Buhari ọmọ Musa ní ìyàwó kan àti ọmọ mẹ́ta ni òun bí èyí tí kò wọ́pọ̀ láàrin àwọn àgbà Alfa

Oríṣun àwòrán, Buhariomomusa/Instagram
Ilumọọka oniwaasi agbaye, to tun jẹ agba Aafa, Sheikh Buhari Musa Adelodun, ti ọpọ eeyan mọ si Buhari ọmọ Musa ti salaye idi to fi lọ ṣe waasi ninu ijọ Celestial kan.
Buhari ọmọ Musa, lasiko to n dahun ibeere lori eto BBC Yoruba kan tun sisọ loju rẹ pe, ìjọ Celestial naa lo ransẹ pe oun lati wa ṣe waasi lori ẹni ti Mariam, ti Kristẹni n pe ni Mary, jẹ.
O ni oun kọ ni Aafa akọkọ to wọ inu sọọsi, ìjọ Kristẹni to ba si pe oun lati wa ṣe waasi, oun yoo da wọn lohun.
"Mo wọ inu ìjọ Celestial lai bọ bata tabi si fila, mo gun pẹpẹ wọn lati ṣe waasi, n ko jo tabi patẹwọ, mo si jẹ ki wọn mọ pe ọkan ṣoṣo ni Ọlọrun, aigbọ agbọye ẹṣin lo n da awọn miran laamu."
Nigba to n sọrọ lori idi to ṣe maa n fi awada gbe waasi rẹ kalẹ, agba Aafa naa ni idamọ toun laarin awọn oniwaasi ni awada lilo jẹ, eyi ti yoo mu kawọn ọdọ tete duro lati gbọ oun daadaa.
" Otitọ ọrọ koro, amọ inu yẹyẹ ṣíṣe lo fi le e wọnu ara, niwọn igba ti n kii ṣe onitiata, ma ke kurani, otitọ ọrọ yoo si jade."
Lori awọn Aafa to n gba tẹle awọn oloselu lẹyin, Buhari ọmọ Musa ni owo ti wọn ba fi di irufẹ awon Aafa bẹẹ lẹnu, ko ni jẹ ki wọn lee sọ ododo, ti wọn yoo si jiyin iṣẹ wọn ni alukiamọ.
Oniwaasi agbaye naa, ẹni to sọrọ nipa bo ṣe nira to lati ṣe waasi aawẹ ninu ọdun yii tun woye pe, bilala ni Coronavirus jẹ fun wa, wahala nla si lo da silẹ nitori ile ni olukaluku wa, lai lee ṣe waasi tabi idanilẹkọ aawẹ to fi mọ lanlatu kọdiri.
Bakan naa lo tun koro oju si awọn musulumi to ni aya pupọ lai lee ṣe deede laarin wọn pẹlu afikun pe iyawo kan ati ọmọ mẹta ni oun bi, lodi si bo ṣe n waye pẹlu ọpọ Aafa nla.
Nigba to n dahun ibeere pe owo to n gba pọ lati ṣe waasi, Buhari ọmọ Musa ni Ọlọrun lo paa laṣẹ pe ka ma ta ọrọ oun lọpọ, ni owo oun ṣe pọ.
O ni awọn Aafa lo yẹ ki araye maa tọju, oun si ni aya ati ọmọ nile lati tọju nitori oun ko lee ṣe gbajuẹ.











