Favour Oladele: Bó ṣe kàgbákò ikú gbígbóná lọ́wọ́ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀- Kayeefi
Ninu fidio to wa loke yii, ẹ o ri pabanbari bi Owolabi Adeẹkọ ṣe fi ọrẹbinrin rẹ ṣe oogun owo fun oun ati iya rẹ.
Ṣe ẹ ranti Favour Daley Oladele ni nkan bii ọsẹ diẹ sẹyin ti ọrẹkunrin rẹ Owolabi ati iya rẹ ati Woli rẹ pa ti wọn si ge ẹran ara rẹ fi ṣe asejẹ ki Owolabi ati iya rẹ le di ọlọla laye.
Odidi ilu marun un ni ọrọ to kan iku Favour rọ mọ kaakiri - Eko, Abeokuta, Mowe, Ikoyi Ile, Osogbo.
- Àjọ NCDC kéde èèyàn 239 míràn tó ni ààrùn Covid-19 lórílẹ̀-èdè Naijíríà
- Ìjọba yóò ṣe ìwádìí ohun tí kò jẹ́ kí ìpínlẹ̀ Kogi àti Cross River tíì ní coronavirus- Mínísítà
- Ọmọ ìjọ 20 kú bí wọ́n ṣe tẹ̀ wọ́n pa níbi ìsọjí ìtagbangba
- Ọọni, Aláàfin, Ojisẹ Ọlọ́run àti oniṣẹ ìwádìí fi Ògún gbari pé òògùn ìbílẹ̀ le wo Covid-19
- Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà wọ́gilé ẹ̀wọ̀n Orji Uzor Kalu, pàṣẹ ìgbẹ́jọ́ tuntun
Eko ni ile iwe Favour wa, Fasiti ti ipinlẹ Eko (LASU) nibi to ti n kọ nipa imọ ẹkọ Tiata.
Mowe ni Favour n gbe pẹlu awọn obi rẹ, Alagba ati iyaafin Dale David Oladele. Mowe naa ni agọ Ọlọpa ti awọn obi Favour lọ nigba to di pe wọn n wa ọmọ wọn.
Ikoyi Ile ni ṣọọṣi Wolii Phillips to jẹ Pasitọ ijọ ti Owolabi ọrẹkunrin Favour mu u lọ wa.

- Ọmọ Yahoo yóò pọ̀ si tẹ bá ní kí ọ̀kadà má rìn lójú pópó Eko - Àwọn ọ̀dọ́
- "Ọlọ́pàá ní kí n bọra sílẹ láti mọ bóyá obìnrin ní mí torí mo ní irùngbọ̀n"
- Ojora ń mú mi lọ́wọ́ lórí ìkọlù tó wáyé, ara mi kò tíì balẹ̀ - Toyosi Adesanya
- Ó gbà mí tó wákàtí kan kí ń tó gbàgbọ́ pé mo bímọ lẹ́yìn ìdádúró ọdún mẹ́jọ - Imoyosola
Favour dagbere nile pe oun n lọ si ile iwe lati lọ mura ko to bẹrẹ idanwo aṣekagba ni fasiti rẹ, Fasiti ilu Eko ninu imọ ẹkọ Tiata.
Oun ati awọn obi rẹ dagbere lai mọ pe ọtọ ni ibi ti o n lọ gẹgẹ bi ọrẹkunri rẹ ṣe ti sọ fun un pe ko wa ba oun ni ilu Ikoyi Ile.
- Ọgbẹ́ ọkàn láéláé ni fún ọmọbìnrin ọdún mẹ́wàá, tí bàbá rẹ̀ dáná sí lábẹ́ - Amòfin
- Maryam Sanda, ìyàwó tó pa ọkọ rẹ, ri ìdájọ ikú he
- Ẹ ta kété sí àjọṣepọ̀ tí kò bá fún yín láyọ̀ torí ẹ̀mí kò ní ààrọ̀ - Àwọn òṣèré tíátà gbarata lórí ìdájọ́ ikú
- Ẹ wo bí Amotekun ṣe gba ilẹ̀ Yoruba silẹ̀ lọ́wọ́ agbéṣùnmọ̀ní ní igba ọdún sẹ́yìn














