Ramadan 2020: Ṣọ́ọ́ṣì kan sí ìlẹ̀kùn rẹ̀ fún àwọn mùsùlùmí láti kírun Jímọ̀ ní Germany

Oríṣun àwòrán, Reuters
Sọọsi kan nilu Berlin, l'orilẹ-ede Germany, ti silẹkun rẹ fawọn musulumi lati jọsin nibẹ nitori pe mọsalasi wọn ko gba wọn mọ.
Igbesẹ yi ko sẹyin titẹle ilana titaketesiraẹni tuntun ti ijọba gbekalẹ, eleyi ti o mu adinku ba iye eeyan to le jọsin lẹẹkan naa ninu ile ijọsin.
Orileede Germany faye gba ki eto ijọsin yala ni Mọsalasi tabi sọọsi bẹrẹ pada ni ọjọ Kẹrin osu Karun, sugbọn awọn olujọsin gbọdọ takete si ara wọn niwọn ẹsẹ bata marun un.
Nitori eyi, mọsalasiDar Assalamni agbegbe Neukölln ko gba gbogbo awọn to wa jọsin nibẹ.
- Olùkọ́ Seyi Makinde gba èrè tiẹ̀ láyé, gómìnà yàn án sípò òṣèlú
- Ilé ẹjọ́ dá Ààfá dúró láti gbé ọmọ ọdun 16 sílé gẹ̀gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀ kẹ́sàn án
- Wo ohun tí a mọ̀ nípa iléeṣẹ́ "ISON Xperiences" tí òṣìṣẹ́ 78 ti kó àrùn coronavirus ní Ìbàdàn
- Arákùnrin tó jí Ese Oruru gbé ti rí ẹ̀wọ̀n ọdún 26 he
- Mo wọ bàtà àti fìlà wọ pẹpẹ Cele láti ṣe wáàsí, kò sí ṣọ́ọ̀ṣì tí n kò le wọ̀ - Sheik Buhari ọmọ Musa
Ki awọn eeyan ba le ribi jọsin, sọọsi Martha Lutheran ni Kreuzberg nawọ iranwọ pe ki awọn olujọsin to kuwa si ọdọ awọn lati le kirun jimọ to kẹyin ninu osu awẹ Ramadan.
Amọ ni Berlin, bi o ti se ri lawọn orileede to ku l'agbaye, asiko Coronavirus yi sebi ẹni da eto awẹ ru lọdun yi.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Imaamu mọsalasi naa sọ fun ileesẹ iroyin Reuters pe ''apẹẹrẹ nla leleyi jẹ, ti o si mu ayọ ati idunnu wa lasiko ifoya yii''.
O ni ''ajakalẹ aarun yii ti mu ki gbogbo wa di ọkan naa.O ti mu ki isọkan wa laarin gbogbo eniyan''.
Ẹlẹsin musulumi kan, Samer Hamdoun ni ''o kọkọ ri bakan lara nigba ta wa nibẹ nitori awọn ohun eelo orin, ati aworan to yi wa ka. Amọ ti ẹ ba moju kuro lawọn iyatọ diẹ diẹ yi, ẹ o ri pe ile Ọlọrun naa nibi jẹ''

Oríṣun àwòrán, Reuters
Koda pasitọ sọọsi naa, Monika Mathias , n kopa ninu ijọsin ọhun, to si ba wọn sọrọ.
O sọ pe "nigba ti wọn si n sadura, mo sa n sọ pe bẹẹni, bẹẹni , bẹẹni nitori pe nkankan na ni ohun to jẹ wa logun, mo si fẹ kẹkọọ lọdọ rẹ. Oun to rẹwa ni lati ri bi ero ọkan wa ti se ri si ara wa".
Wo díẹ lára ẹkọ tí àwọn Mùsùlùmí leè kọ lásìkò Ramadan tó ń wáyé nínú àrùn Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi oṣu Ramadan ṣe bẹrẹ lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2020, Ramadan ọdun yii yoo yatọ nitori ajakalẹ arun Coronavirus.
Coronavirus yii lo n ba gbogbo agbaye finra leyi to ti mu ki ọpọ orilẹede gbe ofin konile-o-gbele kalẹ.
Eyii si ti mu ki ọpọ awọn Musulumi maa bere pe bawo ni Ramadan ọdun yii yoo ṣe ri.
Sheikh Muhammad Ibn Othman to jẹ Imamu Mọṣalaṣsi Kano ba akọṛoyin ileeṣẹ BBC sọrọ lori bi awọn nkan ti Musulumi le ṣe lasiko Ramadan pẹlu bi arun Coronavirus ṣe wa lode.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi Coronavirus yoo ṣe mu ayipada ba Ramadan ọdun 2020
Itakete sira ẹni ti wa ninu ẹsin Imale ṣaaju akoko yii, fun apẹẹrẹ, ti eeyan ba jẹ alubọsa, iru ẹni bẹẹ ko le wọ Mọṣalaṣi nitori oorun rẹ.
Ṣaaju asiko yii, awọn Musulumi ma n korajọ sinu Mọṣalaṣi fun ẹkọ, lati gbadura papọ ati lati ṣinu loṣu Ramadan.
Ṣugbọn bayii nnkan ti yi pada ni Naijiria, ati lawọn orilẹ-ede miran bi Egypt ati Saudi Arabia to jẹ olu ilu awọn Musulumi lagbaye.
Ti isunfunraẹni ba le wa nitori alubọsa, o yẹ ko rọrun fun awọn Musulumi ododo lati takete fun ara wọn ninu Ramadan lasiko arun Covid-19 to wa lode.
Ipa ti imọ ẹrọ lee ko lasiko Ramadan

