Adultery/Adeboye: Agbẹjọró ní ìjìyà wà lábẹ́ òfin Naijiria fún pànságà nínú ìgbéyàwó

Baba Adeboye Ati Iyawo re

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Agbẹjoro ati onimọ nipa ofin orilẹede Naijiria, Kayode Ajulo ti sọ wi pe, ijiya wa labẹ ofin ti ẹnikẹni ninu igbeyawo ba ṣe pansaga.

Ajulọ sọ eyi lasiko to n fesi si ọpọlọpọ awuyewuye to n lọ lori ọrọ ti Adari Agba Ijọ Redeem, RCCG, Pasitọ Enoch Adeboye sọ lori bi o ṣe yẹ ki eniyan o ṣe ninu igbeyawo.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

O ni labẹ ofin Naijiria, orisirisi igbeyawo meta ti o wa ni igbeyawo ti wọn lọ si ileejọ lati lọ ṣe igbeyawo wọn, eleyii ti ẹsin musulumi fi aye gba ati igbeyawo ti ẹsin abalaye ẹkun si ẹkun fi aye gba.

Agbẹjọro naa ni, igbeyawo abalaye ti ilẹ Yoruba nikan lo faye gba ki ọkunrin o ni iyawo pupọ, nigba ti ẹsin musulumi labẹ ofin sọ wi pe, eniyan le fẹ mẹrin ti o ba si le ṣe deede laarin awọn iyawo ohun.

Kayode Ajulọ tun mọ pansaga gẹgẹ bi ibaṣepọ tabi ibalopo laarin eniyan meji ti wọn kii se lọkọlaya, abi ti wọn ko ṣe igbeyawo labẹ ofin to rọ mọ igbeyawo lorilẹede Naijiria.

Awọn ọmọ Naijiria ko fi ara ire gba imọran rẹ lori igbeyawo!

Amọ awọn ọmọ Naijiria to tako ọrọ ti Adeboye sọ ni wi pe, ki lo de to jẹ obinrin ni Baba ni ki wọn le, nigba to jẹ wi pe ọkunrin lo n ni ifẹkufẹ si ọmọbinrin to n ba a ṣiṣẹ.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Bakan naa ni awọn ti wọn tako ọrọ ti pasito naa sọ salaye pe, imọran Adeboye lodi si ofin ibi iṣẹ to kọ ki wọn le eniyan lai ni idi.

Wọn gbagbọ pe ẹbi isẹlẹ naa le e ma wa lati ọdọ ọmọbinrin to jẹ akọwe ti baba ni ki ọmọ rẹ le danu, nitori o jẹ moriwu fun un lojoojumọ lati lọ si ibi iṣẹ.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Sugbọn awọn to faramọ ọrọ ti Baba Adeboye sọ ni ko si ohun to buru ninu ọrọ naa, nitori eniyan ni aṣẹ lati yago fun ohunkohun to le e fa ijamba fun ẹmi ati ara rẹ.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Wọn fikun pe, igbeyawo jẹ ohun ọlọla ti awọn eniyan yẹ ki wọn bọwọ fun lai si inira fun wọn nipa pansaga, eleyii ti o le e sediwọ fun wọn nipa ṣiṣe ojuṣe wọn ni inu ile.

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Ti a ko ba gbagbe, laipẹ yii ni ile ẹjọ da ẹjọ iku fun Abileko Maryam Sanda fun fifi ọbẹ gun ọkọ rẹ lori ẹsun pe o n ṣe pansaga ninu igbeyawo wọn.