Ìdílé kan gbé ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú lọ ilé ẹjọ́ lẹ́yìn tí wọ́n léwọ̀n dànù nínú ọkọ̀ pé ara wọ́n ń rùn

Airlinne

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Idíle kan gbé ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufu lọ ilé ẹjọ lẹ́yin ti wọ́n lẹwọ̀n dànu ninu ọkọ pé ara wọ́n ńrun

Idile kan ni Michigan, ti àwọn ilé iṣẹ ọkọ ofurufu ilẹ Amẹrika kan lé kuro ninu ọkọ ofurufu wọ́n nítori pé wọ́n ni òòru ara (Body Odour) ti gbé ilé iṣk náà lọ ilé ẹjọ.

Ilé iṣẹ́ ọkọ ofurufu náà lé Yehuda Yosef Adler, iyawo rẹ̀ Jennie àti ọmọ wọ́n obinrin kékéré kuro ninu ọkọ ofurufu Detroit ni inú oṣù kini ọdun to kọja.

Wọ́n ni ọkàn nínú àwọn olùrànlọwọ inu ọkọ ofurufu sọ̀rọ̀ nipa ẹsin ìgbà jew ti àwọn ń sìn.

Sùgban àwọn ilé iṣẹ́ ọkọ ofurufu náà ni ìdi ti àwọ̀n fi le wan kuro ni pe kìí ṣe nitori ẹsìn bíkòṣe pé àwọn àlábara wọ́n to ku ń kùn pé wọ́n ni òòrun ara pàápàá jùlọ ọgbẹ́ni Adlers

Ipẹjọ náà ti wọ́n pe ni Texas sàlàye pe ìbanilórukọ jẹ́ ni wọ́n se fun ẹbi ọhùn , ti èyi si fa iréwési ọkàn fun àwọn ẹbi náà to si tàkà àbuku si ẹsìn wọ́n

Airline

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Idíle kan gbé ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufu lọ ilé ẹjọ lẹ́yin ti wọ́n lẹwọ̀n dànu ninu ọkọ pé ara wọ́n ńrun

Ogẹni Alder ni lẹyin iṣkju marun ti a[wọn ti wa ninu ọkọ ni ọkan ninu àwọn òsìsẹ́ wọ́n wa sọ pe ìṣẹ̀lẹ̀ pajawiri sẹlẹ̀ wọ́n si ni lati sọkalẹ.

Nígbà ti wan sọkalẹ tan ni o wá sọ fun wan pe awako ofurufu lọ yọ orukọ wan kuro ninu irinajo náà.

Nínú àtẹjade ilé iṣẹ́ náà fi sita la'ti ọdọ Fox News: " a so fun ọgbẹni Alder àti ẹbi rẹ̀ láti sọkalẹ ninu ọkọ ofurufu náà lẹ́yin ọpọlọpọ àwọn èrò ńkùn nitori wọ́n, ìgbésẹ wa ni ]nkan ti a ro pe o tọna láti ṣe nitori alafia awọn èrò to kù"

" Ko si eyi to niṣe pẹlu ẹsin ọgbẹ̀ni Adler