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Sheikh Othman sọ pe "Ori ayelujara ni mo ti maa ṣe Tafsir lọjọ Ẹti lati inu iyẹwu mi."Eyii to n tumọ sipe imọ ẹrọ yoo ko ipa to pọ ninu Ramadan ọdun yii.
Sheikh Othman ni akoko ti to fun awọn adari ẹsin Musulumi lati gbe ero atijọ ti sẹgbẹ kan, ki wọn si bẹrẹ si n lo ẹrọ ayelujara fun isin wọn.
Ẹkọ ti Musulumi le kọ lasiko ajakalẹ arun yii
Ẹkọ kinni, gẹgẹ bi Sheik ọhun ṣe sọ, ni pe Allah nikan lọba lori ohun gbogbo ati lori gbogbo ẹda alaaye.
Ati pe, akoko yi jẹ akoko lati fi ifẹ han si aladugbo ẹni, papa julọ awọn to ku diẹ kaato fun.Sheik ni asiko yi lo yẹ ki awọn eeyan, papa awọn Musulumi ma ro ọjọ atisun, ki wọn si sun mọ Ọlọrun ati awọn ẹbi wọn.
O tun sọ pe ki wọn fi akoko igbele ati Ramadan ọhun gba adura ki wọn si tun fi ṣetọju awọn alaini.
Sheikh Othman pari ọrọ rẹ pe "Adura wa ni pe ki Ọlọrun ba wa dawọ iji arun naa duro."

Sultan ìlú Sokoto pàṣẹ kí àwẹ̀ Ramadan ó bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n rí oṣù

Oríṣun àwòrán, AFP
Lẹyin to kofiri oṣu tuntun to le , Sultan ti ilu Sokoto, Saad Abubakar ti kede pe awẹ Ramadan fawọn Musulumi yoo bẹrẹ lọjọ Ẹti.
Ninu ikede kan to ṣe lori tẹlifisan ijọba kan lorilẹede Naijiria, Sultan Abubakar to jẹ olori ijọ musulumi lorilẹede Naijiria rọ awọn musulumi lati yago fun ipejọpọ ọlọpọ ero ki wọn si duro si ile wọn.
Bakan naa ni igbimọ to n ṣe akoso ẹsin musulumi lorilẹede Naijiria, NSCIA tun ke sawọn mọṣalaṣi gbogbo lati wọgile gbogbo eto taraweeh, iyẹn adura araarọ lasiko awẹ, idanilẹkọọ Tafsir, atawọn eto miran to js ms asiko awẹ Ramadan.
- ''Ìséde káàkiri Nàìjíríà lọ̀nà àbayọ sí ìtànkálẹ̀ coronavirus, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àpá kò ní ká covid-19 mọ́''- Onímọ̀
- Ọkùnrin Lebanese tó lu ọmọ Nàìjíríà ní gbàǹjo lórí Facebook ti kó sí páńpẹ́ ọlọ́pàá
- "Ọlọ́pàá ní kí n bọra sílẹ láti mọ bóyá obìnrin ní mí torí mo ní irùngbọ̀n"
- Nàìjíríà yóò wo tí aráàlú bá bínú lórí àfikún igbele Covid-19 - Dele Momoodu
Wọn wa rọ awọn olori ijọ musulumi gbogbo lati lo ayelujara fun eto iwaasu atawọn nnkan miran ti wọn ba ni lọkan lati ṣe lasiko awẹ yii.

Oríṣun àwòrán, others
Sultan tilu Sokoto, tíì tún ṣe aarẹ àpapọ̀ fàwọn musulumi ni Naijiria, Alhaji Sa'ad Abubakar Kẹta tí kesi àwọn Mùsùlùmí ni Naijiria lati máṣe kí irun àpapọ̀ fún ìbẹ̀rẹ̀ oṣù aawẹ.
- Ọ̀nà àbáyọ fún olóyún lásìkò àjàkálẹ̀ ààrùn Covid-19
- Ẹnìkan ṣoṣo nínú ìdílé kan ni yóò gbà N20, 000 owó ìdẹ̀rùn igbele Covid-19 - ìjọba àpapọ̀
- Lórí ọ̀rọ̀ Ogun Majek, mi ò lọ́rọ́ láti sọ, ẹ lọ pe ẹni tára rẹ̀ kò yá- Mr. Latin lórí àìsàn Ogun Majek
- Ewu ń bẹ! Coronavirus lè tara òkú Abba Kyari ran àwọn tó péjú síbi ìsìnkú rẹ̀- Ààrẹ ẹgbẹ́ dókítà ní Nàìjíríà
Sultan, ẹni tí akọ̀wé ẹgbẹ́ àpapọ̀ musulumi, Ọmọwe Khalid Abubakar-Aliyu gba ẹnu rẹ sọ̀rọ̀ nílu Kaduna, tun rọ àwọn musulumi lati mase lọ fún Haji kékeré taa mọ si Umurah nílẹ̀ Saudi Arabia nítorí àrùn Coronavirus."Kò ní sí ìpéjọpọ̀ musulumi fún waasi lásìkò aawẹ, irun isinu àti irun janmọ làwọn mọsalasi gbogbo títí tí ohun gbogbo yóò fi padà bọ sípò.
Sultan wá rọ àwọn musulumi lati maa kan sáwọn ojú òpó ikansira ẹni bíi Facebook, Skype, YouTube, Zoom, Instagram ati bẹẹ bẹẹ lọ, fun waasi aawẹ àti ìtọ́ni àwọn asaaju ẹṣin lásìkò oṣù Alapọnle náà .















