NYSC: Àwọn àgùnbánirọ̀ fi orin ọpẹ́ bọ ẹnu lórí owó oṣù tuntun 33k

Alabi Seyifunmi to n sin ilẹ baba rẹ nilu Abuja ti ni idunnu subu layọ fun awọn nigba ti awọn agunbanirọ ri pe ijọba ti n san ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn Naira(33,000) owo osu fun awọn.
Agunbanirọ Seyifunmi ni ẹgbẹrun mọkanlelọgbọn ni awọn tilẹ n reti, ko to di wi pe awọn akẹgbẹ rẹ sọ fun un wi pe ẹgbẹrun mẹ̀talelọgbọn ni wọn ri ninu banki wọn.

Arabinrin naa ni bi inu oun ṣe dun mọ oun to, oun ko ni fi ẹsẹ rin mọ ni igboro Abuja, ọkọ ọyọkẹlẹ ni oun yoo ma a wọ bayii.
O fikun pe oun yoo fi afikun owo naa kọ ẹkọ imọ ti yoo ṣe oun ni anfaani, bakan naa ni oun yoo ra awọn nkan ti o nilo si ara oun.
Ninu ọrọ tirẹ, agunbanirọ Akinlolu Ogunmọlawa ni oun fẹ fi owo naa kọ iṣẹ ọwọ ki oun le dadurọ ti oun ba bari gẹgẹ bi agunbanirọ.
Ogunmọlawa fikun wi pe nibi ti inu awọn dun de, awọn ti wọn ti fi igba kan ṣe agunbanirọ ri n parọwa si ijọba lati fun awọn laaye lati wa ṣe agunbanirọ lẹẹkan si, ati wi pe ki wọn fikun iye ọdun ti awọn yoo ma a fi sin orilẹede Naijiria.
Ẹgbẹrun mọkanlelogun o le ẹgbẹrin naira ni wọn n gba tẹlẹ ni oṣooṣu, ki o to di pe ijọba wa fikun owo oṣu wọn to di ẹgbẹ̀run mẹ̀talelọgbọn.
'Lórí owó gọbọi 33k,mò lè tún àgùnbánirọ̀ NYSC mi ṣé tí ààyè bá gbà mí'
Alaati ti dun, kii ṣe 'audio money', ijọba ti n san owo agunbanirọ tuntun ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn Naira!
Ọrọ ti agunbanirọ kan fi si oju opo Facebook rẹ lati fi jẹri fawọn ọrẹ rẹ pe alekun ti ba owo ti ijọba n san fun wọn.
Idunnu to ṣubu layọ fun agunbanirọ yii jẹ eleyi tawọn ẹlomiran ti kii ṣe agunbanirọ gaan n ba wọn yọ nipa alekun owo naa.
Koda awọn kan sọ pe ti awọn ba ni anfaani, awọn yoo pada lati lọ ṣe agunbanirọ ki wọn baa le jẹ anfaani owo yii.
Loju opo Twitter wọn ko fi ọrọ yi bo rara
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ki lo mu awọn eeyan fẹ tun agunbanirọ ṣe
Pupọ awọn to ti pari ẹkọ ati agunbanirọ ni Naijiria ni ko tii ri iṣẹ.
Lara awọn to ti ri gan, owo oṣu ti ẹlomiran n gba ko to owo tuntun yii ti ijọba ṣẹṣẹ bẹrẹ si ni san.

Oríṣun àwòrán, PIUS UTOMI EKPEI
Ṣaaju asiko yii, owo oṣu to kere julọ ti ijọba n san fawọn oṣiṣẹ ko kọja ẹgbẹrun mejidinlogun le diẹ ti alawee awọn agunbaniro si jẹ ẹgbẹrun mọkandilogun naira le diẹ.
Idi ree ti awọn ti ko tii ri iṣẹ miiran fi n sọ pe yoo wu awọn lati tun agunbanirọ ṣe lati le fi ma ri owo yii gba.












