Brexit: Bí orílẹ̀-èdè Gẹẹsi ṣe fi àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Europe sílẹ̀ rèé

Brexit

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Adari ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson ni inu awọn kan ko dun si iyapa yii.

Orilẹ-ede Gẹẹsi ti yapa kuro ni EU lẹyin ibaṣepọ ọlọdun mẹtadinlaadọta ati lẹyin ọdun mẹta o le diẹ to ti n gbero ati fi ajọ naa silẹ.

Iṣẹlẹ manigabgbe yii lo waye ni dede ago mejila oru ọjọ kinni, oṣu Keji ọdun 2020.

Igbesẹ naa si ti fa ọpọ ajọyọ nile Gẹẹsi ati ifẹhonuhan lodi si igbesẹ naa lawọn apa ibikan lorilẹ-ede Ireland.

Ninu atẹjade kan ti olori ijọba Gẹẹsi Boris Johnson fi lede ni igba to ku wakati kan ki ipinya naa waye, o ni ipinnya ọhun jẹ akoko ti awọn kan ti n reti, ti wọn ko si lero pe o lee waye.

Boris tẹsiwaju pe, "Inu awọn kan ko dun si iyapa yii. Ṣugbọn ojuṣe mi ni lati rii pe orilẹ-ede yii jẹ ọkan ṣoṣo, ati pe o ni itẹsiwaju."

O ni bo tilẹ jẹ pe ajọṣepọ pẹlu EU ni anfani tirẹ, ṣugbọn lati nnkan bi aadọta ọdun sẹyin ni ibi ti ajọ EU n doju kọ kodun mọ orilẹ-ede Gẹẹsi ninu mọ.

Ọpọ awọn ọmọ orilẹ-ede UK lo korajọ si ile igbafẹ lati ṣajọyọ ipinya orilẹ-ede ọhun pẹlu ajọ EU.

Ni Àríwá Ireland, awọn ẹgbẹ to lodi si iyapa naa korajọ si Armagh fun ifẹhonuhan lodi si iyapa naa, ṣugbọn o dabi pe omi ti tẹyin wọgbin lẹnu.

Nibi ti ọrọ de duro bayii, bo tilẹ jẹ pe ilẹ Gẹẹsi ti yapa kuro ni ajọ EU, ọpọ ohun bii eto ọrọ aje, ifọwọsowọpọ lori eto abo, atawọn ọrọ mii lo ṣi wa nilẹ ti wọn ko tii yanju.

Àkọlé fídíò, 'Ọwọ́ tó bá dilẹ̀ ni èṣù ń bl ní iṣẹ́kíṣẹ́'