Richard Akinjide: Ìtàn igbe ayé Richard Akinjide, agbẹjọro àti olóṣèlú tó moye

Yoruba ni awaye ku kò sì, kò sì ẹni tí kò ní kú, kò si ẹni ti oko baba rẹ kò ní di igboro.
Kii se ìròyìn tuntun mọ pe orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tún ti padanu ọkàn lára ojúlówó ọmọ orílẹ̀ èdè yìí, èèkàn ìlú àti àgbà amofin, Olóògbé olóyè Richard OSUOLALE Abimbola Akinjide.
- Lórí ọ̀rọ̀ Ogun Majek, mi ò lọ́rọ́ láti sọ, ẹ lọ pe ẹni tára rẹ̀ kò yá- Mr. Latin lórí àìsàn Ogun Majek
- Coronavirus: Kíni àwọn àmì tuntun tó n fihàn?
- Ìyàwó mi ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ tuntun, kò si oúnjẹ fún wa torí ìgbélé Coronavirus- Yakubu
- Ewu ń bẹ! Coronavirus lè tara òkú Abba Kyari ran àwọn tó péjú síbi ìsìnkú rẹ̀- Ààrẹ ẹgbẹ́ dókítà ní Nàìjíríà
Ìdajì kutu òwúrọ̀ ọjọ́ Isẹgun ni ìròyìn tán kalẹ pé erin tí wó, akọni amofin tí lọ, bẹ́ẹ̀ sì lo yẹ ká mọ àkọsílẹ̀ àwọn ohun tó gbé ilé ayé ṣe.
Gẹ́gẹ́ bàa tí ká a lójú òpó itakun agbaye, ọdún mọkandinlaadọrun ni olóògbé Akinjide lo lókè erupẹ, kò tó tẹrí gbasọ, bí ìtàn ayé rẹ sì ṣe lọ ree:
Ìtàn ìgbé ayé Richard Osuolale Akinjide:

Ìlú Ibadan, tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Osuolale forí sọ ilẹ̀ sì ni ọdún 1930, ní agboolé Aperin, ládùúgbò Orita Aperin n'ilu Ibadan.
Agboolé Aperin jẹ ìdílé àwọn akíkanjú jagunjagun láyé atijọ, a sì leè ni ẹ̀jẹ̀ lọ ro Osuolale, tí òun náà fi jẹ akíkanjú ẹ̀dá lókè eepẹ.
Ilé ẹ̀kọ́ gírámà Odùduwà College nílùú Ilé-Ifẹ̀ ni Osuolale lọ lẹ́yìn tó parí ẹ̀kọ́ alakọbẹrẹ ni Ibadan, tó sì ṣe àṣeyọrí ńlá nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Others
Ọmọ ti yoo jẹ́ Ásàmú ni ọrọ Osuolale, kékeré lọ tí ń jẹ ẹnu samu-samu nítorí esi idanwo ipele àkọ́kọ́, taa mọ sì Grade one ni Osuolale mú jáde nínú ìdánwò asejade, gbogbo iṣẹ tó sì jókòó sedanwo rẹ, lo yege pátápátá.
Àṣeyọrí alailẹgbẹ yìí ló ṣe iwuri fáwọn òbí rẹ láti jẹ ko tẹsiwaju lẹ́nu ẹ̀kọ́ rẹ lọ sókè òkun lọ́dún 1951, láti lọ kọ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin nílùú Ọba United Kingdom (UK), to sì yege ni ọdun 1955.
Osuolale ni ifẹ ilẹ̀ bàbá rẹ pupọ, ìdí si rèé tó fi pinnu láti má ṣe jókòó silu ọba, àmọ́ ó padà wá sile láti wá da ẹ̀ka isẹ agbẹjọro tiẹ̀ si orílẹ̀ èdè Nàìjíríà èyí tó pe orúkọ rẹ ní Akinjide & Co.
Osuolale ṣe gùdù gùdù meje àti ya ya mẹ́fà nídìí isẹ agbẹjọro ni Nàìjíríà, tí òkìkí rẹ sì kan yíká ilẹ̀ yìí àti lókè òkun, a kò sì lè e gbàgbé inagijẹ Mr two third tí wọn ń pé olóògbé náà.

