Ọ̀nà ti ìyá mi kọ mi ni mò n tọ- Sotayogaga

Sotayo

Oríṣun àwòrán, Sotayogaga

Àkọlé àwòrán, Ọ̀rọ̀ owó lo da emi àti Saheed Balogun pọ ti mo fi ke gbajare lori Instagram
    • Author, Yemisi Oyedepo
    • Role, Broadcast Journalist
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Sotayo ni ìpolowó ọjà ni òun ba ẹni ti Saheed Balogun sọ fun oun pe ki òun ba ṣe iṣẹ́, eyi ti oun náà si pe àwọn miran láti jọ ṣe isẹ́ náà.

O ni ìrètí òun ni pé nígbà ti iṣẹ́ ba pari ìrètí òun ni pé ẹni to ni okun nidi ni òun bá siṣẹ, sùgbọ́n ìyàlẹnu lo jẹ́ pe àti saheed Balogun ati ẹni ti oun bá ṣe iṣẹ́ ko si ẹni to sọ̀rọ̀ loro rẹ mọ.

Gbajugbaja oṣèré Tiata náà fi kun pé àwọn ti oun náà pe si iṣẹ́ n fa òun, èyi lo mu ki òun ke gbàjare si gbogbo àwọn miran ninu agbo òṣèré wọ́n ba àwọn dási.

Sobola ni ọ̀rọ̀ náà ki ṣe ǹkan to lágbara rara, nitori òun ko tilé fẹ́ràn àriwo tàbi ọ̀rọ̀ to ba da bii ija.

Sotayo

Oríṣun àwòrán, Sotayogaga

Àkọlé àwòrán, Ọ̀rọ̀ owó lo da emi àti Saheed Balogun pọ ti mo fi ke gbajare lori Instagram

Nínú ìfọ̀rọ̀werọ náà, Sobola ni kii ṣe gbogbo òṣère tiata lo ri ṣe ti ènìyàn ba si ri ẹlomiran to n ṣe npnkan ko nilo ki a sẹ afara wé.

O ni kìí ṣe gbogbo ǹkan ti eniyan ba ri lori ayelujara ni ki èniyan gbàgbọ. O sàlaye pe omi gan ko ṣe mu níle ẹlọmiran.

Kìí ṣe gbogbo ǹkan ti àwọn òṣère ba gbe sori ayelujara ni o jẹ òòtọ

Bakan náà lo sàlaye pe gbogbo ìwà ati iṣesi òun ni òni, àwọn ǹkan ti iya òun fi kọ oun ni

Ọ̀rẹ́ lásàn ni èmi àti Qdot bẹ́ẹ̀ ni kò ra G-Wagon fun mi- Sotayo Gaga

Sotayo

Oríṣun àwòrán, BBC Sport

Àkọlé àwòrán, Ọ̀rẹ́ lásàn ni èmi àti Qdot bẹ́ẹ̀ ni kò ra G-Wagon fun mi- Sotayo Gaga

Sobola Tayo ti o jẹ́ gbajugbaja oṣèré tiata ti gbogbo ènìyàn mọ si Sotayo Gaga sọ̀rọ̀ ilẹ kun lásìkò ti o wá si ilé BBC yoruba ni òsán òní.

O sàlàye lori àwọn ẹsùn ti o gbòde nipa ìwà awọn ọgá lọ́ga nínú Nollywood ti wọ́n maa n dẹnu ifẹ́ tipatipa skọ àwọn ọmọ ti wọ́n fẹ́ ṣe iṣẹ tiata.

O fí kun pé ni ọ̀pọ̀ ìgbà ǹkan ti oníkulùkù ba n fẹ́ lo n ṣe, nitori pe nígba ti ẹlomiran ba kọ ẹni ti o dẹnu ifẹ́ kọ wọ́n, ni a ti ri ẹlomiran ti a ni ẹ jọwọ ẹ fi mi silẹ bi mo ṣe wà, sùgbọ́n ẹlòmiran gan ni yóò kọkọ sọ pe gbogbo ǹkan ti wọ́n ba fẹ́ ni òun yóò ṣe.

O ní ẹlomiran ko fẹ́ dúro rára láti san àwọn ǹkan to yẹ láye òde òni.

"Arewa oníjọgbọ̀n ní fíímù àkọkọ ti mo kọkọ ṣe pẹ̀lú owó mí ti o si kọkọ gbé mi Jade''

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Lóri, ìbáṣepọ to wà láàrin òun àti Baba Tee pẹlu Qdot, Sotayo ni ọ̀rẹ lásàn lo wà láàrin àwọn nítori òun ko fi bẹẹ fẹ́ràn láti maa ko ọ̀rẹ nitori náà òun kò ni ọ̀rẹ binrin.