Maryam Sanda: Femi Adebayo, Bimbo Akinsanya sọ̀rọ̀ lórí ohun tó ń kóbá ìgbèyàwó

Oṣere Femi Adebayo ati Bimbo Akinsanya

Oríṣun àwòrán, Instagram

Bi awọn eeyan ṣe n fesi si ọrọ idajọ ti ile ẹjọ da fun Maryam Sanda ti ile ẹjọ ṣẹṣẹ da ẹjọ iku nipa yiyẹ igi fun tori wi pe o pa ọkọ rẹ, Bilyaminu Bello ṣi n fẹ loju sii.

Ọrọ naa n mu awọn oṣere tiata lọkan gan to bẹẹ ti wọn n tu aṣiri bi wọn ṣe ṣe ninu igbeyawo tiwọn ko to de ibi to buru jai ti ipa wọn ko ni le ka.

Femi Adebayo

Oṣere Femi Adebayo

Oríṣun àwòrán, femiadebayosalami

Femi Adebayo to jẹ gbajugbaja oṣere ti ọpọlọpọ eeyan fẹran fi ọrọ igbeyawo rẹ ṣe apẹrẹ lori eto ileeṣẹ Amohunmaworan TVC kan ti awọn atọkun obinrin ti da ibeere bo o.

"Mo gbudọ so ootọ pe o lagbara lati to ile rẹ paapaa bi o ko ba ni iyawo tabi ọkọ to ni oye kikun".

Femi Adebayo ni "ará ìta ti fẹnu kò mí lẹ́nu rí lójú ìyàwó mi láti mọ rírì àwọn fíìmù mi ti mo n ṣe".

Femi ni bi o ko ba ni aya tabi ọkọ ti ọrọ rẹ ati iru iṣẹ ti o n ṣe ye daadaa, igbeyawo bẹẹ ko ni lee duro fun ọjọ pipẹ.

Àkọlé fídíò, Maryam Sanda: Ṣe ló ń wa ẹkún mu nílé ẹjọ́ lórí ìdájọ́ ikú tí wọn fun

Femi fi ọrọ iṣẹ ti wọn gẹgẹ bi oṣere naa we iṣẹ awọn oṣiṣẹ banki. "Awọn oṣiṣẹ Banki naa n jade, wọn si maa n pẹ wọle, bẹẹ naa ni iṣ wa ṣe maa n gbe eeyan rinrinajo pupọ.

Femi ni o kan jẹ pe adanwo to wa ninu iṣẹ tiata pọ ni fun apẹrẹ awọn ololufẹ ipa ti mo n ko ninu ere to jẹ obinrin maa n gbe adanwo wa.

"Mo ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdánwò látọ̀dọ̀ obìnrín".

Nigba miiran owo gọbọi bii miliọnu marun un ni obinrin mii a gbe ka ẹ laya pe ki wọn wa pẹlu ẹ ninu yara fun ọjọ mẹrin nigba to ṣe pe o le ma gba ju ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin fun sinima kan ti o fara han ninu rẹ lọ.

O ni o yẹ ki ọkọ ati aya maa ni ifarada fun ara wọn. Ẹni ti o fẹ gbudọ mọ iru iṣẹ ti o n ṣe ati bi o ṣe lee ṣamojuto awọn to jẹ onibara rẹ daadaa.

Bimbo Akinsanya

Oṣere Bimbo Akinsanya

Oríṣun àwòrán, Bimbo Akinsanya/Facebook

Molumọọka oṣerebinrin Bimbo Akinsanya ni tirẹ ni lati lee doola ẹmi ara oun loun ṣe fi igbeyawo oun silẹ.

"Mo fi igbeyawo mi silẹ nigba ti ọmọ mi wa ni oṣu mẹta pere. Bi o til jẹ pe o ni ko rọrun rara rara lati ṣe iru ipinu yii, Bimbo ni oun kuro tori pe oun ko fẹ ku ni".

Bimbo ni oun tete kuro ninu igbeyawo naa tori oun ko fẹ padanu ọmọ ko si fẹ di apaniyan.

"Ọdun kan ati oṣu mẹrin pere ni mo fi ṣe igbeyawo o si da bii ọrun apaadi ni". Bimbo gba awọn eeyan niyanju lati ma pa ọmọ ọlọmọ tori ati mu igbeyawo duro.

O ni ẹ jọwọ ẹ ma gbadura tabi gbero si obinrin pe ko kan jiya lasan.