ALGON Oyo: Aleshinloye ní ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ làwọn ń tẹ̀lé, kò sì yẹ kó fa ìjà

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Gomina ipinlẹ Ọyọ, onimọ-ẹrọ Seyi Makinde ti salaye pe, owo awọn ijọba ibilẹ to rogun lo wọ awọn alaga ijọba ibilẹ labẹ APC to wa nipinlẹ́ naa loju.

Fidio ree lori ọrọ ti Seyi Makinde ati Ayodeji Abass Aleshinloye:

Àkọlé fídíò, ALGON Oyo: Aleshinloye ní ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ làwọn ń tẹ̀lé, kò sì yẹ kó fa ìjà

Amọ Alaga ẹgbẹ awọn alaga ijọba ibilẹ APC naa ti fesi pada pe ko si ohun to buru ninu bi awọn se n lakaka lati pada si ọọfisi awọn nitori ileẹjọ ti fun awọn lasẹ.

Wọn wa kesi gomina Makinde lati bọwọ fun ofin, ko si jẹ ki awọn wa pari saa ti ilu to dibo yan awọn, gbe le awọn lọwọ.

Ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ̀ fún alága Káńṣù APC kan l'Ọyọ, tọ́ọ́gì lùú délé ìwòsàn

Ọrọ awọn alaga ijọba ibilẹ ti ijọba Seyi Makinde fi ofin de ti n ba ọna miran yọ nitori ọkan ninu wọn ti di ero ile iwosan bayii.

Awọn eeyan duro si ibujoko ijọba ibilẹ Afijio

Oríṣun àwòrán, Others

Gẹgẹ bi iroyin to n to wa leti ti wi, Ọjọru lawọn janduku ẹda kan lọ kọlu alaga kansu Afijio, Samuel Aderemi , ti wọn si lu bii ẹni lu bara, eyi to mu ki wọn lọ sile iwosan.

Awọn janduku naa la gbọ pe ya bo ibujoko ijọba ibilẹ Afijio laarọ Ọjọru, ti wọn di alaga ọhun ni apanyaka lẹyin ti wọn lu ni aludoju bolẹ tan, ti wọn si gbe sinu ọkọ bọọsi ti wọn gbe wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọpẹlọpẹ awọn agbofinro to tete dide sọrọ naa, ti wọn gbaya ọkọ awọn janduku ẹda naa, ti wọn si gba alaga ọhun silẹ lọws wọn.

Nigba to n sọrọ lori ikọlu naa, alaga ẹgbẹ awọn alaga kansu labẹ ijọba APC to kọja, Ayọdeji Abass Alẹsinlọyẹ salaye pe isẹlẹ naa ko jẹ tuntun si awọn, tori awọn ti mura silẹ pe o seese ki iru awọn ikọlu naa waye.

Alaga ẹgbẹ Algon ni Ọyọ

Oríṣun àwòrán, ALGON

'Wọn mọọmọ ran awọn janduku lati wa kọlu wa ni, ko ma baa seese fun wa lati sisẹ ti ofin gbe le wa lọwọ. Wọn kọlu ọpọ awa ọmọ ẹgbẹ APC, sugbọn omi ta ba sa si ẹyin lara lawọn ikọlu yii, ko lee mọ ẹyin lara."

Bẹẹ ba gbagbe, Ọjọ Aje ni awọn alaga kansu labẹ ijọba APC yọju si awọn kansu wọn lodi si asẹ ti gomina Seyi Makinde pa pe oun ti juwe ọna ile fun wọn.

Àkọlé fídíò, Amotekun: Fatomilola ní gaga ọwọ̀ làwọn baba wa fi ń ṣọ́ ilé, òyìnbó ló sọ wá di ọ̀lẹ

Màá bọ̀wọ̀ fún àṣẹ iléẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó bá jáde lórí ọ̀rọ̀ káńṣù l'Ọyọ - Makinde ṣèlérí fún ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti ṣe abẹwo si Ọga Agba Ọlọpaa, Adamu Mohammed ni Abuja fun ijiroro lori yiyọ awọn alaga ijọba nipo, eyi to n fa awuyewuye ni ipinlẹ naa.

Ọga agba ọlọ pa, Seyi Makinde ati Hosea Agboola

Oríṣun àwòrán, @AjisebioyoGsm

Makinde lasiko abẹwọ naa sọ fun ọga ọlọpaa pe, ijọba oun ko ni faye gba iwa ipa ni ipinlẹ naa.

Gomina naa ti o ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade naa ni ipade ọhun niiṣe pẹlu ọna lati wa ọna abayọ si eto aabo ipinlẹ naa.

O fikun wi pe, ọrọ aigboraẹniye to n waye ni ipinlẹ naa ko ṣẹyin bi oun ṣe kọwe ‘lọ gbe ile rẹ’ fun awọn alaga ijọba ibilẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ti oun si yan awọn alaga afunsọ dipo wọn, lo fa gbọnmi si, omi o to ni ipinlẹ naa.

Makinde ni oun ṣetan lati bọwọ fun aṣẹ ile ẹjọ, ni kete ti ile ẹjọ kotẹmilọrun ba ti fi idajọ rẹ lede lori ẹjọ naa.

Awọn alaga ijọba ibilẹ labẹ ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọyọ

Oríṣun àwòrán, Algon

Gomina, to sọrọ gẹgẹ bi ẹni to bọwọ fun ofin ilẹ naa ni, oun ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn eniyan lati le pese orilẹede ti yoo bọwọ fun ofin orilẹede naa.

O wa parọwa si awọn eniyan lati gba alaafia laye, ki wọn si maṣe dawọ le ohunkohun ti yoo fa rogbodiyan ni ipinlẹ naa.

Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Oyo naa ni oun ti jẹ ki ọga agba ọlọpaa mọ wi pe, ile ẹjọ ti paṣẹ pe oun pẹlu kọmisana ọlọpaa ipinlẹ naa ati ọga agba ọlọpaa, ko ni aṣẹ lati gbe igbesẹ kankan lori ọrọ to niiṣe pẹlu ọrọ ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Oyo.

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Eleyii to ni ọga agba ọlọpaa ni oun yoo fesi si, ni kete ti oun ba ti ri iwe aṣẹ ile ọjọ naa.

Gomina ipinlẹ Oyo naa wa rọ gbogbo araalu lati gba alaafia laye, ki orilẹede to n bọwọ fun ofin ti awọn gbiyanju lati gbekale le wa si imuṣẹ.