Àjọ EFCC gbé òtè lé àwọn adélébọ̀ tó ń wá iṣẹ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Patako atọka ileeṣẹ EFCC

Ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra lorilẹede Naijiria EFCC n gba ni si iṣẹ lọwọ wọn si ti fi kun ara awọn ofin to wa labẹ ipolowo iṣẹ naa pe ki awọn to ti lọkọ tabi laya ma dabaa rẹ rara.

Igbesẹ yii ni ọpọ awọn eeyan ti n bu ẹnu atẹ lu to fi mọ ẹgbẹ kan to so mọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ to n jẹ ẹgbẹ awọn olugbaninimọran nipa igbanisiṣẹ.

Ninu iwe kan to tan ka gbogbo ori ayelujara lọjọ kẹẹdogun oṣu kinni ọdun 2020 ninu eyi to sọ pe ajọ EFCC fẹ gba oṣiṣẹ si awọn ipo kan lo ti han wi pe " ẹni to ba ti lọkọ tabi laya ko ma rẹ".

Bakan naa fun ọkan lara awọn ipo naa, ẹni to ba ti le ni ọdun mọkanlelogun ko gbudọ kọ iwe lati wa iṣẹ naa. Fun omii, ẹni to ba ti le ni ọdun mẹẹdọgbọn ati ikẹta, ẹni to ba ti le ni ọdun mẹtadinlọgbọn.

Lẹyin eyi ni wọn wa fi kun gbogbo rẹ pe ẹni ti yoo ba wa iṣẹ naa ṣi gbudọ jẹ apọn ati omidan.

Ohun ti awọn eeyan n sọ nipa rẹ lori ayelujara ree.

"...ewo tun ni ti ọjọ ori ninu iṣẹ ijọba. O da mi loju gan pe iwọnba ti wọn fẹ gba yẹn, ẹni ba lẹsẹ ni yoo ri i gba...

Ọjọ ori yii ti ja ọpọlọpọ awa ti a nifẹ lati gba iṣẹ naa walẹ... Aparo kan ko ga ju ọkan lọ o. Eyi ko dara rara.

"Mi o mọ idi ti eeyan nilo lati lọ fi iwe naa silẹ ni ọfiisi ajọ EFCC. Ori ayelujara lo yẹ ki wọ

Ẹwẹ nigba ti akọroyin BBC kan si ọkan lara awọn agbẹnusọ ileeṣẹ naa, o kọ lati fọ esi kankan lori rẹ.