Buhari Resign: Secondus ní kí Buhari kéde nǹkan ò fararọ lẹ́ka ààbò, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kó kọ̀wé fipò sílẹ̀

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter/Bashir Ahamad

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹgbẹ oṣelu PDP sọ pe gbọingbọin lawọn wa lẹyin olori ẹgbẹ osẹlu alatako to gbojigan julọ nile aṣofin agba l'Abuja, Ṣẹnẹtọ Enyinnaya Abaribe to sọ pe ki aarẹ Muhammadu Buhari kọwe fipo silẹ.

Alaga gbogbogbo ẹgbẹ oṣelu PDP, Uche Secondus lo sọrọ yii fawọn akọroyin niluu Abuja l'Ọjọbọ.

Sẹnẹtọ Abaribe sọ fun aarẹ pe ko kọwe fi ipo silẹ lori eto aabo to mẹhẹ kaakiri lorilẹede Naijiria.

Ninu ọrọ tiẹ, Secondus ni o ṣe pataki fun Buhari lati kede ilu nnkan o fararọ lẹka eto aabo, o ni ijọba ti ko dara to lo ṣokunfa eto aabo to mẹhẹ.

O fikun ọrọ rẹ pe bi ẹgbẹ oṣelu APC to wa lori aleefa ṣe n ṣejọba lo jẹ ki eto aabo mẹhẹ, ohun naa lo si jẹ ki airiṣẹṣe pọ si ati ọrọ aje to dẹnu kọlẹ.

Amọ Secondus ṣalaye pe ẹgbẹ oṣelu PDP ko fẹ doju ijọba Naijiria bo lẹ, ṣugbọn ohun ti ẹgbẹ naa n sọ ni pe ki Buhari fipo silẹ ti ko ba le wa nnkan ṣe si eto aabo to mẹh

Abaribe, ọ̀rọ̀ agọ̀ lo sọ pé kí Buhari kọ́we fipo sílẹ́ torí ààbò tó mẹ́hẹ - Iléèṣẹ ààrẹ

Ileeṣẹ aarẹ orileede Naijiria ti tutọ soke foju gba lori ọrọ ti ile aṣofin agba sọ pe ki aarẹ Buhari kọwe fiposilẹ lori lori pe ko ri nkankan ṣe lori ipenija aabo to n koju Naijiria.

Lọjọru ni Garba Sheu to jẹ agbẹnusọ ileeṣ aarẹ fi ọrọ yi sita loju opo Twitter ti o si ni iwa agọ ni Sẹnẹtọ Enyinnaya Abaribe hu bo ti ṣe ni ki aarẹ Buhari fiposilẹ.

Aworan Sẹnẹtọ Abaribe

Oríṣun àwòrán, Enyinaya Abaribe/Facebook

Garba Sheu ni ti aarẹ Buhari ba ni lati fiposilẹ,aimọye eeyan naa lo yẹ ko ṣebẹ ti Abaribe naa yoo si wa lara wọn.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ọrọ Garba Sheu yi ti mu iriwisi ọtọọtọ wa lati ọdọ awọn ọmọ Naijiria loju opo Twitter.

Bi awọn kan ti ṣe n gbe lẹyin Sheu lawọn miran n sọ pe ọrọ Abaribe ko buru rara toun ti ipenija aabo to n koju Naijiria

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Skip X post, 3

End of X post, 3

Skip X post, 4

End of X post, 4

Skip X post, 5

End of X post, 5

Ki gan ni Abaribe sọ ni ile asofin agba?

Lasiko ti ile aṣofin agba n jiroro lori ọrọ aabo Naijiria ni Sẹnẹtọ Enyinaya Abaribe dide lati sọrọ.

Ọrọ rẹ to da lori pe ipa aarẹ Buhari ko ka ipenija aabo ti Naijiria n koju, mu ki awọn Sẹnẹtọ fẹ ma tahun si ara wọn.

Skip X post, 6
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 6

Ṣugbọn kii ṣe ohun nikan lo sọ bẹẹ, tile si pada wa panupọ lori koko ọrọ mẹta ti o da lori pe:

  • Ki aarẹ Buhari kede pe nkan ko fararọ nipa pipese aabo ni Naijiria
  • Ki o ṣe idasilẹ igbimọ alabẹ ṣekele ti yoo wa wọrọkọ fi ṣada lori ọna abayọ lati koju ipenija aabo
  • Ki wọn si pe ọga agba ọlọpaa lati wa siwaju ile ni ọjọ kaarun oṣu Keji, ki o wa sọ bi idasilẹ ilẹeṣẹ ọlọpaa lawọn ipinlẹ yoo ti ṣe gberasọ.

Bo tilẹ jẹ wi pe orukọ Abaribe lawọn eeyan n mu bọnu paapa julọ loju opo Twitter, Sẹnẹtọ Abdullahi Abubakar to n ṣoju ẹkun ariwa ipinlẹ Kebbi, lo daba ọrọ ti o fẹ ṣebi ẹni da wahala silẹ yii.