EFCC: Ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlá ní iléẹjọ́ fún tìyá-tọmọ tó lu òyìnbó ní jìbìtì

Alaba ati Damilola Adeyeri

Oríṣun àwòrán, EFCC

Yoruba ni owu ti iya ba gbọn, ni ọmọ yoo ran, bẹẹ si ni ọmọ kii ba ipele iya rẹ, ko si asọ da.

Iya kan ree, Alaba Kareem Adeyeri, ti adajọ da ẹjọ ẹwọn ọdun mejila fun oun ati ọmọ rẹ, Damilola Ahmed Adeyeri lori ẹsun pe awọn mejeeji dijọ lẹdi apo pọ lu oyinbo ara Amẹrika kan ni jibiti owo to to ẹgbẹrun lọna mejilelọgọrin ati aabọ naira.

Ẹsun mẹrin ọtọọtọ to nii se pẹlu iwa jibiti lori ayelujara ni ajọ EFCC fi kan tiya-tọmọ, tawọn mejeeji si ni ki adajọ se awọn jẹjẹ, tori pe awọn jẹbi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọlọpa ọtẹlẹmuyẹ fun EFCC, Idi Musa lo salaye pe ajọ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ Amẹrika, FBI, lo fi to awọn leti pe awọn onijibiti kan lo tọwọbọ oju opo Email ifiweransẹ ileesẹ Amẹrika naa, ti wọn si ji owo gọbọi naa.

Musa ni ni kete ti Damilola ri pe awọn ọtẹlẹmuyẹ ti n dọdẹ oun, lo ba fi ara soko, to si ni kii iya oun lọ ba oun gba owo tuulu yii, to si ba fi ra ọpọ ile ati dukia lorisilorisi.

Alaba Adeyeri

Oríṣun àwòrán, EFCC

Ibi ti iya naa ti lọ gba owo nile ifowopamọ lọjọ kan ni ọwọ ti baa, to si mu awọn ọtẹlẹmuyẹ lọ si ibi ti ọmọ rẹ wa, bẹẹ ni wọn ba ọpọ owo ni inu apo asunwọn wọn.

Agbẹjọro fun ajọ EFCC, Bilikisu Buhari sọ fun ileẹjọ pe Alaba ati ọmọ rẹ yii ati ẹnikan ti wọn pe ni Kareem Russel, to ti na papa bora, ni wọn dijọ lu adari ileesẹ kan nilẹ Amẹrika ni jibiti lọdun 2017 amọ ti ọwọ tẹ wọn lọdun 2019.

Damilola Adeyeri

Oríṣun àwòrán, EFCC

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Aneke salaye pe afihan fidio ti ajọ EFCC se nile ẹjọ fidi rẹ mulẹ pe awọn mejeeji lo jẹbi ẹsun lilu jibiti ti wọn fi kan wọn, to si ni ki wọn lọ fun ẹwọn ọdun mẹta mẹta lori ikọọkan ẹsun mẹrẹẹrin ti wọn fi kan wọn.

Bakan naa lo pasẹ pe gbogbo owo ti wọn ba ninu apo asunwọn owo wọn nile ifowopamọ, ko di ti ijọba