Child Abuse: Amòfin ní ọmọbìnrin náà leè rí ara rẹ̀ bíi ẹni tí kò wúlò

Amofin nipa ẹtọ ọmọde, Taiwo Akinlami sọ pe ọgbẹ ọkan manigbagbe laelae ni ijiya ti baba ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹwaa jẹ fun ọmọ naa, lẹyin ti baba rẹ so mọ aja ti o si tun dana sii labẹ.
O ni ọkan lara ipa ti iru ijiya yii le ni lori ọmọ naa ni pe o le jẹ ki ọmọ yii ri ara rẹ gẹgẹ ẹni ti ko wulo lọjọ iwaju.
Ajọ NSDC lo fọwọ ofin ju baba ọmọ naa, ẹni ọdun mọkanlelogoji pẹlu iyawo rẹ lẹyin ti wọn fẹsun kawọn mejeeji pe wọn pa ọwọ pọ fiya jẹ ọmọdebinrin yii lọna aitọ.
- Ọmọ Yahoo yóò pọ̀ si tẹ bá ní kí ọ̀kadà má rìn lójú pópó Eko - Àwọn ọ̀dọ́
- Ọmọ ìgboro ní mí, ọdún 13 ní wọ́n fipá bámi lòpọ̀ àmọ́ mo fẹ́ dà bíi Muhammed Alli - Kọńgílá Aṣẹ́wó
- Ọ̀gọ́rún sọ́ọ̀bù, àìmọye dúkìá ni iná tún jó lọ́jà Sabo nílùú Sagamu
- "Ọlọ́pàá ní kí n bọra sílẹ láti mọ bóyá obìnrin ní mí torí mo ní irùngbọ̀n"
- Bí Amẹrika bá dínà mọ́ Nàíjíríà láti wá sílẹ̀ wọn, ewu ń bẹ fún wa - Lai Muhammed
- Maryam Sanda, ìyàwó tó pa ọkọ rẹ, ri ìdájọ ikú he
Baba ọmọ naa ṣalaye pe, oun fẹ dẹru ba ọmọ oun ni ko le jẹwọ lẹyin to ji ẹgbẹrun un mẹta naira to jẹ ti obinrin kan, ti orukọ rẹ n jẹ Rukayat Trimisiyu.
Iroyin sọ pe ọmọ naa pada jẹwọ, bẹẹ lo si lọ mu owo ọhun wa nibi to fi pamọ si, lẹyin ti wọn fiya jẹ ẹ tan.
Ọmọdebinrin yii wa nile iwosan bayii nibi ti o ti n gba itọju si apa ti ijiya naa ni ara rẹ.
Amọ agbẹjọro Akinlami ni, ko si ohun to buru ninu ki obi ba ọmọ wi ti ọmọ ba ṣẹ, ṣugbọn kii ṣe ki obi wa sọ ọmọ di alaabọ ara tabi ko lu ọmọ naa pa.
Amofin Akinlami ni, ohun tawọn obi yii ṣe buru jai, bakan naa ni ohun ti wọn se lodi si ofin ẹtọ ọmọde ni Naijiria.
O fikun ọrọ rẹ pe, ileejọ nikan lo le sọ iru ijiya to tọ si awọn obi ọmọ yii.
O ni eyi yoo jẹ ẹkọ fawọn obi mii tawọn le fẹ fiya jẹ ọmọ wọn lọna to lodi s'ofin.
Amofin Akinlami sọ pe, o ṣe pataki lati tubọ ṣe ilanilọyẹ sii lori ofin to n ja fẹtọ awọn ọmọde ni Naijiria.














