Kano Xtian Burial: Lẹ́yìn Ọjọ méje ní wọ́n tó mọ̀ pé Kristẹni ni ẹni tí wọ́n sin, tí wọn sì hú òkú náà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ipinlẹ Kano ni iṣẹlẹ kan ti ṣẹ, nibi ti wọn ti bẹrẹ si ni hu oku lẹyin ọjọ meje nitori ẹni ti o yẹ ki wọn sin kọ ni wọn sin.
Amọ, ẹbi naa ni ki i ṣe awọn to n sin oku ni ipinlẹ Kano, bi ko ṣe ile igbokusi, lo ṣe aṣiṣe naa.
Agbeegbe ibi ti awọn musulumi n gbe ni Gandun Albasa ni aarin gbungun Kano, ni wọn ti ṣe aṣiṣe lati sin arakunrin Basil Ejensi dipo Abdullahi Obinwa.
Alaga agbeegbe naa, Imam Aminu Adam lọ sọ fun BBC pe, ohun ni oun ṣe aṣiṣe naa nitori awọn mejeeji jọ ara wọn loju oun.

Imam Adam ni "Wọn sọ fun wa ni ile igbokusi pe nọmba kejilelogun ni Abdullahi Obinwa wa, nitori naa nigba ti mo de ibẹ lati wo oku naa, Basil jọọ Obinwa to ti gbe pẹlu wa fun ogoji ọdun.
Awọn mejeeji ni omi lara diẹ, ti wọn ko si ga lọpọ, bẹẹ ni wọn ko si ni irun agbọn".
Adam fikun pe, nigba ti oun beere lọwọ awọn oṣiṣẹ ile igbokusi pe, o dabi ẹni pe oku naa ko ni irugbọn, ni wọn sọ fun oun pe, nigba miran awọn ma n fa irun agbọn awọn eniyan to ba ti papoda.
Wahala bẹ silẹ nigba ti awọn mọlẹbi Ejensi naa fẹ lọ gbe oku wọn, ti o si di awati ni ile igbokusi.
Awọn mọlẹbi naa wa oku Ejensi de ibi ti wọn ti sin oku naa si fun ọjọ meje, ti wọn si lọ gba aṣẹ ile ẹjọ lati le lọ gba oku naa.

Amọ titi di wakati yii, wọn si n wa oku ọgbẹni Obinwa, nitori ko si ni ile igbokusi, ki wọn le e fun ni isinku ti ọna igbagbọ musulumi.
Awọn alaṣẹ ile iwosan Aminu Kano nibi ti wọn ti gbe oku funrawọn sọ fun BBC pe, awọn yoo ṣe iwadii ohun to ṣẹlẹ ni ile igbokusi naa.