Osuolale, gẹ́gẹ́ bíi agbẹjọro àgbà fún ẹgbẹ́ òṣèlú NPN, ẹgbẹ́ Onílé nígbà náà, gba inagijẹ Mr two third ọhun, nítorí bo se kéde lórí redio lọ́dún 1979 lẹ́yìn ibo aarẹ tó gbé Alhaji Shehu Shagari wọlé pé, idà méjì nínú mẹta ìpínlẹ̀ mọkandinlogun tó wà ní Nàìjíríà jẹ́ 12 2/3.
Ọ̀nà kan kò wọ ọjà ni ọrọ Osuolale nítorí bo ti ń ṣe agbẹjọro lọ tún mú oselu mọ isẹ rẹ, tó sì jẹ minisita feto ẹ̀kọ́ ni ṣáá eto ìṣèlú àkọ́kọ́, ni ayé ijọba Tafawa Balewa
Bákan náà lọ tún jẹ́ minisita feto ìdájọ́ ni ṣáá eto iselu alágbada kejì, nígbà tí Alhaji Shehu Shagari jẹ aarẹ Naijiria.

Kí ogbó tó dá ikooko Osuolale lára, ó ṣiṣẹ agbẹjọro débi pé ó gbà òye àgbà amofin taa mọ si SAN, tó sì tún jẹ́ òye n'ilu Ibadan, tíì ṣe ikú abinibi rẹ.
Richard Osuolale Abimbola Akinjide wá sílè ayé, ó ṣe ayé rẹ, o jagun, ó sẹgun, to sì ṣe àṣeyọrí nínú gbogbo ohun tó dá wọ lé.
Osuolale ni ìyàwó, èyí tó ti jẹ́ ìpè Ọlọ́run síwájú rẹ, tó sì bí ọpọ ọmọ pẹ̀lú, nínú èyí taa tí rí Amofin Olajumoke Akinjide, tí òun náà jẹ amofin àti minisita tẹ́lẹ̀ fún olú ìlú ilẹ wá, Abuja.
BBC Yoruba wa ń gba ni àdúrà pé Ọlọ́run Ọba yóò gbà àbọ̀ olóògbé náà, yóò si fi ikú ṣe ìsinmi fún un.
Awọn eniyan ti n ṣe idaro Oloye Richard Akinjide to d'oloogbe.
Akọroyin BBC to ṣe abẹwo si ile oloogbe to wa ni adugbo Idi Ishin nilu Ibadan jabọ pe ẹbi, ara, ọrẹ ati awọn olubanikẹdun ti n pejupesẹ si ile oloogbe naa.
Aworan Oloye Akinjide n bẹ lorii tabili pẹluu iwe nla kan ti awọn olubanikẹdun n kọ ikini ati idagbere ikẹyin si.

Ko tii si alaye ni pato lori isinku oloogbe, ṣugbọn iwadi fi idi rẹ mulẹ pe wọn ti tọju oku oloogbe si ileewosan ikọsẹ iṣegun oyinbo, UCH to n bẹ ni Ibadan.
Lara awọn eekan ilu to ti ṣedaro rẹ ni igbakeji aarẹ Naijiria nigba kan, Atiku Abubakar.
Atiku sọ pe Akinjide gbe igbeaye to ni ipa gẹgẹ bi amofin, oloṣelu ati olori ilu.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Bakan naa ni Minisita fun igboke-gbodo ọkọ ofurufu, Femi Fani-Kayode naa sọ pe Akinjide jẹ olori ilu ti ko ṣe fọwọ rọ sẹyin.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Oru ọjọ Iṣẹgun ni iroyin jade pe amofin ati agbẹjọrọ, Oloye Abimbọla Oṣuọlale Richard Akinjide ti ju awa silẹ.
Baba da gbere faye ni nkan bi agogo kan oru lẹni ọdun mejidinlọgọrin ni ile rẹ to wa ni ilu Ibadan lẹyin aisan ranpẹ.
Oloye Richard Akinjide ti figbalan ri jẹ minisita feto idajọ lasiko iṣejọba Aarẹ Shehu Shagari.
Bakan naa lo jẹ minisitita feto ẹkọ nigba iṣejọba saa oṣelu akọkọ lorilẹede Naijiria labẹ olootu ijọba naa, Alaaji Tafawa Balẹwa.













