsílẹ̀ miran ṣàlàyé ọ̀nà míì tó yàtọ̀ tí ikọ ogun Ibadan gba borí ogun Ìjàyè.A gbọ pé awọn ọmọ ogún ìjàyè, Ẹ̀gbá, Ìjẹ̀bú àti Fulani di ọ̀nà mọ àwọn ọmọ ogún Ibadan, ki wọn máa leè ni anfaani sì àwọn èròjà tí àwọn oyinbo aláwọ̀ funfun ń kó wá bíi iyọ̀, ẹtu àti bẹẹ bẹẹ lọ.
Iọ ọmọ ogún Ibadan náà sì di ọ̀nà mọ ìjàyè, èyí tí kò jẹ ki wọn kó oúnjẹ wọlé síbẹ̀ àmọ́ àwọn oyinbo fà ojú àwọn Remo tó wà ní ìlú Sagamu ati Ikorodu mọ́ra,.
Eyí tó mú kí wọn ráyè kò àwọn ohun ìjà ìgbàlódé láti Eko wá sí Ibadan.Atilẹyin àwọn oyinbo Gẹ̀ẹ́sì nìdí ìpèsè ohun ìjà igbalode tí Ibadan rí gbà yii, lo mú kó rọrùn fún láti ṣẹ eegun ẹyin àwọn ọmọ ogún ìjàyè lọ́dún 1862, tí ogún náà sì wà sopin lẹ́yìn odidi ọdún kan gbáko. Ikú Ààrẹ KurunmiBí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tó mọ ikú tó pa Ààrẹ Kurunmi, akọni, jagun-jagun alagbara àti Ààrẹ Ọ̀nà Kakanfo nígbà náà, àmọ́ ìròyìn kan ni, ó gbé majele jẹ n.
Wọn ni o ṣe eyí kí ojú má baa tii nígbà tó rí pe ogún náà tí dojúrú mọ òun lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Other
Ìtàn sọ pé Kurunmi ro ó pe, ki lo tún kù tí òun fẹ́ máa mú láyé mọ nígbà tí ọmọ rẹ maraarun tó bí sáyé, tí bá ogun lọ, tó si gba ẹ̀mí ara rẹ.Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sí lo mú kí àwọn ikọ Ogun Ìjẹ̀bú, Ẹ̀gbá àti Fulani to ń ṣe atilẹyin fun ìjàyè tètè fà sẹ́yìn lójú ogun, nígbà tí wọn rí pé olórí ogun ti awọn tẹle tí di ara ilẹ̀.Àwọn asamọ àti òwe tó jẹ mọ́ ogun ìjàyè: Asamọ tó nii ṣe pẹlu ogun ìjàyè lo ni "ọpẹ Ìjàyè là bá bí léèrè ogún Ogunmola"Òwe tó sì rọ mọ ogun náà lo ní "A kì ni, n jẹ a kì ni, a fi ní hàn, n jẹ a fi ní hàn, èwo ni ọọku ara Ìjàyè ni ojúde Ogunmola"Ẹ̀kọ́ tí ìtàn ogún Ìjàyè kọ́ wa:
Ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ tí ogún Ìjàyè kọ wá ni pé, ká ṣe ara wa ni ọkàn nilẹ Yoruba.Ẹ̀kọ́ kejì ni pé ogun Ìjàyè kọ wa lati gba àlàáfíà láàyè láàárín ara wa, lai fi ààyè gba èdè aiyede àbí ìkùnsínú.Ẹ̀kọ́ kẹta ti ogun Ìjàyè kọ wa ni pe ti àlàáfíà bá wà nílẹ Yoruba, àwọn ará ìta kò ni ráyè dá sí ọ̀rọ̀ wa lati mú iyapa wa.A tún kọ nínú ìtàn yìí pé, kò yẹ ká máa jẹ gàba le ara wa lori, tàbí fi tipa wá ipò aṣáájú nítorí ọmọ iya kan náà ni wa nilẹ Yoruba. Ẹ̀kọ́ miran ti ogun náà tún kọ wa ni pe, ko si èrè kankan ta fẹ́ jẹ́ nínú ogun jija, a kàn fi ẹ̀mí ṣòfò ni.















