Child marriage: Ilé ẹjọ́ dá Ààfá dúró láti gbé ọmọ ọdun 16 sílé gẹ̀gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀ kẹ́sàn án

Oríṣun àwòrán, @dsw_intl
Ile ẹjọ to n gbọ ọrọ to ni se pelu idile ni ilu Akure ti dẹkun aafa to gbiyanju ati gbe ọmọ ọdun mẹrindilogun sile gẹgẹ bi iyawo rẹ kẹsan an.
Igbimọ ẹlẹni mẹta to ṣedajọ ọrọ naa, ti adajọ Aderemi Adegoroye dari rẹ ti paṣẹ pe ki wọn da ọmọ ọhun pada si ọdọ awọn obi rẹ.
Ọdun 2019 ni Aaafaa naa, Yusuf lateef ti kọ gbiyanju lati fẹ ọmọde ọhun ni igba to ṣi wa ni ile ẹkọ girama, ṣugbọn igbiyanju rẹ fori ṣọpọn.
Ko pẹ si ti ọmọ naa pe ẹni ọdun mẹrindilogun ti aafaa ọhun mu ọjọ igbeyawo pẹlu rẹ.
Ṣugbọn ọmọ ọhun, ni ifọwọsowọpọ pẹlu ẹgbọn rẹ sa kuro nile ko to di pe igbeyawo naa waye.
Lẹyinorẹyin, ileeṣẹ ijọba ipinblẹ Ondo to n ri si ọrọ awọn obinrin da si ọrọ naa.
- Wo àwọn òṣèré tíátà Yorùbá tó ti kú àmọ́ tí iṣẹ́ wọn ń fọhùn síbẹ̀
- Olùkọ́ Seyi Makinde gba èrè tiẹ̀ láyé, gómìnà yàn án sípò òṣèlú
- Wo ohun tí a mọ̀ nípa iléeṣẹ́ "ISON Xperiences" tí òṣìṣẹ́ 78 ti kó àrùn coronavirus ní Ìbàdàn
- Kìí ṣe pé mo fẹ́ jẹ Ààrẹ Nàìjíríà ló mú kí n ṣe àtìlẹyìn fún ìfilọ́lẹ̀ ìkọ Amotekun - Fayemi
Lẹyin eyi ni ileeṣẹ naa pe awọn obi ọmọ naa ati aafaa to fẹ gbe niyawo lẹjọ, ile ẹjọ naa fẹsun kan wọn pe wọ tapa si ofin to n dabo bo ẹtọ awọn ọmọde ti ipinlẹ ọhun gbe kalẹ lọdun 2007.
Lẹyin atotonu awọn olujẹjọ, ile ẹjọ ni ki wọn yanju ọrọ ọhun itubi inubi, o si kan an nipa fun Aljaji Yusuf lati tọwọ bọwe pe ohunkohun ko ni ṣe ọmọdebirin naa, ati pe ko jinna rere sii.
Ni bayii, kọmiṣọna fun ọrọ awọn obinrin ati idagbasoke awujọ ni ipinlẹ Ondo, Titilola Adeyemi ti fa ọmọ naa le awọn ibi rẹ lọwọ.













