Lai Mohammed: Mi ò mọ ohunkóhun nípa àbádòfin ọ̀rọ̀ ìkórìíra

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Minisita eto ibanisọrọ ati iroyin lorilẹede Naijiria Lai Mohammed ti sọ pe oun ko mọ ohunkohun nipa abadofin ọrọ ikorira.
Lai sọ ọrọ naa nibi ifọrọwerọ kan lori eto "Conflict Zone" pẹlu ileeṣẹ DW News to waye ni ilu London.
Nigba to n dahun awọn ibeere nipa abadofin to ni ṣe pẹlu titẹ oju ẹtọ awọn ọmọ Naijiria mọlẹ lati sọrọ lori itakun agabye, o ni oun ko mọ nnkan kan nipa abadofin naa.
- Ìdí tí Ààrẹ Trump fi dínà mọ́ Nàìjíríà àtí orílẹ̀èdè márùn ún míì láti má wọ Amẹ́ríkà
- Òfin lè má mọ ògùn ṣùgbọ́n èmí gbàgbọ́ pé ǹkan wà nídìí bí wọ́n ṣe pa ọmọ mi - Baba Favour
- Ní ìgbẹ̀yìngbẹ́yín, orílẹ̀èdè UK fi àjọ EU sílẹ̀
- Odion Ighalo darapọ mọ́ ikọ̀ Manchester United, òjijì ló bá àwọn olólùfẹ́ rẹ̀
- Femi Adebayo, Bimbo Akinsanya sọ ìdí tí wọ́n ṣe fi ìgbéyàwó wọn àkọ́kọ́ sílẹ̀ kó tó bọ́ sórí
Lai tẹsiwaju pe, ko si abadofin kankan nile igbimọ aṣofin Naijiria to ni ṣe pẹlu ọrọ ikorira tabi ṣiṣamojuto oju opo ayelujara.
O sọ pe orilẹ-ede Naijiria ko fun awọn oniroyin lọrun lati sọrọ bo ṣe wuwọn ati pe, ijọba to wa lode ko tẹ oju ẹtọ awọn ara ilu mọlẹ.
O ni "Mo ti jẹ Ministia fun nnkan bi ọdun marun un bayii, mi o tii ri eto kan ti ijọba yii ṣe to jẹ lati fi ẹtọ ara ilu dun wọn."
- Ìdílé kan gbé ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú lọ ilé ẹjọ́ lẹ́yìn tí wọ́n léwọ̀n dànù nínú ọkọ̀ pé ara wọ́n ń rùn
- Sinimá tí Lateef Adedimeji dá nikan jẹ́ òṣèré yóò jáde, Yemi Solade fi ọ̀pọ̀ fọ́tò "dẹngẹ pó" lọ́jọ́ ìbí rẹ̀
- Ìròyìn òfegè lásán ni! A ò fi físà dun Bísọ̀bù Oyedepo- US Embassy
- Uber ni mo fẹ́ máa gbé báyìí, mi ò tún fẹsẹ̀ rìn mọ́ - Agunbaniro to n gba N33,000
Minisita naa sọ pe ijọba Buhari ko ni ohunkohuin lati fi pamọ, ati pe ijọba naa n dari ilu gẹgẹ bi ofin ṣe gbe kalẹ.
O tẹsiwaju pe irọ nla ni pe ijọba ko fọwọsowopọ pẹlu awọn ajọ ajafẹni ni Naijira ati kaaakiri agbaye.
Ṣaaju ni ọgbẹni lai ti sọ fun awọn oniroyin pe ijọba yoo maa ṣamojuto oju opo ikansiraẹni lori itakun agbaye.
Lẹyin ti fidio ifọrọwerọ naa jade tan ni ọpọ awọn ọmọ Naijiria bẹrẹ si n fi eroungba wọn lede loju opo Twitter.













