World Hijab Day: Ọmọ Musulumi tí orin takasufèé rẹ̀ ta lẹ́nu rèé
Ninu fidio to wa loke yii, awọn orin ti Mina Voilée n kọ kọja afẹnusọ gẹgẹ bi olorin takasufee ṣugbọn to n ri idiwọ lati ọdọ gbogbo awọn to yi i ka.
"Wọ́n sọ fún mi pé nkò lè lo Hijab ki n tun maa kọ orin takasufee, wọ́n maa ń pè mí ni Eṣu pe mo ti ba ẹsin jẹ"
Ni idile ti wọn ti bi Mina gẹgẹ bii ọmọ Musulumi, o ni awọn ko le jade ki wọn ṣi wa nita di ago meje alẹ, ko ṣeeṣe. Lati kekere ni Mina si ti n wọ Hijab.

- Femi Adebayo, Bimbo Akinsanya sọ ìdí tí wọ́n ṣe fi ìgbéyàwó wọn àkọ́kọ́ sílẹ̀ kó tó bọ́ sórí
- Ní ìgbẹ̀yìngbẹ́yín, orílẹ̀èdè UK fi àjọ EU sílẹ̀
- Ọkọ̀ wa wọ'gbó lọ lẹ́yìn táwọn dánàdánà dàbọn bò wá- Toyosi Adesanya
- Bí Favour ṣe sùn, mo gbá ọmọ odó mọ́ ọ lórí a sì gé orí, ọkàn àti ọyàn rẹ̀ fún àsèjẹ - Kayeefi

Mina ni ohun ti oun nṣe ko ye gbogbo awọn to n bu oun lori ayelujara ni wọn ṣe n sọrọ bẹẹ.
"Wọ́n sọ fún mi pé nkò lè lo Hijab ki n tun maa kọ orin takasufee, wọn ní mò ń ba ẹ̀sìn jẹ́".

Koda Mina ni baba rẹ kọjalẹ nigba ti ọrọ yii kọkọ bẹrẹ ṣugbọn nigba ti wọ ri i pe oun ti ọkan oun fẹ ṣe niyẹn, wọn pada bẹrẹ si ni ti i lẹyin.
"Gbogbo igbiyanju wọn lati jẹ ki n fi i silẹ ni mo kọ. Lati igba naa ni wọn ti n ti mi lẹyin" ti Mina fi le sọ wi pe "Hijab mi ni idanimọ mi"











