Ogun Accident: FRSC ní Sokoto làwọn èrò náà ti ń bọ̀ wá sí Ijẹbú Ode

Ọkọ akẹru to ko sinu ọkọ Ogun

Oríṣun àwòrán, Abiodun

Iroyin to n tẹ wa lọwọ fi ye ni pe ọpọ oku lo ti sun, ti ọkẹ aimọye si farapa lasiko ti ọks akẹru kan rebọ sinu odo Ogun lopopona Ibadan silu Ijẹbu Ode lọjọ Isẹgun.

Iroyin naa ni ọkọ akẹru ọhun, ti nọnba rẹ jẹ XE331MKA lo ko ero bii mejidinlọgọta, to si n bọ lati ilu Sokoto wa si Ijẹbu Ode lasiko to rebọ sinu odo Ogun ni idaji kutu hai ana.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi oludari fun ajọ ẹsọ oju popo, FRSC, ẹka tipinlẹ Ogun, Clement Oladele yi sọ fun awọn akọroyin, o seese ko jẹ pe o ti rẹ awọn arinrinajo naa dẹnu lo mu ki ijamba naa waye.

Awọn eeyan to farapa ninu ọkọ FRSC

Oríṣun àwòrán, Others

"Ni kete ti isẹlẹ yii to wa leti, lawọn osisẹ wa lati ẹka ti Ijẹbu Ode ati Ago Iwoye, yara lọ sibi ti isẹlẹ ọhun ti waye, ti wọn si ko awọn oku to fori sọta ijamba naa lọ sile igbokusi, nigba tawọn to farapa wa ni ile iwosan ijọba nilu Ijẹbu Ode."

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Ìrírí àwọn ọ̀dọ́bìnrin tó dágbà sójú pópó àti ìrètí wọn fún ọjọ́ ọ̀la

Oladele wa rọ awọn ero lati maa rinrinajo pẹlu ọkọ ti wọn se fun ẹru kiko nikan nitori awọn ijoko wọn ko wa fun ijoko.